Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 50:4-9

Olúwa Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán,
    láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró.
O jí mi láràárọ̀,
    o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.
Olúwa Olódùmarè ti ṣí mi ní etí,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí;
    Èmi kò sì padà sẹ́yìn.
Mo ṣí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí,
    àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irùngbọ̀n mi;
Èmi kò fi ojú mi pamọ́
    kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọṣùtì sí.
Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́;
    A kì yóò dójútì mí.
Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ
    èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.
Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí.
    Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí?
Jẹ́ kí a kojú ara wa!
    Ta ni olùfisùn mi?
    Jẹ́ kí ó kò mí lójú!
Olúwa Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́.
    Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi?
Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ;
    kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run.

Saamu 70

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

70 (A)Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,
    Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.

Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi
    kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;
kí àwọn tó ń wá ìparun mi
    yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.
Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè
    ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”
Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀
    kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,
kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,
    “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;
    wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;
    Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.

Heberu 12:1-3

Ìbáwí àwọn ọmọ Ọlọ́run

12 Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa, (A)Kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run. Máa ro ti ẹni tí ó faradà irú ìṣọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má ba á rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.

Johanu 13:21-32

21 (A)Nígbà tí Jesu ti wí nǹkan wọ̀nyí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú nínú rẹ̀, ó sì jẹ́rìí, ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, ọ̀kan nínú yín yóò dà mí.”

22 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń wò ara wọn lójú, wọ́n ń ṣiyèméjì ti ẹni tí ó wí. 23 (B)Ǹjẹ́ ẹnìkan rọ̀gbọ̀kú sí àyà Jesu, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí Jesu fẹ́ràn. 24 Nítorí náà ni Simoni Peteru ṣàpẹẹrẹ sí i, ó sì wí fún un pé, “Wí fún wa ti ẹni tí o ń sọ.”

25 Ẹni tí ó ń rọ̀gún ní àyà Jesu wí fún un pé, “Olúwa, ta ni í ṣe?”

26 (C)Nítorí náà Jesu dáhùn pé, “Òun náà ni, ẹni tí mo bá fi àkàrà fún nígbà tí mo bá fi run àwo.” Nígbà tí ó sì fi run ún tan, ó fi fún Judasi Iskariotu ọmọ Simoni. 27 Ní kété tí Judasi gba àkàrà náà ni Satani wọ inú rẹ̀ lọ.

Nítorí náà Jesu wí fún un pé, “Ohun tí ìwọ ń ṣe nì, yára ṣe é kánkán.” 28 Kò sì sí ẹnìkan níbi tábìlì tí ó mọ ìdí tí ó ṣe sọ èyí fún un. 29 (D)Nítorí àwọn mìíràn nínú wọn rò pé, nítorí Judasi ni ó ni àpò, ni Jesu fi wí fún un pé, ra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kò le ṣe aláìní fún àjọ náà; tàbí kí ó lè fi nǹkan fún àwọn tálákà. 30 (E)Nígbà tí ó sì ti gbà òkèlè náà tan, ó jáde lójúkan náà àkókò náà si jẹ òru.

Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru yóò sẹ́ òun

31 (F)Nítorí náà nígbà tí ó jáde lọ tan, Jesu wí pé, “Nísinsin yìí ni a yin Ọmọ ènìyàn lógo, a sì yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀. 32 Bí a bá yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀, Ọlọ́run yóò sì yìn ín lógo nínú òun tìkára rẹ̀, yóò sì yìn ín lógo nísinsin yìí.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.