Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 130

Orin fún ìgòkè.

130 Láti inú ibú wá ni
    èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa
Olúwa, gbóhùn mi,
    jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

(A)Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,
    Olúwa, tá ni ìbá dúró.
Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,
    kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.

Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,
    àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí
Ọkàn mi dúró de Olúwa,
    ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,
    àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.

Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:
    nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,
    àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.
Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè
    kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.

1 Samuẹli 19:18-24

18 Nígbà tí Dafidi ti sálọ tí ó sì ti bọ́, ó sì lọ sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama ó sì sọ gbogbo ohun tí Saulu ti ṣe fún un. Òun àti Samuẹli lọ sí Naioti láti dúró níbẹ̀. 19 Ọ̀rọ̀ sì tọ Saulu wá pé, “Dafidi wà ní Naioti ní Rama,” 20 Saulu sì rán àwọn ènìyàn láti fi agbára mú Dafidi wá ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Samuẹli dúró níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí, ẹ̀mí Ọlọ́run sì wá sórí àwọn arákùnrin Saulu àwọn náà sì ń sọtẹ́lẹ̀. 21 Wọ́n sì sọ fún Saulu nípa rẹ̀, ó sì rán ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn lọ àwọn náà sì ń sọtẹ́lẹ̀. Saulu tún rán oníṣẹ́ lọ ní ìgbà kẹta, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní sọtẹ́lẹ̀. 22 Nígbẹ̀yìn, òun fúnrarẹ̀ sì lọ sí Rama ó sì dé ibi àmù ńlá kan ní Seku. Ó sì béèrè, “Níbo ni Samuẹli àti Dafidi wà?”

Wọ́n wí pé, “Wọ́n wà ní ìrékọjá ní Naioti ní Rama.”

23 (A)Saulu sì lọ sí Naioti ni Rama. Ṣùgbọ́n, ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e lórí ó sì ń lọ lọ́nà, ó sì ń sọtẹ́lẹ̀ títí tí ó fi dé Naioti. 24 (B)Ó sì bọ́ aṣọ rẹ̀, òun pẹ̀lú sì ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú Samuẹli. Ó sì dùbúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà àti ní òru. Ìdí nìyìí tí àwọn ènìyàn fi wí pé, “Ṣé Saulu náà wà lára àwọn wòlíì ni?”

2 Kọrinti 7:2-16

Ayọ̀ Paulu

(A)Ẹ gbà wá tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹ́ni, a kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́, a kò rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. (B)Èmi kò sọ èyí láti dá a yín lẹ́bi; nítorí mo tí wí ṣáájú pé, ẹ̀yin wà nínú ọkàn wa kí a lè jùmọ̀ kú, àti kí a lè jùmọ̀ wà láààyè. Mo ní ìgboyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa.

(C)Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedonia, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú. (D)Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Titu dé; Kì í sì i ṣe nípa dídé rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n nípa ìtùnú náà pẹ̀lú tí ẹ ti tù ú nínú, nígbà tí ó ròyìn fún wa ìfẹ́ àtọkànwá yín, ìbànújẹ́ yín, àti ìtara yín fún mi; bẹ́ẹ̀ ní mo sì túbọ̀ yọ̀.

(E)Nítorí pé, bí mo tilẹ̀ ba inú yín jẹ́ nípa ìwé tí mo kọ èmi kò kábámọ̀ mọ́, bí mo tilẹ̀ ti kábámọ̀ tẹ́lẹ̀ rí; nítorí tí mo wòye pé ìwé mi mú yín banújẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀. Èmi yọ̀ nísinsin yìí, kì í ṣe nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́, ṣùgbọ́n nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́ sí ìrònúpìwàdà: nítorí ti a mú inú yín bàjẹ́ bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, kí ẹ̀yin má ṣe ti ipasẹ̀ wa pàdánù ní ohunkóhun. 10 Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run a máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá: ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú. 11 Kíyèsi i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúraṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ńkọ́, ìbànújẹ́ ńkọ́, ìpayà ńkọ́, ìfojúṣọ́nà ńkọ́, ìtara ńkọ́, ìjẹ́ni-níyà ńkọ́. Nínú ohun ààmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà. 12 (F)Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ tí kọ̀wé sí yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí ẹni tí ó ṣe ohun búburú náà tàbí nítorí ẹni ti a fi ohun búburú náà ṣe, ṣùgbọ́n kí àníyàn yín nítorí wá lè farahàn níwájú Ọlọ́run. 13 Nítorí náà, a tí fi ìtùnú yín tù wá nínú.

Àti nínú ìtùnú wa, a yọ̀ gidigidi nítorí pé Titu ní ayọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ gbogbo yín ni a ti tu ẹ̀mí rẹ̀ lára. 14 Bí mo tilẹ̀ ti lérí ohunkóhun fún ún nítorí yín, a kò dójútì mí; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwa ti sọ ohun gbogbo fún yín ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìlérí wá níwájú Titu sì jásí òtítọ́. 15 Ọkàn rẹ̀ sì fà gidigidi sí yín, bí òun ti ń rántí ìgbọ́ràn gbogbo yín, bí ẹ ti fi ìbẹ̀rù àti ìwárìrì tẹ́wọ́gbà á. 16 Mo yọ̀ nítorí pé ní ohun gbogbo, mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.