Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 107:1-3

ÌWÉ KARÙN-ÚN

Saamu 107–150

107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
    nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn
    ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì
    láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
    láti àríwá àti Òkun wá.

Saamu 107:17-22

17 Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn
    wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn
18 Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ
    wọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú.
19 Nígbà náà wọ́n kígbe sí Olúwa nínú
    ìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn
20 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá
    ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú.
21 Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
22 Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́
    kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.

Gẹnẹsisi 9:8-17

Ọlọ́run sì wí fún Noa àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín àti pẹ̀lú àwọn ìran yín tí ń bọ̀ lẹ́yìn. 10 Àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, ìbá à ṣe ẹyẹ, ẹja, ẹran ọ̀sìn, ẹranko igbó, gbogbo ohun tí ó jáde kúrò nínú ọkọ̀ pẹ̀lú yín, àní gbogbo ẹ̀dá alààyè ní ayé. 11 Mo dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín, láéláé, Èmi kì yóò fi ìkún omi pa ayé run kúrò mọ láéláé, a kì yóò fi omi pa ayé run.”

12 Ọlọ́run sì wí pé, “Èyí ni ààmì májẹ̀mú tí mo ń dá yìí láàrín èmi àti ẹ̀yin àti ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú yín, májẹ̀mú àtìrandíran tó ń bọ̀: 13 Mo ti fi òṣùmàrè sí àwọsánmọ̀, yóò sì jẹ́ ààmì májẹ̀mú láàrín èmi àti ayé. 14 Nígbàkúgbà tí mo bá mú kí òjò ṣú, tí òṣùmàrè bá farahàn ní àwọsánmọ̀. 15 Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi, tí ó wà láàrín èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo ẹ̀dá alààyè, kì yóò sì tún sí ìkún omi mọ́ láti pa gbogbo ẹ̀dá run. 16 Nígbàkígbà tí òṣùmàrè bá yọ ní àwọsánmọ̀, èmi yóò rí i, èmi yóò sì rántí májẹ̀mú ayérayé tí ń bẹ láàrín Ọlọ́run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń bẹ ní ayé.”

17 Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èyí ni ààmì májẹ̀mú tí mo ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láàrín èmi àti gbogbo alààyè ní ayé.”

Efesu 1:3-6

Ìbùkún ti Ẹ̀mí Mímọ́ nínú Kristi

(A)Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kristi. Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́ Ẹni tí Ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jesu Kristi fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀ (B)fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí Ó ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀:

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.