Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 29

Saamu ti Dafidi.

29 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
    Ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.
Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;
    sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;
    Ọlọ́run ògo sán àrá,
    Olúwa san ara.
Ohùn Olúwa ní agbára;
    ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
Ohùn Olúwa fa igi kedari;
    Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.
Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,
    àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.
Ohùn Olúwa ń ya
    bí ọwọ́ iná mọ̀nà
Ohùn Olúwa ń mi aginjù.
    Olúwa mi aginjù Kadeṣi.
Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,
    ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.
Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”

10 Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;
    Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.
11 Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;
    bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.

Isaiah 2:1-5

Òkè Olúwa

Èyí ni ohun tí Isaiah ọmọ Amosi rí nípa Juda àti Jerusalẹmu:

(A)Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́

òkè tẹmpili Olúwa ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀
    gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè,
a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ,
    gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé,

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa,
    àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu.
Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,
    kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.”
Òfin yóò jáde láti Sioni wá,
    àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.
Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
    yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.
Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀,
    wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.
Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́,
    bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.

Wá, ẹ̀yìn ará ilé e Jakọbu,
    ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa.

Romu 8:9-11

(A)Ṣùgbọ́n ẹyin kò sí nínú ti ara, bí kò ṣe nínú ti Ẹ̀mí, bí ó bá ṣe pé Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín, Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá ní Ẹ̀mí Kristi, òun kò sí nínú ẹni tirẹ̀. 10 (B)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristi ń gbé inú yín síbẹ̀síbẹ̀, ara yín jẹ́ òkú nítorí ẹ̀ṣẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú yín yóò fún yín ní ìyè, nítorí ó ti fún un yín ní òdodo. 11 (C)Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jesu kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, ẹni tí ó jí Kristi Jesu dìde kúrò nínú òkú, yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ tí ń gbé inú yín sọ ara kíkú yín di ààyè pẹ̀lú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.