Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Samuẹli 8:4-11

Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn àgbàgbà ti Israẹli péjọpọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama. Wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ ti di arúgbó, àwọn ọmọ rẹ kò sì rìn ní ọ̀nà rẹ: Nísinsin yìí, yan ọba fún wa kí ó lè máa darí wa gẹ́gẹ́ bí i tí gbogbo orílẹ̀-èdè.”

Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n wí pé, “Fún wa ní ọba tí yóò darí wa” Èyí kò tẹ́ Samuẹli lọ́rùn, ó sì gbàdúrà sí Olúwa. Olúwa sì sọ fún Samuẹli pé: “Gbọ́ ohùn àwọn ènìyàn náà, ní gbogbo èyí tí wọ́n sọ fún ọ; nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n Èmi ni wọ́n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí wọn. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde wá láti Ejibiti títí di ọjọ́ òní, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ń sin ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí ọ. Nísinsin yìí, gbọ́ tiwọn; ṣùgbọ́n kìlọ̀ fún wọn dáradára, kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ohun tí ọba tí yóò jẹ́ lórí wọn yóò ṣe.”

10 Samuẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa sí àwọn ọmọ ènìyàn tí ó ń béèrè fún ọba lọ́wọ́ rẹ̀. 11 Ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba tí yóò jẹ lórí yín yóò ṣe. Yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín, yóò sì mú wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti fún ẹlẹ́ṣin rẹ, wọn yóò sì máa sáré níwájú kẹ̀kẹ́ rẹ̀.

1 Samuẹli 8:12-15

12 Yóò yan díẹ̀ láti jẹ́ olórí ẹgbẹ̀rún àti olórí àádọ́ta àti àwọn mìíràn. Yóò yan wọ́n láti máa tulẹ̀ oko rẹ̀ àti láti máa kórè rẹ̀ àti àwọn mìíràn láti máa ṣe ohun èlò ogun àti ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. 13 Yóò mú àwọn ọmọbìnrin yín láti máa ṣe olùṣe ìkunra olóòórùn dídùn àti láti máa ṣe àsè àti láti máa ṣe àkàrà. 14 Yóò mú èyí tí ó dára jù nínú oko yín, àti nínú ọgbà àjàrà yín àti nínú igi olifi yín, yóò sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 15 Yóò mú ìdásímẹ́wàá hóró ọkà yín àti àká èso àjàrà yín, yóò sì fi fún àwọn oníṣẹ́ àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

1 Samuẹli 8:16-20

16 Àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín àti èyí tí ó dára jù nínú ẹran ọ̀sìn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín ni yóò mú fún ìlò ti ara rẹ̀. 17 Yóò sì mú ìdámẹ́wàá nínú àwọn agbo ẹran yín, yóò sì máa ṣe ẹrú u rẹ̀. 18 Tí ọjọ́ náà bá dé, ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ọba tí ẹ̀yin ti yàn. Olúwa kò sì ní dá a yín lóhùn ní ọjọ́ náà.”

19 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kọ̀ láti tẹ́tí sí Samuẹli wọ́n wí pé, “Rárá! A bí ìwọ fẹ́ jẹ́ ọba lórí i wa? 20 Nígbà náà àwa yóò dàbí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹ̀lú ọba láti darí i wa àti láti jáde lọ níwájú wa láti ja ogun wa.”

1 Samuẹli 11:14-15

14 Nígbà náà ni Samuẹli wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Gilgali, kí a lè fi ẹsẹ̀ Saulu múlẹ̀ bí ọba.” 15 Nítorí náà gbogbo ènìyàn lọ sí Gilgali, wọn sí fi Saulu jẹ ọba ní iwájú Olúwa. Níbẹ̀, ni wọn ti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ní iwájú Olúwa, Saulu àti gbogbo Israẹli ṣe àjọyọ̀ ńlá.

Saamu 138

Ti Dafidi

138 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;
    níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀
    èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ
nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;
    nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,
    ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.

Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,
    Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ
Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;
    nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.

Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;
    ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;
    ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;
    Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;
    Má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.

2 Kọrinti 4:13-5:1

13 (A)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ pé, “Èmi gbàgbọ́, nítorí náà ni èmi ṣe sọ,” pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan náà, a tún gbàgbọ́ àti nítorí náà ni àwa sì ṣe ń sọ. 14 (B)Àwa mọ̀ pé, ẹni tí o jí Jesu Olúwa dìde yóò sì jí wa dìde pẹ̀lú nípa Jesu, yóò sì mú wa wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú yín 15 Nítorí tiyín ní gbogbo rẹ̀, ki ọ̀pẹ lè dí púpọ̀ fún ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ ti ń gbòòrò sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.

16 Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́. 17 Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayé tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa. 18 Níwọ́n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.

Ibùgbé wa ọrun

Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run.

Marku 3:20-35

Jesu àti Beelsebulu

20 (A)Nígbà náà ni Jesu sì wọ inú ilé kan, àwọn èrò sì tún kórajọ, tó bẹ́ẹ̀ tí Òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò rí ààyè láti jẹun. 21 (B)Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wá láti mú un lọ ilé, nítorí tí wọn wí pé, “Orí rẹ̀ ti dàrú.”

22 (C)(D) Àwọn olùkọ́ni ní òfin sọ̀kalẹ̀ wá láti Jerusalẹmu, wọ́n sì wí pé, “Ó ni Beelsebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde!”

23 Jesu pè wọ́n, ó sì fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀: “Báwo ni Èṣù ṣe lè lé èṣù jáde? 24 Bí ìjọba kan bá yapa sí ara rẹ̀, ìjọba náà yóò wó lulẹ̀. 25 Bákan náà, bí ilé kan bá sì yapa sí ara rẹ, ilé náà kí yóò le è dúró. 26 Bí Èṣù bá sì dìde sí ara rẹ̀, tí ó sì yapa, òun kí yóò le è dúró ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ yóò dé. 27 (E)Kò sí ẹni tí ó le wọ ilé ọkùnrin alágbára kan lọ, kí ó sì kó o ní ẹrù lọ, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà ní okùn, nígbà náà ni yóò lè kó ẹrù ní ilé rẹ̀. 28 (F)Lóòótọ́ ní mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a ó dáríjì àwọn ọmọ ènìyàn, àti gbogbo ọ̀rọ̀-òdì. 29 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, kì yóò rí ìdáríjì títí ayé, ṣùgbọ́n ó wà nínú ewu ẹ̀bi àìnípẹ̀kun.”

30 Òun sọ eléyìí fún wọn, nítorí tí wọ́n sọ pé, “Nípa agbára ẹ̀mí àìmọ́ ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.”

Ìyá àti àwọn Arákùnrin Jesu

31 (G)Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìyá wá, wọ́n dúró lóde, wọ́n sì ránṣẹ́ sí i, wọ́n ń pè é. 32 Àwọn ènìyàn tí wọ́n jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ wà lóde.”

33 Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn wí pé, “Ta ni í ṣe ìyá mi tàbí àwọn arákùnrin mi?”

34 Ó sì wò gbogbo àwọn tí ó jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ yíká, ó sì wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi: 35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, òun ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.