Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:9-16

Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?
Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ.
10 Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi
    má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.
11 Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi
    kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ
12 Ìyìn ni fún Olúwa;
    kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
13 Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò
    gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ.
14 Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ,
    bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá.
15 Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ
    èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ
16 Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ;
    èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ.

Isaiah 44:1-8

Israẹli tí a yàn

44 “Ṣùgbọ́n gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi
    àti Israẹli, ẹni tí mo ti yàn.
Ohun tí Olúwa wí nìyìí
    ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́n
láti inú ìyá rẹ wá,
    àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú:
Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu, ìránṣẹ́ mi,
    Jeṣuruni ẹni tí mo ti yàn.
Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ
    àti àwọn odò ní ilẹ̀ gbígbẹ;
Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ,
    àti ìbùkún mi sórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.
Wọn yóò dàgbàsókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù,
    àti gẹ́gẹ́ bí igi Poplari létí odò tí ń sàn.
Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’;
    òmíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jakọbu;
bẹ́ẹ̀ ni òmíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, ‘Ti Olúwa,’
    yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Israẹli.

Olúwa ni, kì í ṣe ère òrìṣà

(A)“Ohun tí Olúwa wí nìyìí
    ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní
Olúwa àwọn ọmọ-ogun:
    Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn,
    lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan.
Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀.
    Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi
Kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí
    àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀,
àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀
    bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.
Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù.
    Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ
àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́?
    Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan
ha ń bẹ lẹ́yìn mi?
    Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”

Ìṣe àwọn Aposteli 2:14-24

Peteru wàásù sí ọ̀pọ̀ ènìyàn

14 Nígbà náà ni Peteru dìde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá yòókù, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin Júù ènìyàn mi àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí èyí kí ó yé yin; kí ẹ sì fetísí ọ̀rọ̀ mi. 15 Àwọn wọ̀nyí kò mu ọtí yó, bí ẹ̀yin tí rò ó; wákàtí kẹta ọjọ́ sá à ni èyí. 16 Bẹ́ẹ̀ kọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ ti a ti sọ láti ẹnu wòlíì Joeli wá pé:

17 (A)“Ọlọ́run wí pé, ‘Ní ìkẹyìn ọjọ́,
    Èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí jáde sára ènìyàn gbogbo,
àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀
    àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò sì máa ríran,
    àwọn arúgbó yín yóò sì máa lá àlá;
18 Àti sára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mi ọkùnrin àti sára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mi obìnrin,
    ni Èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mi jáde ni ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì:
    wọn yóò sì máa sọtẹ́lẹ̀;
19 Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn lójú ọ̀run,
    àti àwọn ààmì nísàlẹ̀ ilẹ̀;
    ẹ̀jẹ̀ àti iná àti rírú èéfín;
20 A ó sọ oòrùn di òkùnkùn,
    àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀,
    kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ológo Olúwa tó dé.
21 Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe
    orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.’

22 “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jesu tí Nasareti, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti ààmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrín yín, bí ẹ̀yin tìkára yín ti mọ̀ pẹ̀lú. 23 Ẹni tí a ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa ìpinnu ìmọ̀ àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀yin pẹ̀lú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú kàn mọ́ àgbélébùú, tí a sì pa á. 24 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú: nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dìímú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.