Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 9:9-20

Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,
    ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.
10 Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ,
    nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.

11 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni;
    kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.
12 Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;
    òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.

13 Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!
    Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,
14 Kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ
    ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni
    àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.

15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́;
    ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.
16 A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀;
    àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
17 Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,
    àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
18 Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé,
    ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.

19 Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí;
    Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.
20 Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa;
    jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela.

1 Samuẹli 18:1-4

Saulu ń jowú Dafidi

18 Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá Saulu sọ, ọkàn Jonatani di ọ̀kan pẹ̀lú ti Dafidi, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀. Láti ọjọ́ náà Saulu pa Dafidi mọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì jẹ́ kí ó padà sí ilé baba rẹ̀ mọ́. Jonatani bá Dafidi dá májẹ̀mú nítorí tí ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀. Jonatani sì bọ́ aṣọ ìgúnwà, ó sì fi fun Dafidi pẹ̀lú aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ àti pẹ̀lú idà rẹ̀, ọrun rẹ̀ àti àmùrè rẹ̀.

Luku 21:25-28

25 (A)(B) “Ààmì yóò sì wà ní oorun, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpayà híhó Òkun àti ìgbì omi. 26 Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì. 27 (C)Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 28 (D)Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.