Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 118:1-2

118 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;
    àánú rẹ̀ dúró láéláé.

Jẹ́ kí Israẹli wí pé:
    “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.

Saamu 118:19-29

19 Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi:
    èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.
20 Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwa
    ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.
21 Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn;
    ìwọ sì di ìgbàlà mi.

22 (A)Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
    ni ó di pàtàkì igun ilé;
23 Olúwa ti ṣe èyí,
    ó ṣe ìyanu ní ojú wa.
24 Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá:
    ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.

25 (B)Olúwa, gbà wá;
    Olúwa, fún wa ní àlàáfíà.

26 Ìbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.
    Àwa ti fi ìbùkún fún ọ láti ilé Olúwa wá.
27 Olúwa ni Ọlọ́run,
    ó ti mú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn sí wa lára
    pẹ̀lú ẹ̀ka igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́
ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀
    ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ.

28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ;
    ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga.

29 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
    nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

Jeremiah 33:1-9

Ìlérí ìmúpadàbọ̀sípò

33 Nígbà tí Jeremiah wà nínú àgbàlá túbú, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ọ́ wá lẹ́ẹ̀kejì: “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ẹni tí ó dá ayé, Olúwa tí ó mọ ayé tí ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, Olúwa ni orúkọ rẹ̀: ‘Pè mí, èmi ó sì dá ọ lóhùn, èmi ó sì sọ ohun alágbára ńlá àti ọ̀pọ̀ ohun tí kò ṣe é wádìí tí ìwọ kò mọ̀ fún ọ.’ Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Israẹli sọ nípa àwọn ilẹ̀ ìlú yìí àti ààfin àwọn ọba Juda tí ó ti wó lulẹ̀ nítorí àwọn ìdọ̀tí àti idà nínú ìjà pẹ̀lú Kaldea: ‘Wọn yóò kún fún ọ̀pọ̀ òkú ọmọkùnrin tí èmi yóò pa nínú ìbínú àti nínú ìrunú mi. Èmi ó pa ojú mi mọ́ kúrò ní ìlú yìí nítorí gbogbo búburú wọn.

“ ‘Wò ó, èmi ó mú ọ̀já àti oògùn ìmúláradá dì í; èmi ó wo àwọn ènìyàn mi sàn. Èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó jẹ ìgbádùn lọ́pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́. Èmi ó mú Juda àti Israẹli kúrò nínú ìgbèkùn, èmi ó sì tún wọn kọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀. Èmi ó wẹ̀ wọ́n nù kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ sí mi. Èmi ó sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àìṣedéédéé wọn sí mi jì wọ́n. Nígbà náà ni ìlú yìí ó fún mi ní òkìkí, ayọ̀, ìyìn àti ọlá níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé; tí wọ́n gbọ́ gbogbo rere tí èmi ṣe fún wọn. Wọn ó sì bẹ̀rù, wọn ó wárìrì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore àti àlàáfíà tí èmi pèsè fún wọn.’

Filipi 2:12-18

Títàn gẹ́gẹ́ bí àwọn ìràwọ̀

12 Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́rọ̀ nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárín yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, 13 (A)Nítorí pé Ọlọ́run ni ó n ṣiṣẹ́ nínú yín, láti fẹ́ àti láti ṣiṣẹ́ fún ète rere rẹ̀.

14 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti ìjiyàn. 15 (B)Kí ẹ̀yin lè jẹ́ aláìlẹ́gàn àti oníwà mímọ́, ọmọ Ọlọ́run, aláìlábàwọ́n, láàrín oníwà wíwọ́ àti alárékérekè orílẹ̀-èdè láàrín àwọn ẹni tí a ń rí yín bí ìmọ́lẹ̀ ní ayé. 16 Bí ẹ sì ṣe di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kristi pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán. 17 Ṣùgbọ́n, bí a tilẹ̀ ń dà mí bí ọtí-ìrúbọ sórí ẹbọ iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́ yín, inú mi dùn, mo sì ń bá gbogbo yín yọ̀ pẹ̀lú. 18 Bákan náà ni kí ẹ̀yin máa yọ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀ pẹ̀lú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.