Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 37:12-22

12 Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́,
    wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn;
13 ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú,
    nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.

14 Ènìyàn búburú fa idà yọ,
    wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn,
láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀,
    láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.
15 Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ,
    àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.

16 Ohun díẹ̀ tí olódodo ní,
    sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú;
17 nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,
    ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.

18 Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin,
    àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé;
19 Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi,
    àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.

20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé.
    Àwọn ọ̀tá Olúwa yóò dàbí ẹwà oko tútù;
    wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.

21 Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà,
    ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni;
22 Nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
    àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.

2 Samuẹli 11:22-27

22 Ìránṣẹ́ náà sì lọ, ó sì wá, ó sì jẹ́ gbogbo iṣẹ́ tí Joabu rán an fún Dafidi. 23 Ìránṣẹ́ náà sì wí fún Dafidi pé, “Nítòótọ́ àwọn ọkùnrin náà lágbára jù wá lọ, wọ́n sì jáde tọ̀ wá wá ní pápá, àwa sì tẹ̀lé wọn títí wọ́n fi dé ẹ̀yìn odi. 24 Àwọn tafàtafà sì ta sí ìránṣẹ́ rẹ láti orí odi wá, díẹ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́ ọba sì kú, ìránṣẹ́ rẹ̀ Uriah ará Hiti sì kú pẹ̀lú.”

25 Dafidi sì wí fún ìránṣẹ́ náà pé, “Báyìí ni ìwọ yóò wí fún Joabu pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí nǹkan yìí burú ní ojú rẹ, nítorí pé idà a máa pa lọ́tùn ún lósì, mú ìjà rẹ le sí ìlú náà, kí o sì bì í ṣubú.’ Kí ìwọ sì mú un lọ́kàn le.”

Dafidi fẹ́ Batṣeba ní ìyàwó

26 Nígbà tí aya Uriah sì gbọ́ pé Uriah ọkọ rẹ̀ kú, ó sì ṣọ̀fọ̀ nítorí ọkọ rẹ̀. 27 Nígbà tí ìṣọ̀fọ̀ náà sì kọjá tan, Dafidi sì ránṣẹ́, o sì mú un wá sí ilé rẹ̀, ó sì di aya rẹ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un, ṣùgbọ́n nǹkan náà tí Dafidi ṣe burú níwájú Olúwa.

Romu 15:22-33

22 (A)Ìdí nìyìí tí ààyè fi há pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ fún mi kí n tó tọ̀ yín wa.

Paulu ṣètò láti ṣé àbẹ̀wò sí Romu

23 (B)Ṣùgbọ́n báyìí tí kò tún sí ibòmíràn fún mi mọ́ láti ṣiṣẹ́ ní ẹkùn yìí, tí èmi sì ti ń pòǹgbẹ láti ọdún púpọ̀ sẹ́yìn láti bẹ́ yín wò, 24 (C)mo gbèrò láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí mo bá lọ sí Spania. Èmi yóò rí i yín ní ọ̀nà àjò mi, àti pé ẹ ó mú mi já ọ̀nà níbẹ̀ láti ọ̀dọ̀ yín lọ, lẹ́yìn tí mo bá gbádùn ẹgbẹ́ yín fún ìgbà díẹ̀. 25 (D)Ṣùgbọ́n ní báyìí, mo ń lọ sí Jerusalẹmu láti sé ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀. 26 (E)Nítorí pé ó wu àwọn tí ó wà ní Makedonia àti Akaia láti kó owó jọ fún àwọn tálákà tí ó wà ní àárín àwọn ènìyàn mímọ́ ní Jerusalẹmu. 27 (F)Pẹ̀lú ayọ̀ ni wọ́n ń ṣe èyí, nítorí wọ́n gbà wí pé, wọ́n jẹ́ ajigbèsè fún wọn. Nítorí bí ó bá ṣe pé a fi àwọn Kèfèrí ṣe alájọni nínú ohun ẹ̀mí wọn, ajigbèsè sì ni wọn láti fi ohun ti ara ta wọ́n lọ́rẹ. 28 (G)Nítorí náà, nígbà tí mo bá ti ṣe èyí tán, tí mo bá sì di èdìdì èso náà fún wọn tán, èmi yóò ti ọ̀dọ̀ yín lọ sí Spania. 29 (H)Mo sì mọ̀ pé nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín, èmi yóò wà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbùkún ìhìnrere Kristi.

30 Èmí rọ̀ yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, nítorí Olúwa wa Jesu Kristi, àti nítorí ìfẹ́ Ẹ̀mí, kí ẹ̀yin kí ó kún mi láti bá mi làkàkà nínú àdúrà yín sí Ọlọ́run fún mi. 31 (I)Kí a lè kó mi yọ kúrò lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ní Judea àti kí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo ní sí Jerusalẹmu le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀, 32 (J)kí èmi le fi ayọ̀ tọ̀ yín wa, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti kí èmi lè ní ìtura pọ̀ pẹ̀lú yín. 33 (K)Kí Ọlọ́run àlàáfíà wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.