Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 14

Fún adarí orin. Ti Dafidi.

14 (A)(B) Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé,
    “Ko sí Ọlọ́run.”
Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú;
    kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere.

Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá
    lórí àwọn ọmọ ènìyàn
bóyá ó le rí ẹni tí òye yé,
    ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.
Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́;
    kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere,
    kò sí ẹnìkan.

Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀?

Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun;
    wọn kò sì ké pe Olúwa?
Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù,
    nítorí Ọlọ́run wà ní àwùjọ àwọn olódodo.
Ẹ̀yin olùṣe búburú da èrò àwọn tálákà rú,
    ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn.

Ìgbàlà àwọn Israẹli yóò ti Sioni wá!
    Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,
    jẹ́ kí Jakọbu kí ó yọ̀, kí inú Israẹli kí ó dùn!

2 Samuẹli 10:1-5

Dafidi ṣẹ́gun Ammoni

10 (A)Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, ọba àwọn ará Ammoni sì kú, Hanuni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Dafidi sì wí pé, “Èmi yóò ṣe oore fún Hanuni ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ sì ti ṣe oore fún mi.” Dafidi sì ránṣẹ́ láti tù Hanuni nínú láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá, nítorí ti baba rẹ̀.

Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì wá sí ilé àwọn ọmọ Ammoni. Àwọn olórí àwọn ọmọ Ammoni sì wí fún Hanuni olúwa wọn pé, “Ǹjẹ́ o rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nígbà tí ó rán ènìyàn wá láti bá ọ kẹ́dùn? Kò ha ṣe pé Dafidi rán àwọn ìránṣẹ́ sí ọ láti wo ìlú àti láti yọ́ ọ wò àti láti gbà ọ́.” Hanuni sì mú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi ó fá apá kan irùngbọ̀n wọn, ó sì gé ààbọ̀ kúrò ní agbádá wọn, títí ó fi dé ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ.

Wọ́n sì sọ fún Dafidi, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jeriko títí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.”

Kolose 1:9-14

(A)Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò sinmi láti máa gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí. 10 Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run, 11 pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀. 12 Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀. 13 (B)Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn. 14 Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.