Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
6 (A)Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ,
ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.
7 Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú
nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ,
nípa fífi ààmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.
8 Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia;
láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe
orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.
9 Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba
wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀,
ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró
nínú wúrà ofiri.
10 Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi
gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ
11 Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi
nítorí òun ni olúwa rẹ
kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.
12 Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn
àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.
13 Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀,
iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀.
14 Nínú aṣọ olówó iyebíye ni a mú un tọ́ ọba wá,
àwọn wúńdíá ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé e, wọ́n sí mú un tọ̀ ọ́ wá.
15 Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn
wọ́n sì wọ ààfin ọba.
16 Ọmọ rẹ̀ ni yóò gba ipò baba rẹ̀
ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.
17 Èmí yóò máa rántí orúkọ rẹ̀ ní ìran gbogbo,
nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.
Hosea bá ìyàwó rẹ làjà
3 Olúwa sì wí fún mi pé, “Tun lọ fẹ́ obìnrin kan tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, àti panṣágà, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Olúwasì àwọn ọmọ Israẹli tí ń wo àwọn ọlọ́run mìíràn, tí wọ́n sì ń fẹ́ àkàrà èso àjàrà.”
2 Nítorí náà, mo sì rà á padà ní ṣékélì fàdákà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti homeri kan àti lẹ́tékì barle kan. 3 Mo sì sọ fún un pé, “Ìwọ gbọdọ̀ máa gbé pẹ̀lú mi fún ọjọ́ pípẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè mọ́ tàbí kí o fẹ́ ọkùnrin mìíràn, èmi náà yóò sì gbé pẹ̀lú rẹ.”
4 Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láìní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́, láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan. 5 Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò padà láti wá Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dafidi ọba wọn. Wọn yóò sì wá síwájú Olúwa pẹ̀lú ẹ̀rù, wọn ó sì jọ̀wọ́ ara wọn fún Olúwa àti ìbùkún rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.
23 Mo sì pe Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí ọkàn mi pé nítorí àti dá yín sí ní èmi kò ṣe padà sí Kọrinti. 24 Kì í ṣe nítorí tí àwa jẹ gàba lórí ìgbàgbọ́ yín: ṣùgbọ́n àwa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú yín fún ayọ̀ yín nítorí nípa ìgbàgbọ́ ni ẹ̀yin dúró ṣinṣin. 2 1 Nítorí náà mo tí pinnu nínú ara mí pé, èmi kì yóò tún fi ìbànújẹ́ tọ̀ yin wá. 2 Nítorí pé bí èmi bá mú inú yín bàjẹ́, ǹjẹ́ ta ni ẹni ti ìbá mú inú mí dùn ní àkókò tí inú mi bá bàjẹ́ bí kò ṣe ẹni tí mo ti ba nínú jẹ́? 3 Èmi sì kọ̀wé bí mo tí kọ sí yín pé, nígbà tí mo bá sì de, kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ti ìbá mú mi ní ayọ̀: nítorí tí mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú gbogbo yín, wí pé ẹ̀yin yóò jẹ́ alábápín ayọ̀ mi. 4 Nítorí pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà àti ìrora ọkàn mí ni mo ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ omijé kọ̀wé sí yín; kì í ṣe nítorí kí a lè bà yín nínú jẹ́, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin bá a lè mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó.
Ìdáríjì fún ẹlẹ́ṣẹ̀
5 Bí ẹnikẹ́ni bá fa ohun ìbànújẹ́ kì í ṣe èmi ni ó bà nínú jẹ́, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnrayín, níwọ̀n ìyówù kí ó jẹ́; n kò fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà líle jù. 6 Ìyà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fi jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tó fún un. 7 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ìbá kúkú dáríjì í, kí ẹ sí tù ú nínú ní gbogbo ọ̀nà, kí ìbànújẹ́ má bà á bo irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀. 8 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìdánilójú ìfẹ́ yín hàn sí irú ẹni náà. 9 Ìdí tí mo ṣe kọ̀wé ni kí èmi ba à lè rí ẹ̀rí dìímú nípa ìgbọ́ràn yín nínú ohun gbogbo. 10 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi pẹ̀lú dáríjì í. Ohun tí èmi pẹ̀lú bá fi jì, nítorí tiyín ní mo fi jì níwájú Kristi. 11 Kí Satani má ba à rẹ́ wa jẹ. Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ́ àrékérekè rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.