Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 115

115 Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa,
    ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún,
    fún àánú àti òtítọ́ rẹ.

Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé,
    níbo ni Ọlọ́run wa wà.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run:
    tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.
(A)Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
    iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni,
Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀,
    wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀:
    wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn
Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó,
    wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn;
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn.
Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn;
    gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.

Ìwọ Israẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
10 Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn
11 Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa:
    òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn.

12 Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé Israẹli;
    yóò bùkún ilé Aaroni.
13 (B)Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
    àti kékeré àti ńlá.

14 Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú,
    ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
15 Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa
    ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.

16 Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa:
    ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn.
17 Òkú kò lè yìn Olúwa,
    tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́.
18 Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa
    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

Ẹ yin Olúwa.

Numeri 8:5-22

Ìyàsọ́tọ̀ àwọn ọmọ Lefi

Olúwa sọ fún Mose pé: (A)“Yọ àwọn ọmọ Lefi kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́. Báyìí ni kí o ṣe wẹ̀ wọ́n mọ́: Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, mú kí wọn ó fá irun ara wọn, kí wọn ó fọ aṣọ wọn, kí wọn ó ba à lè wẹ ara wọn mọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ kí wọn ó mú akọ ọ̀dọ́ màlúù pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ tí í ṣe ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò, kí ìwọ náà mú akọ ọ̀dọ́ màlúù kejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Ìwọ ó sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú àgọ́ ìpàdé, kí o sì kó gbogbo àpapọ̀ ọmọ Israẹli jọ síbẹ̀ pẹ̀lú. 10 Báyìí ni kí o mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa, gbogbo ọmọ Israẹli yóò sì gbọ́wọ́ lé àwọn ọmọ Lefi lórí. 11 Aaroni yóò sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli wá, kí wọn lè máa ṣiṣẹ́ Olúwa.

12 “Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Lefi bá gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ ọmọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun sí Olúwa, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Lefi. 13 Mú kí àwọn ọmọ Lefi dúró níwájú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí ó sì gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì sí Olúwa. 14 Báyìí ni ìwọ yóò ṣe ya ọmọ Lefi sọ́tọ̀, kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, àwọn ọmọ Lefi yóò sì jẹ́ tèmi.

15 “Lẹ́yìn tí ó ti wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, tí ó sì ti gbé wọn kalẹ̀ bí ẹbọ fífì nígbà náà ni kí wọn ó lọ máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. 16 Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátápátá nínú àwọn ọmọ Israẹli. Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkùnrin gbogbo Israẹli. 17 Nítorí pé gbogbo àkọ́bí ọmọ lọ́kùnrin ní Israẹli jẹ́ tèmi, ti ènìyàn àti ti ẹranko, láti ọjọ́ tí mo ti pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ara mi. 18 (B)Mo sì ti gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí ọmọ ọkùnrin nínú Israẹli 19 Nínú Israẹli, mo fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé fun àwọn ọmọ Israẹli àti láti máa ṣe ètùtù fún wọn kí àjàkálẹ̀-ààrùn má ba à kọlu àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi mímọ́.”

20 Mose, Aaroni àti gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì ṣe fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 21 Àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Aaroni sì mú wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú Olúwa, Aaroni sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́. 22 Lẹ́yìn èyí àwọn ọmọ Lefi lọ sínú àgọ́ ìpàdé láti lọ máa ṣiṣẹ́ wọn lábẹ́ àbojútó Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n ṣe fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Titu 1:1-9

Paulu, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti aposteli Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run àti ìmọ̀ òtítọ́ irú èyí tí í máa darí ènìyàn sí ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run— ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí ó dúró lórí ìrètí iyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run tí kì í purọ́ ti ṣe ìlérí rẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀, àti pé ní àkókò tirẹ̀, òun ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn nínú ìwàásù tí a fi lé mi lọ́wọ́ nípa àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa.

(A)Sí Titu, ọmọ mi tòótọ́ nínú ìgbàgbọ́ wa kan náà.

Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Kristi Jesu Olùgbàlà wa.

Iṣẹ́ Titu sí Krete

Ìdí tí mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Krete ni pé kí o lè ṣe àṣepé àwọn iṣẹ́ tó ṣẹ́kù. Mo sì ń rọ̀ ọ́ kí o yan àwọn alàgbà ní ìlú kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí mo ṣe darí rẹ̀. Ẹni tí yóò jẹ́ alàgbà gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onìyàwó kan, ọmọ wọn náà gbọdọ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí kò ní ẹ̀sùn ìwà ipá tàbí ẹ̀sùn àìgbọ́ràn kankan. Alábojútó jẹ́ ẹni tí a gbé iṣẹ́ Ọlọ́run lé lọ́wọ́, nítorí náà, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kankan tàbí agbéraga, oníjà, kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí tàbí alágídí tàbí olójúkòkòrò. Wọ́n ní láti jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, olùfẹ́ ohun tí ó dára. Wọ́n ní láti jẹ́ ẹni tí ó kò ara rẹ̀ ní ìjánu, ẹni dúró ṣinṣin, ọlọ́kàn mímọ́, àti ẹni oníwàtítọ́. Ó gbọdọ̀ di ẹ̀kọ́ nípa ìdúró ṣinṣin mú dáradára gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ ọ, kí ó lè fi ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Nípa èyí, yóò lè fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀ fún àwọn alátakò.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.