Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 51:1-12

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nígbà ti wòlíì Natani tọ wá, lẹ́yìn tí Dafidi dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀ pẹ̀lú Batṣeba.

51 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí
    ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀
    kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.
Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò
    kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!

Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,
    nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.
(A)Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí
    ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀,
kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀,
    kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.
Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,
    nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.
Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;
    ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.

Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́;
    fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.
Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;
    jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.
Pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi
    kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédéé mi rẹ́.

10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,
    kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.
11 Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú rẹ,
    kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.
12 Mú ayọ̀ ìgbàlà rẹ tọ̀ mí wá,
    kí o sì fún mi ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.

Eksodu 30:1-10

Pẹpẹ tùràrí

30 (A)“Ìwọ yóò sì ṣe pẹpẹ igi kasia kan; máa jó tùràrí lórí rẹ̀. Kí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé, kí ó jẹ́ ìdajì mítà ní gígùn, ìdajì mítà ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga rẹ̀—kí ìwo rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. Ìwọ yóò sì bo òkè rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀ pẹ̀lú u kìkì wúrà, ìwọ yóò sì ṣe wúrà gbà á yíká. Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì fún pẹpẹ náà níṣàlẹ̀ ìgbátí méjèèjì ní òdìkejì ìhà rẹ̀—láti gbá àwọn òpó rẹ̀ mú, láti lè máa fi gbé e. Ìwọ yóò sì ṣe òpó igi kasia, ìwọ yóò sì bọ́ wọ́n pẹ̀lú wúrà. Ìwọ yóò gbé pẹpẹ náà sí iwájú aṣọ ìkélé, èyí tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí níwájú ìtẹ́ àánú èyí tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí níbi ti èmi yóò ti máa bá ọ pàdé.

“Aaroni yóò sì máa jó tùràrí dídùn lórí pẹpẹ náà ní àràárọ̀, nígbà tí ó tún àwọn fìtílà náà ṣe. Aaroni yóò sì tún jó tùràrí nígbà tí ó bá tan fìtílà ní àṣálẹ́, bẹ́ẹ̀ ní tùràrí yóò máa jó títí láé níwájú Olúwa fún àwọn ìran tó ń bọ̀. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mú àjèjì tùràrí wá sórí pẹpẹ yìí tàbí ẹbọ sísun kankan tàbí ọrẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ da ẹbọ ohun mímu sórí i rẹ̀. 10 Aaroni yóò sì máa ṣe ètùtù sórí àwọn ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Òun yóò sì máa ṣe ètùtù ọdọọdún yìí pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ètùtù fún ìran tó ń bọ̀. Mímọ́ jùlọ ni sí Olúwa.”

Heberu 4:14-5:4

Jesu ni olórí àlùfáà tòótọ́

14 Ǹjẹ́ bí a ti ní olórí àlùfáà ńlá kan, tí ó ti la àwọn ọ̀run kọjá lọ, Jesu ọmọ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ wa mú ṣinṣin. 15 Nítorí a kò ní olórí àlùfáà tí kò lè ṣàì ba ni kẹ́dùn nínú àìlera wa, ẹni tí a ti dánwò lọ́nà gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwa, ṣùgbọ́n òun kò dẹ́ṣẹ̀. 16 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a wá si ibi ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí oore-ọ̀fẹ́ láti máa ran ni lọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.

Nítorí olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan tí a yàn nínú àwọn ènìyàn, ní a fi jẹ nítorí iṣẹ́ ìsìn àwọn ènìyàn sí Ọlọ́run láti máa mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀. Ẹni tí ó lè ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ pẹ̀lú àwọn aláìmòye, tí ó sì lé bá àwọn tí ó ti yapa kẹ́dùn, nítorí a fi àìlera yí òun náà ká pẹ̀lú. Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe yẹ, bí ó ti ń rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní ń ṣe fún ara rẹ̀ náà. Kọ sí ẹni tí o gba ọlá yìí fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí a ti pe Aaroni.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.