Add parallel Print Page Options

10 (A)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bí i pé, “Èéṣe tí ìwọ ń fi òwe bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀?”

11 Ó sì da wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a ti fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wọn. 12 Ẹnikẹ́ni tí ó ní, òun ni a ó fún sí i, yóò sì ní lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n lọ́wọ́ ẹni tí kò ní, ni a ó ti gbà èyí kékeré tí ó ní náà. 13 Ìdí nìyìí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀:

“Ní ti rí rí, wọn kò rí;
    ní ti gbígbọ́ wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yé wọn.

14 (B)Sí ara wọn ni a ti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Isaiah ṣẹ:

“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọ́n kì yóò sì yé yín;
    ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye.
15 Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́
    etí wọn sì wúwo láti gbọ́
    ojú wọn ni wọ́n sì dì
nítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn rí
    kí wọ́n má ba à fi etí wọn gbọ́
    kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òye,
kí wọn má ba à yípadà, kí èmi ba à le mú wọn láradá.’

Read full chapter

(A)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Kí ni a lè mọ òwe yìí sí?” 10 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run; ṣùgbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn wọn yóò jẹ́ òwe, pé ní rí rí,

“ ‘kí wọn má ba à rí,
    àti ní gbígbọ́ kí ó má lè yé wọn.’

Read full chapter