Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Samuẹli 3:1-10

Olúwa pe Samuẹli

Samuẹli ọmọkùnrin náà ṣe òjíṣẹ́ níwájú Olúwa ní abẹ́ Eli. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ọ̀rọ̀ Olúwa ṣọ̀wọ́n: kò sì sí ìran púpọ̀.

Ní alẹ́ ọjọ́ kan Eli ẹni tí ojú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí di aláìlágbára, tí kò sì ríran dáradára, ó dùbúlẹ̀ ní ipò rẹ̀ bi ti àtẹ̀yìnwá. Nígbà tí iná kò tí ì kú Samuẹli dùbúlẹ̀ nínú tẹmpili Olúwa, níbi tí àpótí Olúwa gbé wà. Nígbà náà ni Olúwa pe Samuẹli.

Samuẹli sì dáhùn “Èmi nìyí” Ó sì sáré lọ sí ọ̀dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyí nítorí pé ìwọ pè mí.”

Ṣùgbọ́n Eli wí fún un pé, “Èmi kò pè ọ́; padà lọ dùbúlẹ̀.” Nítorí náà ó lọ ó sì lọ dùbúlẹ̀.

Olúwa sì tún pè é, “Samuẹli!” Samuẹli tún dìde ó tọ Eli lọ, ó sì wí pé, “Èmi nìyìí, nítorí tí ìwọ pè mí.”

“Ọmọ mi, èmi kò pè ọ́, padà lọ dùbúlẹ̀.”

Ní àkókò yìí Samuẹli kò tí ì mọ̀ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ Olúwa hàn án.

Olúwa pe Samuẹli ní ìgbà kẹta, Samuẹli sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyìí; nítorí tí ìwọ pè mí.”

Nígbà náà ni Eli wá mọ̀ pé Olúwa ni ó ń pe ọmọ náà. Nítorí náà Eli sọ fún Samuẹli, “Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀. Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, ‘máa wí, Olúwa nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀.

10 Olúwa wá, ó sì dúró níbẹ̀, ó pè é bí ó ṣe pè é ní ìgbà tí ó kọjá, “Samuẹli! Samuẹli!”

Nígbà náà ni Samuẹli dáhùn pé, “Máa wí nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.”

1 Samuẹli 3:11-20

11 Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Wò ó, èmi ṣetán láti ṣe ohun kan ní Israẹli tí yóò jẹ́ kí etí gbogbo ènìyàn tí ó gbọ́ ọ já gooro. 12 Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Eli ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. 13 Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀-òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun. 14 Nítorí náà, mo búra sí ilé Eli, ‘Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Eli ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé.’ ”

15 Samuẹli dùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀ nígbà náà ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, ó sì bẹ̀rù láti sọ ìran náà fún Eli. 16 Ṣùgbọ́n Eli pè é, ó sì wí pé, “Samuẹli, ọmọ mi.”

Samuẹli sì dáhùn pé, “Èmi nìyìí.”

17 Eli béèrè pé, “Kín ni ohun tí ó sọ fún ọ?” “Má ṣe fi pamọ́ fún mi. Kí Ọlọ́run mi ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ bá fi ohunkóhun tí ó wí fún ọ pamọ́ fún mi.” 18 Samuẹli sọ gbogbo rẹ̀ fún un, kò sì fi ohun kankan pamọ́ fún un. Nígbà náà Eli wí pé, “Òun ni Olúwa; jẹ́ kí ó ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.”

19 Olúwa wà pẹ̀lú Samuẹli bí ó ṣe ń dàgbà, kò sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kùnà. 20 Gbogbo Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba mọ̀ pé a ti fa Samuẹli kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì Olúwa.

Saamu 139:1-6

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

139 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,
    ìwọ sì ti mọ̀ mí.
Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
    ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
    gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
    kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
    ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
    ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.

Saamu 139:13-18

13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;
    ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;
    ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;
    èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
    nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
    Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi
    nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé:
    àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
ní ọjọ́ tí a dá wọn,
    nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
    iye wọn ti pọ̀ tó!
18 Èmi ìbá kà wọ́n,
    wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
nígbà tí mo bá jí,
    èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.

2 Kọrinti 4:5-12

Nítorí àwa kò wàásù àwa tìkára wa, bí kò ṣe Kristi Jesu Olúwa; àwa tìkára wa sì jẹ́ ẹrú yín nítorí Jesu. (A)Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó tan láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń tan mọ́lẹ̀ lọ́kàn wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jesu Kristi.

Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò amọ̀, kí ọláńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá. A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dààmú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù. A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run. 10 Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jesu Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jesu hàn pẹ̀lú lára wa. 11 Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fi àwa tí ó wà láààyè fún ikú nítorí Jesu, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú. 12 Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín.

Marku 2:23-3:6

Olúwa ọjọ́ ìsinmi

23 (A)(B) Ó sì ṣe ni ọjọ́ ìsinmi, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń kọjá lọ láàrín oko ọkà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya ìpẹ́ ọkà. 24 Díẹ̀ nínú àwọn Farisi wí fún Jesu pé, “Wò ó, èéṣe tiwọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi.”

25 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò ti ka ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí ó ṣe aláìní, tí ebi sì ń pa á, òun àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀? 26 (C)Bí ó tí wọ ilé Ọlọ́run lọ ni ọjọ́ Abiatari olórí àlùfáà, tí ó sì jẹ àkàrà ìfihàn ti kò tọ́ fún un láti jẹ bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà, ó sì tún fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.”

27 (D)Ó sì wí fún wọ́n pé, a dá ọjọ́ ìsinmi fún ènìyàn, “Ṣùgbọ́n a kò dá ènìyàn fún ọjọ́ ìsinmi. 28 Nítorí náà Ọmọ Ènìyàn ni Olúwa ọjọ́ ìsinmi pẹ̀lú.”

(E)Nígbà tí Jesu wá sí Sinagọgu. Sì kíyèsi i ọkùnrin kan wà níbẹ̀, tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. (F)Àwọn kan nínú wọn sì ń wa ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu, Nítorí náà, wọ́n ń ṣọ́ Ọ bí yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi. Jesu wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé, “Dìde dúró ní iwájú ìjọ ènìyàn.”

Nígbà náà ni Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ǹjẹ́ ó bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú! Láti gbà ẹ̀mí là, tàbí pa á run?” Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ láìfèsì.

Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá. (G)Lójúkan náà, àwọn Farisi jáde lọ, láti bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Herodu gbìmọ̀ pọ̀, bí wọn yóò ṣe pa Jesu.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.