Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jobu 14:1-14

Jobu tẹ̀síwájú nínú àròyé rẹ̀

14 “Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin,
    ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.
Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀;
    ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.
Ìwọ sì ń ṣíjú rẹ wò irú èyí ni?
    Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?
Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá?
    Kò sí ẹnìkan!
Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀,
    iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
    Ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.
Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè
    sinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.

“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá
    ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ,
    àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ.
Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,
    tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀;
Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi,
    yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.
10 Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù;
    Àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́.

Àgékúrú ọjọ́ ọmọ ènìyàn

11 “Bí omi ti í tán nínú ipa odò,
    àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ,
12 bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;
    títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,
    wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.

13 “Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,
    kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,
títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,
    ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!
14 Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?
    Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀
    fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.

Ẹkun Jeremiah 3:1-9

Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú
    pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ.
Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn
    nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀;
Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ padà sí mi
    síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.

Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó
    ó sì tún ṣẹ́ egungun mi.
Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká
    pẹ̀lú ìkorò àti làálàá.
Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn,
    bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.

Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ;
    ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀.
Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́,
    ó kọ àdúrà mi.
Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi;
    ó sì mú ọ̀nà mi wọ́.

Ẹkun Jeremiah 3:19-24

19 Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi,
    ìkorò àti ìbànújẹ́.
20 Mo ṣèrántí wọn,
    ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
21 Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn
    àti nítorí náà ní mo nírètí.

22 Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,
    nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.
23 Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;
    títóbi ni òdodo rẹ̀.
24 Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa;
    nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.

Saamu 31:1-4

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

31 Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí;
    gbà mí nínú òdodo rẹ.
Tẹ́ etí rẹ sí mi,
    gbà mí kíákíá;
jẹ́ àpáta ààbò mi,
    jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.
Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,
    nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.
Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,
    nítorí ìwọ ni ìsádi mi.

Saamu 31:15-16

15 Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
    gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi
    àti àwọn onínúnibíni.
16 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára;
    Gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

1 Peteru 4:1-8

Ìgbé ayé fún Ọlọ́run

Ǹjẹ́ bí Kristi ti jìyà fún wa nípa ti ará, irú kan náà ni kí ẹ̀yin fi hámọ́ra; nítorí ẹni tí ó bá ti jìyà nípa ti ara, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀; Kí ẹ̀yin má ṣe fi ìgbà ayé yín ìyókù wà nínú ara mọ́ sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ènìyàn bí kò ṣe sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Nítorí ìgbà tí ó ti kọjá ti tó fún ṣíṣe ìfẹ́ àwọn aláìkọlà, rínrìn nínú ìwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ọtí àmupara, ìréde òru, kíkó ẹ̀gbẹ́ ọ̀mùtí, àti ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ohun ìríra. Èyí tí ó yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ̀yin kò ba wọn súré sínú irú àṣejù ìwà wọ̀bìà wọ́n, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ yín ní búburú. Àwọn ẹni tí yóò jíyìn fún ẹni tí ó ti múra láti ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú. Nítorí èyí ní a sá ṣe wàásù ìhìnrere fún àwọn òkú, kí a lè ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nípa ti ara, ṣùgbọ́n kí wọ́n lè wà láààyè si Ọlọ́run nípa tí Ẹ̀mí.

Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo kù sí dẹ̀dẹ̀; nítorí náà kí ẹ̀yin wà ní àìrékọjá, kí ẹ sì máa ṣọ́ra nínú àdúrà. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrín ara yín: nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

Matiu 27:57-66

A tẹ́ Jesu sínú ibojì

57 (A)Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Arimatea, tí à ń pè ní Josẹfu, ọ̀kan nínú àwọn tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, 58 lọ sọ́dọ̀ Pilatu, ó sì tọrọ òkú Jesu. Pilatu sì pàṣẹ kí a gbé é fún un. 59 Josẹfu sì gbé òkú náà. Ó fi aṣọ funfun mímọ́ dì í. 60 Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnrarẹ̀. Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu-ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ. 61 Maria Magdalene àti Maria kejì wà níbẹ̀, wọn jókòó òdìkejì ibojì náà.

Àwọn olùṣọ́ ní ibojì

62 Lọ́jọ́ kejì tí ó tẹ̀lé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ sọ́dọ̀ Pilatu. 63 (B)Wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà àwa rántí pé ẹlẹ́tàn nnì wí nígbà tí ó wà láyé pé, ‘Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta èmi yóò tún jí dìde.’ 64 Nítorí náà, pàṣẹ kí a ti ibojì rẹ̀ gbọningbọnin títí ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ má ṣe wá jí gbé lọ, wọn a sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún gbogbo ènìyàn pé, ‘Òun ti jíǹde,’ Bí èyí bá ní láti ṣẹlẹ̀, yóò burú fún wa púpọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ.”

65 Pilatu sì pàṣẹ pé, “Ẹ lo àwọn olùṣọ́ yín kí wọn dáàbò bo ibojì náà bí ẹ bá ti fẹ́.” 66 (C)Nítorí náà wọ́n lọ. Wọ́n sì ṣé òkúta ibojì náà dáradára. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sí ibẹ̀ láti dáàbò bò ó.

Johanu 19:38-42

Ìsìnkú Jesu

38 (A)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ní Josẹfu ará Arimatea, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ní ìkọ̀kọ̀, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, o bẹ Pilatu kí òun lè gbé òkú Jesu kúrò: Pilatu sì fún un ní àṣẹ. Nígbà náà ni ó wá, ó sì gbé òkú Jesu lọ. 39 (B)Nikodemu pẹ̀lú sì wá, ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru lákọ̀ọ́kọ́, ó sì mú àdàpọ̀ òjìá àti aloe wá, ó tó ìwọ̀n ọgọ́ọ̀rún lítà. 40 (C)Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé òkú Jesu, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dì í pẹ̀lú tùràrí, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn Júù ti rí ní ìsìnkú wọn. 41 Àgbàlá kan sì wà níbi tí a gbé kàn án mọ́ àgbélébùú; ibojì tuntun kan sì wà nínú àgbàlá náà, nínú èyí tí a kò tí ì tẹ́ ẹnìkan sí rí. 42 Ǹjẹ́ níbẹ̀ ni wọ́n sì tẹ́ Jesu sí, nítorí ìpalẹ̀mọ́ àwọn Júù; àti nítorí ibojì náà wà nítòsí.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.