Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Samuẹli 11:1-15

Dafidi àti Batṣeba

11 (A)Lẹ́yìn ìgbà tí ọdún yípo, ní àkókò ìgbà tí àwọn ọba máa ń jáde ogun, Dafidi sì rán Joabu, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àti gbogbo Israẹli; wọ́n sì pa àwọn ọmọ Ammoni, wọ́n sì dó ti Rabba. Dafidi sì jókòó ní Jerusalẹmu.

Ó sì ṣe, ní ìgbà àṣálẹ́ kan, Dafidi sì dìde ní ibùsùn rẹ̀, ó sì ń rìn lórí òrùlé ilé ọba, láti orí òrùlé náà ni ó sì rí obìnrin kan tí ó ń wẹ̀ ara rẹ̀; obìnrin náà sì ṣe arẹwà lójú láti wò. Dafidi sì ránṣẹ́ ó sì béèrè obìnrin náà. Ẹnìkan sì wí pé, Èyí ha kọ́ ni Batṣeba, ọmọbìnrin Eliamu, aya Uriah ará Hiti. Dafidi sì rán àwọn ìránṣẹ́, ó sì mú un; ó sì wọ inú ilé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a dàpọ̀: nígbà tí ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ tán, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀. Obìnrin náà sì lóyún, ó sì ránṣẹ́ ó sì sọ fún Dafidi, ó sì wí pé, “Èmi ti lóyún.”

Dafidi tan Uriah wá sílé

Dafidi sì ránṣẹ́ sí Joabu, pé: “Rán Uriah ará Hiti sí mi.” Joabu sì rán Uriah sí Dafidi. Nígbà tí Uriah sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Dafidi sì bi í léèrè báwo ni Joabu ti ṣe àti àlàáfíà àwọn ènìyàn náà, àti bí ogun náà ti ń ṣe. Dafidi sì wí fún Uriah pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ, kí o sì wẹ ẹsẹ̀ rẹ.” Uriah sì jáde kúrò ní ilé ọba, oúnjẹ láti ọ̀dọ̀ ọba wá sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Ṣùgbọ́n Uriah sun ní ẹnu-ọ̀nà ilé ọba lọ́dọ̀ gbogbo ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀.

10 Nígbà tí wọ́n sì sọ fún Dafidi pé, “Uriah kò sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀,” Dafidi sì wí fún Uriah pé, “Ṣe bí ọ̀nà àjò ni ìwọ ti wá? Èéha ti ṣe tí ìwọ kò fi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ.”

11 Uriah sì wí fún Dafidi pé, “Àpótí ẹ̀rí, àti Israẹli, àti Juda jókòó nínú àgọ́; àti Joabu olúwa mi, àti àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi wà ní ibùdó ní pápá: èmi ó ha lọ sí ilé mi, láti jẹ àti láti mu, àti láti bá obìnrin mi sùn? Bí ìwọ bá wà láààyè, àti bí ẹ̀mí rẹ́ si ti ń bẹ láààyè, èmi kì yóò ṣe nǹkan yìí.”

12 Dafidi sì wí fún Uriah pé, “Sì dúró níhìn-ín lónìí, lọ́la èmi ó sì jẹ́ kí ìwọ ó lọ.” Uriah sì dúró ní Jerusalẹmu ní ọjọ́ náà, àti ọjọ́ kejì. 13 Dafidi sì pè é, ó sì jẹ, ó sì mú nítorí rẹ̀; ó sì mu kí ọtí pa á; òun sì jáde ní alẹ́ lọ sí ibùsùn rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀.

Dafidi pàṣẹ kí wọn ó pa Uriah ní ogun

14 Ó sì ṣe ní òwúrọ̀, Dafidi sì kọ̀wé sí Joabu, ó fi rán Uriah. 15 Ó sì kọ sínú ìwé pé, “Fi Uriah síwájú ibi tí ogun gbé le, kí ẹ sì fàsẹ́yìn, kí wọn lè kọlù ú, kí ó sì kú.”

Saamu 14

Fún adarí orin. Ti Dafidi.

14 (A)(B) Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé,
    “Ko sí Ọlọ́run.”
Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú;
    kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere.

Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá
    lórí àwọn ọmọ ènìyàn
bóyá ó le rí ẹni tí òye yé,
    ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.
Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́;
    kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere,
    kò sí ẹnìkan.

Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀?

Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun;
    wọn kò sì ké pe Olúwa?
Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù,
    nítorí Ọlọ́run wà ní àwùjọ àwọn olódodo.
Ẹ̀yin olùṣe búburú da èrò àwọn tálákà rú,
    ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn.

Ìgbàlà àwọn Israẹli yóò ti Sioni wá!
    Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,
    jẹ́ kí Jakọbu kí ó yọ̀, kí inú Israẹli kí ó dùn!

Efesu 3:14-21

Àdúrà fún àwọn ará Efesu

14 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi. 15 Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé. 16 Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ fún ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. 17 Kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́; 18 kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga ìfẹ́ Kristi jẹ́. 19 Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kristi yìí tí ó ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run kún yín.

20 Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa. 21 Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kristi Jesu láti ìrandíran gbogbo àní, ayé àìnípẹ̀kun, Àmín.

Johanu 6:1-21

Jesu bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún

(A)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu kọjá sí apá kejì Òkun Galili, tí í ṣe Òkun Tiberia. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ ààmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn. Jesu sì gun orí òkè lọ, níbẹ̀ ni ó sì gbé jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Àjọ ìrékọjá ọdún àwọn Júù sì súnmọ́ etílé.

(B)Ǹjẹ́ bí Jesu ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Filipi pé, “Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ?” Ó sì sọ èyí láti dán an wò; nítorí tí òun fúnrarẹ̀ mọ ohun tí òun ó ṣe.

Filipi dá a lóhùn pé, “Àkàrà igba owó idẹ kò lè tó fún wọn, bí olúkúlùkù wọn kò tilẹ̀ ní í rí ju díẹ̀ bù jẹ.”

(C)Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Anderu, arákùnrin Simoni Peteru wí fún un pé, (D)“Ọmọdékùnrin kan ń bẹ níhìn-ín yìí, tí ó ní ìṣù àkàrà barle márùn-ún àti ẹja wẹ́wẹ́ méjì: ṣùgbọ́n kín ni ìwọ̀nyí jẹ́ láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí?”

10 Jesu sì wí pé, “Ẹ mú kí àwọn ènìyàn náà jókòó!” Koríko púpọ̀ sì wá níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin náà jókòó; ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní iye. 11 Jesu sì mú ìṣù àkàrà náà. Nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì pín wọn fún àwọn tí ó jókòó; bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni ẹja ní ìwọ̀n bí wọ́n ti ń fẹ́.

12 Nígbà tí wọ́n sì yó, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó àjẹkù tí ó kù jọ, kí ohunkóhun má ṣe ṣòfò.” 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó wọn jọ wọ́n sì fi àjẹkù ìṣù àkàrà barle márùn-ún náà kún agbọ̀n méjìlá, èyí tí àwọn tí ó jẹun jẹ kù.

14 (E)Nítorí náà nígbà tí àwọn ọkùnrin náà rí iṣẹ́ ààmì tí Jesu ṣe, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà tí ń bọ̀ wá sí ayé.” 15 (F)Nígbà tí Jesu sì wòye pé wọ́n ń fẹ́ wá fi agbára mú òun láti lọ fi jẹ ọba, ó tún padà lọ sórí òkè, òun nìkan.

Jesu rin lórí omi

16 (G)Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun. 17 Wọ́n sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì rékọjá Òkun lọ sí Kapernaumu. Ilẹ̀ sì ti ṣú, Jesu kò sì tí ì dé ọ̀dọ̀ wọn. 18 Òkun sì ń ru nítorí ẹ̀fúùfù líle tí ń fẹ́. 19 Nígbà tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi tó bí ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jesu ń rìn lórí Òkun, ó sì súnmọ́ ọkọ̀ ojú omi náà; ẹ̀rù sì bà wọ́n. 20 Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.” 21 Nítorí náà wọ́n fi ayọ̀ gbà á sínú ọkọ̀; lójúkan náà ọkọ̀ náà sì dé ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń lọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.