Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
12 Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀,
àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀.
13 Olúwa wò láti ọ̀run wá;
Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.
14 Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́
Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé
15 ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,
ó sì kíyèsi ìṣe wọn.
16 A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun;
kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀.
17 Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun;
bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀.
18 Wò ó, ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin.
19 Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú
àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn.
20 Ọkàn wa dúró de Olúwa;
òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa.
21 Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀,
nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́.
22 Kí àánú rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa,
àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.
Ọlọ́run kì í pọ́n ni lójú láìnídìí
37 “Àyà sì fò mi sí èyí pẹ̀lú,
ó sì kúrò ní ipò rẹ̀.
2 Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀,
àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.
3 Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo,
Mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.
4 Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù;
ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá.
Òhun kì yóò sì dá àrá dúró,
nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.
5 Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu;
ohùn ńláńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.
6 Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’
àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’
7 Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀,
ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.
8 Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ,
wọn a sì wà ni ipò wọn.
9 Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá,
àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.
10 Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni,
ibú omi á sì súnkì.
11 Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo,
a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.
12 Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀,
kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun
tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.
13 Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀,
tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
50 Ará, ǹjẹ́ èyí ní mo wí pé, ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kò lé jogún àìdíbàjẹ́. 51 Kíyèsi í, ohun ìjìnlẹ̀ ni mo sọ fún un yín: gbogbo wá kì yóò sùn, ṣùgbọ́n gbogbo wá ní a ó paláradà, 52 Lọ́gán, ni ìṣẹ́jú kan, nígbà ìpè ìkẹyìn: nítorí ìpè yóò dún, a ó sì jí àwọn òkú dìde ní àìdíbàjẹ́, a ó sì pa wá láradà. 53 Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé ara àìkú wọ̀. 54 (A)Ṣùgbọ́n nígbà tí ará ìdíbàjẹ́ yìí bá ti gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, ti ara kíkú yìí bá sí ti gbé àìkú wọ̀ bẹ́ẹ̀ tan, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ ti a kọ yóò ṣẹ pé, “A gbé ikú mí ní ìṣẹ́gun.”
55 “Ikú, oró rẹ dà?
Ikú, ìṣẹ́gun rẹ́ dà?”
56 Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀; àti agbára ẹ̀ṣẹ̀ ni òfin 57 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fì ìṣẹ́gun fún wá nípa Olúwa wá Jesu Kristi!
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.