Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
20 Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú;
kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.
2 Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́
kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.
3 Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ
kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela
4 Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ
kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ.
5 Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun
àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.
Kí Ọlọ́run kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.
6 Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé:
Olúwa pa ẹni ààmì òróró rẹ̀ mọ́.
Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá
pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
7 Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin,
ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.
8 Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú,
ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.
9 Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba!
Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!
Samuẹli fi Saulu bú
13 Saulu sì jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba lórí Israẹli ní ọdún méjìlélógójì.
2 Saulu yan ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ọkùnrin ní Israẹli, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Mikmasi àti ní ìlú òkè Beteli ẹgbẹ̀rún kan (1,000) sì wà lọ́dọ̀ Jonatani ní Gibeah ti Benjamini. Àwọn ọkùnrin tókù ni ó rán padà sí ilé e wọn.
3 Jonatani sì kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini ní Gibeah, Filistini sì gbọ́ èyí. Nígbà náà ni Saulu fọn ìpè yí gbogbo ilẹ̀ náà ká, ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́!” 4 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli sì gbọ́ ìròyìn pé, “Saulu ti kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini, Israẹli sì di òórùn búburú fún àwọn Filistini.” Àwọn ènìyàn náà sì péjọ láti darapọ̀ mọ́ Saulu ní Gilgali.
5 Àwọn Filistini kó ara wọn jọ pọ̀ láti bá Israẹli jà, pẹ̀lú ẹgbàá-mẹ́dógún kẹ̀kẹ́, (3,000) ẹgbẹ̀ta (6,000) ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, àwọn ológun sì pọ̀ bí yanrìn etí Òkun. Wọ́n sì gòkè lọ, wọ́n dó ní Mikmasi ní ìhà ilẹ̀ oòrùn Beti-Afeni. 6 Nígbà tí àwọn ọkùnrin Israẹli sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fi ara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàrín àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kànga gbígbẹ. 7 Àwọn Heberu mìíràn tilẹ̀ kọjá a Jordani sí ilẹ̀ Gadi àti Gileadi.
Saulu wà ní Gilgali síbẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń wárìrì fún ìbẹ̀rù. 8 Ó sì dúró di ọjọ́ méje, àkókò tí Samuẹli dá; ṣùgbọ́n Samuẹli kò wá sí Gilgali, àwọn ènìyàn Saulu sì bẹ̀rẹ̀ sí ní túká. 9 Saulu sì wí pé, “Ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún mi.” Saulu sì rú ẹbọ sísun náà. 10 Bí ó sì ti ń parí rírú ẹbọ sísun náà, Samuẹli sì dé, Saulu sì jáde láti lọ kí i.
11 Samuẹli sì wí pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí.”
Saulu sì dáhùn pé, “Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Filistini sì kó ara wọ́n jọ ní Mikmasi, 12 mo rò pé, ‘Àwọn Filistini yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ mí wá ní Gilgali nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ì tí ì wá ojúrere Olúwa.’ Báyìí ni mo mú ara mi ní ipá láti rú ẹbọ sísun náà.”
13 Samuẹli sì wí fún un pé, “Ìwọ hu ìwà aṣiwèrè, ìwọ kò sì pa òfin tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́; bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ìbá fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ lórí Israẹli láéláé. 14 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, Olúwa ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin Olúwa mọ́.”
15 Nígbà náà ni Samuẹli kúrò ní Gilgali, ó sì gòkè lọ sí Gibeah ti Benjamini, Saulu sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta.
Òwe afúnrúgbìn
4 (A)Jesu sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ni létí Òkun Àwọn ìjọ ènìyàn tí ó yí i ká pọ̀ jọjọ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, tí ó sì jókòó nínú rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun, nígbà tí àwọn ènìyàn sì wà ní ilẹ̀ létí Òkun. 2 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé: 3 “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀. 4 Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ. 5 Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hu jáde. 6 Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jóná, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ. 7 Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrín ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbàsókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúgbìn náà kò le so èso. 8 Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, o sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”
9 Jesu sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
10 (B)Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léèrè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?” 11 (C)Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láààyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà. 12 (D)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé,
“ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run.
Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”
13 (E)Ṣùgbọ́n Jesu wí fún wọn pé, “Bí òwe tí ó rọrùn yìí kò bá yé e yín? Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe mọ ìtumọ̀ àwọn mìíràn tí mo ń sọ fún un yín? 14 Afúnrúgbìn ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà. 15 Àwọn èso tó bọ́ sí ojú ọ̀nà, ni àwọn ọlọ́kàn líle tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lójúkan náà èṣù wá ó sì mú kí wọn gbàgbé ohun tí wọ́n ti gbọ́. 16 Bákan náà, àwọn tí ó bọ́ sórí àpáta, ni àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 17 Ṣùgbọ́n kò ni gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n á wà fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà nígbà ti wàhálà tàbí inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, lójúkan náà, wọ́n á kọsẹ̀. 18 Àwọn tí ó bọ́ sáàrín ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọn sì gbà á. 19 Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí àti ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso. 20 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà á lóòtítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.