Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
9 Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,
ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.
10 Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ,
nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.
11 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni;
kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.
12 Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;
òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.
13 Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!
Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,
14 Kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ
ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni
àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́;
ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.
16 A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀;
àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
17 Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,
àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
18 Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé,
ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.
19 Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí;
Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.
20 Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa;
jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela.
Dafidi nínú iṣẹ́ ẹ Saulu
14 Nísinsin yìí, ẹ̀mí Olúwa ti kúrò lára Saulu, ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa sì ń yọ ọ́ lẹ́nu.
15 Àwọn ìránṣẹ́ Saulu sì wí fún un pé, “Wò ó, ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń yọ ọ́ lẹ́nu. 16 Jẹ́ kí olúwa wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà níhìn-ín láti wa ẹnìkan tí ó lè fi dùùrù kọrin. Yóò sì ṣe é nígbà tí ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bá bà lé ọ, ìwọ yóò sì sàn.”
17 Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ wá ẹnìkan tí ó lè kọrin dáradára kí ẹ sì mú u wá fún mi.”
18 Ọ̀kan nínú ìránṣẹ́ náà dáhùn pé, “Èmi ti ri ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Jese ti Bẹtilẹhẹmu tí ó mọ orin kọ, ó jẹ́ alágbára àti ológun. Ó ní ọgbọ́n ọ̀rọ̀ òun sì dára ní wíwò. Olúwa sì wà pẹ̀lú u rẹ̀.”
19 Saulu sì rán oníṣẹ́ sí Jese wí pé, “Rán Dafidi ọmọ rẹ sí mi, ẹni tí ó ń ṣọ́ àgùntàn.” 20 Jese sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti a di ẹrù lé àti ìgò ọtí wáìnì àti ọmọ ewúrẹ́; ó sì rán wọn nípa ọwọ́ Dafidi ọmọ rẹ̀ sí Saulu.
21 Dafidi sì tọ Saulu lọ, ó sì dúró níwájú rẹ̀: òun sì fẹ́ ẹ gidigidi, Dafidi sì wá di ọ̀kan nínú àwọn tí ń ru ìhámọ́ra rẹ̀. 22 Nígbà náà ni Saulu ránṣẹ́ sí Jese pé, “Jẹ́ kí Dafidi dúró níwájú mi, nítorí tí ó wù mí.”
23 Ó sì ṣe, nígbà tí ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá bá dé sí Saulu, Dafidi a sì fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lára dùùrù: a sì san fún Saulu, ara rẹ̀ a sì dá; ẹ̀mí búburú náà a sì fi sílẹ̀.
Paulu kọjá ní Makedonia àti Giriki
20 Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Paulu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ sí Makedonia. 2 Nígbà tí ó sì tí la apá ìhà wọ̀nyí kọjá, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gbà wọ́n ní ìyànjú, ó wá sí ilẹ̀ Giriki. 3 Ó sì dúró níbẹ̀ ní oṣù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àti bá ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria, ó pinnu rẹ̀ láti gbà Makedonia padà lọ. 4 Sopateru ará Berea ọmọ Pirusi sì bá a lọ dé Asia, àti nínú àwọn ará Tẹsalonika, Aristarku àti Sekundu, àti Gaiu ará Dabe, àti Timotiu; Tikiku àti Tirofimu ará Asia.
A jí Eutiku dìde nínú òkú ní Troasi
5 Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí tí lọ síwájú, wọ́n dúró dè wá ni Troasi. 6 Àwa sì ṣíkọ̀ láti Filipi lọ lẹ́yìn àjọ àìwúkàrà, a sì dé ọ̀dọ̀ wọn ní Troasi ni ọjọ́ méje.
7 Ọjọ́ èkínní ọ̀sẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Paulu sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ọjọ́ kejì: ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárín ọ̀gànjọ́. 8 Fìtílà púpọ̀ sì wà ní iyàrá òkè náà, níbi tí wọn gbé péjọ sí. 9 Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní Eutiku sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára; bí Paulu sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lójú oorun, ó ṣubú láti òkè kẹta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú. 10 Nígbà tí Paulu sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbé e mọ́ra, ó ní, “Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu; nítorí tí òun wà láààyè.” 11 Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ. 12 Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà lọ sílẹ̀ láààyè, inú gbogbo wọn sì dùn lọ́pọ̀lọpọ̀.
Ìdágbére Paulu sí àwọn Alàgbà Efesu
13 Nígbà ti àwa sì ṣáájú, àwa sì ṣíkọ̀ lọ sì Asosi, níbẹ̀ ni a ti lérò láti gba Paulu sínú ọkọ̀: nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó tí pinnu rẹ̀, òun tìkára rẹ̀ ń fẹ́ bá ti ọ̀nà-ẹsẹ̀ lọ. 14 Nígbà tí ó sì pàdé wa ní Asosi, a gbà á sínú ọkọ̀, a sì wá sí Miletu. 15 Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, ní ọjọ́ kejì a dé ọ̀kánkán Kiosi; ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a dé Samosi, ni ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Miletu. 16 Paulu ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀ ojú omi kọjá sí Efesu, nítorí ki ó má ba à lo àkókò kankan ni Asia: nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣe é ṣe fún un láti wà ní Jerusalẹmu lọ́jọ́ Pentikosti.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.