Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
139 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,
ìwọ sì ti mọ̀ mí.
2 Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
3 Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
4 Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
5 Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.
13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;
ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;
ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;
èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi
nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé:
àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
ní ọjọ́ tí a dá wọn,
nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
iye wọn ti pọ̀ tó!
18 Èmi ìbá kà wọ́n,
wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
nígbà tí mo bá jí,
èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.
Ìbí Samuẹli
1 Ọkùnrin kan wà, láti Ramataimu-Sofimu, láti ìlú olókè Efraimu, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, ọmọ Sufu, ará Efrata. 2 Ó sì ní ìyàwó méjì: orúkọ wọn ni Hana àti Penina: Penina ní ọmọ, ṣùgbọ́n Hana kò ní.
3 Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ ní Ṣilo, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì, Hofini àti Finehasi ti jẹ́ àlùfáà Olúwa. 4 Nígbàkígbà tí ó bá kan Elkana láti ṣe ìrúbọ, òun yóò bù lára ẹran fún aya rẹ̀ Penina àti fún gbogbo àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin. 5 Ṣùgbọ́n ó máa ń pín ìlọ́po fun Hana nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ àti pé Olúwa ti sé e nínú. 6 Nítorí pé Olúwa ti sé e nínú, orogún rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní fín níràn láti lè mú kí ó bínú. 7 Eléyìí sì máa ń ṣẹlẹ̀ ní ọdọọdún. Nígbàkígbà tí Hana bá gòkè lọ sí ilé Olúwa, orogún rẹ̀ a máa fín níràn títí tí yóò fi máa sọkún tí kò sì ní lè jẹun. 8 Elkana ọkọ rẹ̀ yóò sọ fún un pé, “Hana èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Èéṣe tí ìwọ kò fi jẹun? Èéṣe tí ìwọ fi ń ba ọkàn jẹ́? Èmi kò ha ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ bí?”
9 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n tún mu tán ní Ṣilo, Hana dìde wá síwájú Olúwa. Nígbà náà, Eli àlùfáà wà lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa ní ibi tí ó máa ń jókòó. 10 Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn Hana sọkún gidigidi, ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 11 Ó sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, jùlọ tí ìwọ bá le bojú wo ìránṣẹ́bìnrin rẹ kí ìwọ sì rántí rẹ̀, tí ìwọ kò sì gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ yóò fún un ní ọmọkùnrin, nígbà náà èmi yóò sì fi fún Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ a kì yóò sì fi abẹ kàn án ní orí.”
12 Bí ó sì ṣe ń gbàdúrà sí Olúwa, Eli sì kíyèsi ẹnu rẹ̀. 13 Hana ń gbàdúrà láti inú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ètè rẹ̀ ni ó ń mì, a kò gbọ́ ohùn rẹ̀. Eli rò wí pé ó ti mu ọtí yó. 14 Eli sì wí fún un pé, “Yóò ti pẹ́ fún ọ tó tí ìwọ yóò máa yó? Mú ọtí wáìnì rẹ̀ kúrò.”
15 Hana dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi,” “Èmi ni obìnrin oníròbìnújẹ́. Èmi kò mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle; Èmi ń tú ọkàn mi jáde sí Olúwa ni. 16 Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí obìnrin búburú. Èmi ti ń gbàdúrà níhìn-ín nínú ìrora ọkàn àti ìbànújẹ́ mi.”
17 Eli dáhùn pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Israẹli fi ohun tí ìwọ ti béèrè ní ọwọ́ rẹ̀ fún ọ.”
18 Ó wí pé, “Kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà bá tirẹ̀ lọ, ó sì jẹun, kò sì fa ojú ro mọ́.
Ìjẹ́jọ́ níwájú Festu
25 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí ó dé sí ilẹ̀ náà, Festu gòkè láti Kesarea lọ sì Jerusalẹmu, 2 ní ibi tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn pàtàkì nínú àwọn Júù ti gbé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Paulu wá, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́. 3 Wọ́n tọrọ lọ́wọ́ Festu, kí ó bá le ṣe ojúrere fún wọn, kí ó bá à lè jẹ́ kí wọn mú Paulu wá sí Jerusalẹmu, wọn ń gbìmọ̀ láti dènà dè é, kí wọn sì pa á ní ọ̀nà. 4 Ṣùgbọ́n Festu dáhùn pé, “A pa Paulu mọ́ ní Kesarea, àti pé òun tìkára òun ń múra àti padà lọ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. 5 Ẹ jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn olórí yín bá mi sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ìdí ẹ̀sùn tí ẹ fi sun ọkùnrin náà múlẹ̀ níbẹ̀, bí ó bá ní ohun búburú kan tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀.”
6 Lẹ́yìn tí ó sì ti gbé níwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá pẹ̀lú wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sì Kesarea, ni ọjọ́ kejì ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, ó sì pàṣẹ pé ki a mú Paulu wá síwájú òun. 7 Nígbà tí Paulu sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá dúró yí i ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Paulu lọ́rùn, tí wọn kò lè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.
8 Paulu si wí tí ẹnu rẹ̀ pé, “Èmi kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ kan sì òfin àwọn Júù, tàbí tẹmpili, tàbí sí Kesari.”
9 Ṣùgbọ́n Festu ń fẹ́ láti ní ojúrere lọ́dọ̀ àwọn Júù, ó sì dá Paulu lóhùn, wí pe, “Ìwọ ń fẹ́ gòkè lọ sì Jerusalẹmu, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀ níwájú mi bí?”
10 Paulu sì wí pé, “Mo dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kesari níbi tí ó yẹ kí a ṣe ẹjọ́ mí: èmi kò ṣẹ àwọn Júù, bí ìwọ pẹ̀lú ti mọ̀ dájú. 11 Ǹjẹ́ bí mo bá ṣẹ̀, tí ó ṣe pe mo sì ṣe ohun kan tí ó yẹ fún ikú, èmi kò kọ̀ láti kú: ṣùgbọ́n bí kò bá sí òtítọ́ kan nínú ẹ̀sùn tí àwọn Júù yìí fi mi sùn sí, ẹnìkan kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fà mí lé wọn lọ́wọ́. Mo fi ọ̀ràn mi lọ Kesari.”
12 Lẹ́yìn tí Festu ti bá àjọ ìgbìmọ̀ sọ̀rọ̀, ó dáhùn pe, “Ìwọ ti fi ọ̀ràn rẹ lọ Kesari. Ní ọ̀dọ̀ Kesari ni ìwọ ó lọ!”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.