Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 21

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

21 Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ,
    àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!

Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un,
    bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela.
Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà
    ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.
Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un,
    àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.
Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un;
    ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.
Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un:
    ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.
Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa;
    nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà
    kì yóò sípò padà.

Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí;
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.
Nígbà tí ìwọ bá yọ
    ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru.
Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀,
    àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.
10 Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀,
    àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
11 Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ
    wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.
12 Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà
    nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.

13 Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ;
    a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.

2 Samuẹli 5:11-16

11 (A)Hiramu ọba Tire sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dafidi, àti igi kedari, àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn tí ń gbẹ́ òkúta, wọ́n kọ́ ilé kan fún Dafidi. 12 Dafidi sì kíyèsi i pé, Olúwa ti fi ìdí òun múlẹ̀ láti jẹ ọba lórí Israẹli, àti pé, ó gbé ìjọba rẹ̀ ga nítorí Israẹli àwọn ènìyàn rẹ̀.

13 Dafidi sì tún mú àwọn àlè àti aya sí i láti Jerusalẹmu wá, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti Hebroni bọ̀: wọ́n sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin fún Dafidi. 14 (B)Èyí sì ni orúkọ àwọn tí a bí fún un ní Jerusalẹmu; Ṣammua, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. 15 Àti Ibhari, àti Eliṣua, àti Nefegi, àti Jafia. 16 Àti Eliṣama, àti Eliada, àti Elifeleti.

Jakọbu 5:7-12

Sùúrù nínú ìjìyà

Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò. Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀: nítorí ìpadà wá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má ba à dá a yín lẹ́bi: kíyèsi i, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn.

10 Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù. 11 (A)Sá à wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fi ara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jobu, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú.

12 (B)Ṣùgbọ́n ju ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ má ṣe ìbúra, ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, tàbí ilẹ̀, tàbí ìbúra-kíbúra mìíràn. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni; àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ẹ má ba à bọ́ sínú ẹ̀bi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.