Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 118:1-2

118 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;
    àánú rẹ̀ dúró láéláé.

Jẹ́ kí Israẹli wí pé:
    “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.

Saamu 118:14-24

14 Olúwa ni agbára àti orin mi;
    ó sì di ìgbàlà mi.

15 Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo:
    “Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!
16 Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbéga;
    ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!”
17 Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò yè,
    èmi yóò pòkìkí ohun tí Olúwa ṣe.
18 Olúwa bá mi wí gidigidi,
    ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.
19 Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi:
    èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.
20 Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwa
    ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.
21 Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn;
    ìwọ sì di ìgbàlà mi.

22 (A)Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
    ni ó di pàtàkì igun ilé;
23 Olúwa ti ṣe èyí,
    ó ṣe ìyanu ní ojú wa.
24 Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá:
    ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.

Gẹnẹsisi 1:1-19

Ìbẹ̀rẹ̀ dídá ayé

(A)Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé. Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi.

(B)Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn. Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “Ọ̀sán” àti òkùnkùn ní “Òru.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní.

(C)Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí òfúrufú kí ó wà ní àárín àwọn omi, láti pààlà sí àárín àwọn omi.” Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sì pe òfúrufú ní “Ọ̀run,” àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì.

Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 10 Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “ilẹ̀,” àti àpapọ̀ omi ní “òkun.” Ọlọ́run sì rí i wí pé ó dára.

11 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 12 Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èso ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èso, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára. 13 Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹta.

14 Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún ààmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún, 15 Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run, láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 16 Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńláńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru. Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú. 17 Ọlọ́run sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ si orí ilẹ̀, 18 láti ṣàkóso ọ̀sán àti òru àti láti pààlà sí àárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn: Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 19 Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ jẹ́ ọjọ́ kẹrin.

1 Kọrinti 15:35-49

Àjíǹde ara

35 Ṣùgbọ́n ẹnìkan yóò wí pé, “Báwo ni àwọn òkú yóò ṣe jíǹde? Irú ara wó ni wọn ó padà sí?” 36 (A)Ìwọ aláìmòye, ohun tí ìwọ fúnrúgbìn kì í yè bí kò ṣe pé ó ba kú: 37 Àti èyí tí ìwọ fúnrúgbìn, kì í ṣe ara tí ń bọ̀ ni ìwọ fúnrúgbìn, ṣùgbọ́n èso lásán ni, ìbá à ṣe alikama, tàbí irú mìíràn. 38 (B)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún ún ni ara bí o tí wù ú, àti fún olúkúlùkù irúgbìn ara tirẹ̀. 39 Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe ẹran-ara kan náà: ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ènìyàn, ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ní ti ẹja, ọ̀tọ̀ sì ní tí ẹyẹ. 40 Ará ti òkè ọ̀run ń bẹ, ara ti ayé pẹ̀lú sì ń bẹ: ṣùgbọ́n ògo ti òkè ọ̀run ọ̀tọ̀, àti ògo ti ayé ọ̀tọ̀. 41 Ọ̀tọ̀ ni ògo ti oòrùn, ọ̀tọ̀ ni ògo ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ sì ni ògo ti ìràwọ̀; ìràwọ̀ ṣá yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ni ògo.

42 (C)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ni àjíǹde òkú. A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́; a sí jì í dìde ni àìdíbàjẹ́: 43 A gbìn ín ni àìní ọlá, a sí jí i dìde ni ògo; a gbìn ín ni àìlera, a sì jí í dìde ní agbára. 44 A gbìn ín ni, ara ẹran a sì jí i dìde ni ara ti ẹ̀mí.

Bí ara ẹran bá ń bẹ, ara ẹ̀mí náà sì ń bẹ. 45 (D)Bẹ́ẹ̀ ní a si kọ ọ́ pé, “Adamu ọkùnrin ìṣáájú, alààyè ọkàn ni a dá a;” Adamu ìkẹyìn ẹ̀mí ìsọnidààyè. 46 Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáájú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ara ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí. 47 Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ẹni erùpẹ̀: ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni. 48 Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀: bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run. 49 Bí àwa ti rú àwòrán ẹni erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwa ó sì rú àwòrán ẹni ti ọ̀run.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.