Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu ti Dafidi.
29 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
Ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.
2 Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;
sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.
3 Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;
Ọlọ́run ògo sán àrá,
Olúwa san ara.
4 Ohùn Olúwa ní agbára;
ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
5 Ohùn Olúwa fa igi kedari;
Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.
6 Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,
àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.
7 Ohùn Olúwa ń ya
bí ọwọ́ iná mọ̀nà
8 Ohùn Olúwa ń mi aginjù.
Olúwa mi aginjù Kadeṣi.
9 Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,
ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.
Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”
10 Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;
Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.
11 Kí Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;
bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.
15 Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀
àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀
ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀.
16 Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀,
Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.
17 Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn,
àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.
18 Ègbé ni fún àwọn tí ń fi ohun asán fa ẹ̀ṣẹ̀,
àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹ̀sìn fa ẹsẹ̀,
19 sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá,
jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i,
jẹ́ kí ó súnmọ́ bí
jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé,
kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”
20 Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi,
tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn,
tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò.
21 Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn
tí wọ́n jáfáfá lójú ara wọn.
22 Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímu
àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí,
23 tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́.
24 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko run
àti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná,
bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà
tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku:
nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀
wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli.
Ayé kórìíra àwọn ọmọ-ẹ̀yìn
18 (A)“Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé, ó ti kórìíra mi ṣáájú yín. 19 Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ń ṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ yin bi àwọn tirẹ̀; gẹ́gẹ́ bi o ṣe ri tí ẹ̀yin kì ń ṣe ti ayé, ṣùgbọ́n èmi ti yàn yín kúrò nínú ayé, nítorí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín. 20 (B)Ẹ rántí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín pé, ‘Ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju olúwa rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n ó ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú: bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n ó sì pa tiyín mọ́ pẹ̀lú.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.