Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
6 (A)Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ,
ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.
7 Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú
nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ,
nípa fífi ààmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.
8 Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia;
láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe
orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.
9 Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba
wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀,
ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró
nínú wúrà ofiri.
10 Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi
gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ
11 Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi
nítorí òun ni olúwa rẹ
kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.
12 Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn
àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.
13 Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀,
iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀.
14 Nínú aṣọ olówó iyebíye ni a mú un tọ́ ọba wá,
àwọn wúńdíá ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé e, wọ́n sí mú un tọ̀ ọ́ wá.
15 Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn
wọ́n sì wọ ààfin ọba.
16 Ọmọ rẹ̀ ni yóò gba ipò baba rẹ̀
ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.
17 Èmí yóò máa rántí orúkọ rẹ̀ ní ìran gbogbo,
nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.
Orúkọ Sioni tuntun
62 Nítorí Sioni èmi kì yóò dákẹ́,
nítorí i Jerusalẹmu èmi kì yóò sinmi ẹnu,
títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀,
àti ìgbàlà rẹ̀ bí i fìtílà tí ń jó geere.
2 (A)Àwọn orílẹ̀-èdè yóò rí òdodo rẹ,
àti gbogbo ọba ògo rẹ
a ó sì máa pè ọ́ ní orúkọ mìíràn
èyí tí ẹnu Olúwa yóò fi fún un.
3 Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ Olúwa,
adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ.
4 Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́
tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro.
Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfsiba,
àti ilẹ̀ rẹ ní Beula;
nítorí Olúwa yóò yọ́nú sí ọ
àti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.
5 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwó
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwó
Gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lórí rẹ.
Ẹ̀rí Johanu nípa Jesu
22 (A)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Judea; ó sì dúró pẹ̀lú wọn níbẹ̀ ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún ni. 23 Johanu pẹ̀lú sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi ní Aenoni, ní agbègbè Salimu, nítorí tí omi púpọ̀ wà níbẹ̀: wọ́n sì ń wá, a sì ń tẹ̀ ẹ́ wọn bọ omi. 24 (B)Nítorí tí a kò tí ì sọ Johanu sínú túbú. 25 Nígbà náà ni iyàn kan wà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti Júù kan nípa ti ìwẹ̀nù. 26 (C)Wọ́n sì tọ Johanu wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Rabbi, ẹni tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ lókè odò Jordani, tí ìwọ ti jẹ́rìí rẹ̀, wò ó, òun tẹ àwọn ènìyàn bọ omi, gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá.”
27 (D)Johanu dáhùn ó sì wí pé, “Ènìyàn kò le rí nǹkan kan gbà, bí kò ṣe pé a bá ti fi fún ún láti ọ̀run wá. 28 (E)Ẹ̀yin fúnrayín jẹ́rìí mi pé mo wí pé, ‘Èmi kì í ṣe Kristi náà, ṣùgbọ́n pé a rán mi síwájú rẹ̀.’ 29 (F)Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó; nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún. 30 Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàìmá rẹlẹ̀.
31 (G)“Ẹni tí ó ti òkè wá ju gbogbo ènìyàn lọ; ẹni tí ó ti ayé wá ti ayé ni, a sì máa sọ ohun ti ayé. Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ju gbogbo ènìyàn lọ. 32 (H)Ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́ èyí náà sì ni òun ń jẹ́rìí rẹ̀; kò sì sí ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀. 33 Ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ fi èdìdì dì í pé, olóòtítọ́ ni Ọlọ́run. 34 Nítorí ẹni tí Ọlọ́run ti rán ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí tí Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún un láìsí gbèdéke. 35 Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́ 36 (I)Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun: ẹni tí kò bá sì gba Ọmọ gbọ́, kì yóò rí ìyè; nítorí ìbínú Ọlọ́run ń bẹ lórí rẹ̀.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.