Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Samuẹli 7:1-14

Ìlérí Ọlọ́run si Dafidi

(A)Ó sì ṣe, nígbà tí ọba ń gbé ní ilé rẹ̀, tí Olúwa sì fún un ní ìsinmi yíkákiri kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ọba sì wí fún Natani wòlíì pé, “Sá wò ó: èmi ń gbé inú ilẹ̀ tí a fi kedari kọ́, ṣùgbọ́n àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ń gbé inú ibi tí a fi aṣọ gé.”

Natani sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”

Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọ̀ fún Dafidi láti kọ́ tẹmpili

Ó sì ṣe ní òru náà, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Natani wá pé:

“Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé. Nítorí pé, èmi kò ì ti gbé inú ilé kan láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ọmọ Israẹli gòkè ti ilẹ̀ Ejibiti wá, títí di òní yìí, ṣùgbọ́n èmi ti ń rìn nínú àgọ́, fún ibùgbé mi. Ní ibi gbogbo tí èmi ti ń rìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ǹjẹ́ èmi ti bá ọ̀kan nínú ẹ̀yà Israẹli, tí èmi pa àṣẹ fún láti máa bọ́ àwọn ènìyàn mi àní Israẹli, sọ̀rọ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi kedari kọ́ ilé fún mi.” ’

“Ǹjẹ́, nítorí náà, báyìí ni ìwọ yóò sì wí fún ìránṣẹ́ mi àní Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ti mú ìwọ kúrò láti inú agbo àgùntàn wá láti má tẹ̀lé àwọn àgùntàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli. Èmi sì wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí ìwọ ń lọ, èmi sá à gé gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ, èmi sì ti sọ orúkọ rẹ di ńlá, gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá tí ó wà ní ayé. 10 Èmi ó sì yan ibìkan fún àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi ó sì gbìn wọ́n, wọn ó sì má gbé bí ibùjókòó tiwọn, wọn kì yóò sì sípò padà mọ́; àwọn ọmọ ènìyàn búburú kì yóò sì pọ́n wọn lójú mọ́, bí ìgbà àtijọ́. 11 Àti gẹ́gẹ́ bí àkókò ìgbà tí èmi ti fi àṣẹ fún àwọn onídàájọ́ lórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi fi ìsinmi fún ọ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ.

“ ‘Olúwa sì wí fún ọ pé Olúwa yóò kọ ilé kan fún ọ: 12 Nígbà tí ọjọ́ rẹ bá pé, tí ìwọ ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ lékè lẹ́yìn rẹ, èyí tí ó ti inú rẹ jáde wá, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀. 13 Òun ó sì kọ́ ilé fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ láéláé. 14 (B)Èmi ó máa ṣe baba fún un, òun yóò sì máa jẹ́ ọmọ mi. Bí òun bá dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì fi ọ̀pá ènìyàn nà án, àti ìnà àwọn ọmọ ènìyàn.

Saamu 89:20-37

20 (A)Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi;
    pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án;
21 Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀
    apá mí yóò sì fi agbára fún un.
22 Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀,
    àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀
23 Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ
    èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀
24 Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ
    àti ní orúkọ mi ni a ó gbé ìwo rẹ ga.
25 Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí Òkun
    àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ lórí àwọn odo ńlá
26 Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’
27 (B)Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi,
    Ẹni gíga ju àwọn ọba ayé.
28 Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un,
    àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.
29 Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,
    àti ìtẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.

30 “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀
    tí wọn kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi.
31 Tí wọn bá ba ìlànà mi jẹ́
    tí wọn kò sì pa àṣẹ mi mọ́,
32 Nígbà náà ni èmi ó fì ọ̀gọ̀ bẹ ìrékọjá wọn wò;
    àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú pàṣán:
33 Ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò jẹ́ kí òtítọ́ mi kí ó yẹ̀.
34 Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mi,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde padà.
35 Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra;
èmi kì yóò purọ́ fún Dafidi.
36 Irú-ọmọ rẹ yóò dúró títí láé,
    àti ìtẹ́ rẹ̀ yóò dúró bí oòrùn níwájú mi.
37 (C)A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá,
    àti bi ẹlẹ́rìí òtítọ́ ni ọ̀run”. Sela.

Efesu 2:11-22

Ọ̀kan nínú Kristi

11 Nítorí náà ẹ rántí pé, nígbà àtijọ́ rí, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ Kèfèrí nípa ti ìbí, tí àwọn tí a ń pè ní “aláìkọlà” láti ọwọ́ àwọn tí ń pe ara wọn “akọlà” (Èyí ti a fi ọwọ́ ènìyàn ṣe sí ni ni ara)— 12 (A)Ẹ rántí pé ni àkókò náà ẹ̀yin wà láìní Kristi, ẹ jẹ́ àjèjì sí Israẹli, àti àjèjì sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà, láìní ìrètí, àti láìní Ọlọ́run ni ayé. 13 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kristi Jesu ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kristi.

14 Nítorí òun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórìíra èyí tí ń bẹ láàrín yín. 15 Ó sì ti fi òpin sí ọ̀tá náà nínú ara rẹ̀, àní sí òfin àti àṣẹ wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ nínú ìlànà, kí ó lè sọ àwọn méjèèjì di ẹni tuntun kan nínú ara rẹ̀, kí ó sì ṣe ìlàjà 16 àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú; nípa èyí tí yóò fi pa ìṣọ̀tá náà run. 17 (B)Ó sì ti wá, ó sì ti wàásù àlàáfíà fún ẹ̀yin tí o jìnnà réré, àti àlàáfíà fún àwọn tí o súnmọ́ tòsí. 18 Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan.

19 Ǹjẹ́ nítorí náà ẹ̀yin kì í ṣe àlejò àti àjèjì mọ́, ṣùgbọ́n àjùmọ̀jogún ọmọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn ará ilé Ọlọ́run; 20 a sì ń gbé yín ró lórí ìpìlẹ̀ àwọn aposteli, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jesu Kristi fúnrarẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé; 21 Nínú rẹ ni gbogbo ilé náà, tí a ń kọ wà papọ̀ ṣọ̀kan tí ó sì ń dàgbàsókè láti di tẹmpili mímọ́ kan nínú Olúwa: 22 Nínú rẹ̀ ni a ń gbé ẹ̀yin pẹ̀lú ró pẹ̀lú fún ibùjókòó Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí rẹ̀.

Marku 6:30-34

Jesu bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ènìyàn

30 (A)Àwọn aposteli kó ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n sí ròyìn ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe àti ohun gbogbo tí wọ́n ti kọ́ni. 31 Nígbà tí Jesu rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ tí wọ́n sì ń bọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ààyè fún wọn láti jẹun, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a kúrò láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí fún ìgbà díẹ̀, kí a sì sinmi.”

32 (B)Nítorí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tí ó parọ́rọ́. 33 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn ni o rí wọn nígbà tí wọ́n ń lọ. Àwọn wọ̀nyí sì tún wá láti ìlú ńlá gbogbo wọn sáré gba etí Òkun, wọ́n ṣáájú wọn gúnlẹ̀ ní èbúté. 34 (C)Bí Jesu ti ń sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà, ó bá ọ̀pọ̀ ènìyàn bí i tí àtẹ̀yìnwá, tí wọ́n ti ń dúró dè e. Ó káàánú fún wọn, nítorí wọ́n dàbí àgùntàn tí kò ní olùtọ́jú. Ó sì kọ́ wọn ni ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀.

Marku 6:53-56

53 (A)Lẹ́yìn tí wọ́n la Òkun náà kọjá, wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti. Wọ́n sì so ọkọ̀ sí èbúté. 54 Wọ́n jáde kúrò nínú ọkọ̀. Àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀ rí Jesu, wọ́n sì dá a mọ̀ ọ́n. 55 Wéré, wọ́n ròyìn dídé rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn sáré gbé gbogbo àwọn aláìsàn lórí àkéte wọn wá pàdé rẹ̀. 56 (B)Ní ibi gbogbo tí ó sì dé, yálà ní abúlé, ìlú ńlá tàbí àrọ́ko, ń ṣe ni wọ́n ń kó àwọn aláìsàn pàdé rẹ̀ ní àárín ọjà. Wọ́n sì ń bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí wọn fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n sì fi ọwọ́ kàn án ni a mú láradá.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.