Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
47 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn
ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.
2 Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó
ọba ńlá lórí gbogbo ayé.
3 Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa
àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa
4 Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa
ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.
5 Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀,
Olúwa ti òun ti ariwo ìpè.
6 Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn.
Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn!
7 Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé,
ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu!
8 Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;
Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.
9 Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu
nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni,
òun ni ó ga jùlọ.
Ikú Mose
34 Nígbà náà ni Mose gun òkè Nebo láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu sí orí Pisga tí ó dojúkọ Jeriko. Níbẹ̀ ni Olúwa ti fi gbogbo ilẹ̀ hàn án láti Gileadi dé Dani, 2 gbogbo Naftali, ilẹ̀ Efraimu àti Manase, gbogbo ilẹ̀ Juda títí dé Òkun ìwọ̀-oòrùn, 3 gúúsù àti gbogbo Àfonífojì Jeriko, ìlú ọlọ́pẹ dé Soari. 4 Nígbà náà ní Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí mo ṣèlérí lórí ìbúra fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu nígbà tí mo wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’ Mo ti jẹ́ kí o rí i pẹ̀lú ojú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò dé bẹ̀.”
5 Bẹ́ẹ̀ ni Mose ìránṣẹ́ Olúwa kú ní ilẹ̀ Moabu, bí Olúwa ti wí. 6 Ó sì sin ín nínú àfonífojì ní ilẹ̀ Moabu, ní òdìkejì Beti-Peori, ṣùgbọ́n títí di òní yìí, kò sí ẹnìkan tí ó mọ ibi tí ibojì i rẹ̀ wà. 7 Mose jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún nígbà tí ó kú, síbẹ̀ ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù.
4 Ṣùgbọ́n nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, pé nígbà tí wákàtí wọn bá dé, kí ẹ lè rántí wọn pé mo ti wí fún yín. Ṣùgbọ́n èmi kò sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá, nítorí tí mo wà pẹ̀lú yín.
Iṣẹ́ ẹ̀mí mímọ́
5 (A)“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi; kò sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó bi mí lérè pé, ‘Níbo ni ìwọ ń lọ?’ 6 Ṣùgbọ́n nítorí mo sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín, ìbìnújẹ́ kún ọkàn yín. 7 (B)Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ń sọ fún yín; àǹfààní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ: nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá; ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín. 8 Nígbà tí òun bá sì dé, yóò fi òye yé aráyé ní ti ẹ̀ṣẹ̀, àti ní ti òdodo, àti ní ti ìdájọ́: 9 (C)ní ti ẹ̀ṣẹ̀, nítorí tí wọn kò gbà mí gbọ́; 10 (D)Ní ti òdodo, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ̀yin kò sì mọ̀ mí; 11 (E)Ní ti ìdájọ́, nítorí tí a ti ṣe ìdájọ́ ọmọ-aládé ayé yìí.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.