Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
ÌWÉ KARÙN-ÚN
Saamu 107–150
107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
2 Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn
ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
3 Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì
láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
láti àríwá àti Òkun wá.
4 Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí,
wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí
wọn ó máa gbé
5 Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n,
ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.
6 Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè
sí Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn
7 Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú
tí wọn lè máa gbé
8 Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́
ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,
9 Nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run
ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa.
10 Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú,
a dè wọ́n ní ìrora àti ní irin,
11 Nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀
Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo,
12 Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀;
wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí
yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.
13 Ní ìgbà náà wọ́n ké pe
Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn
14 Ó mú wọn jáde kúrò nínú
òkùnkùn àti òjìji ikú,
ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.
15 Ẹ jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa! Nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.
16 Nítorí tí ó já ìlẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì
ó sì ké irin wọn ní agbede-méjì.
Omi láti inú àpáta
20 Ní oṣù kìn-ín-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Israẹli gúnlẹ̀ sí pápá Sini, wọ́n sì dúró ní Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú, wọ́n sì sin ín.
2 (A)Omi kò sí fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kó ara wọn jọ pọ̀ sí Mose àti Aaroni, 3 Wọ́n bá Mose jà wọ́n sì wí pé, “Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arákùnrin ti kú níwájú Olúwa! 4 Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn Olúwa wá sí aginjù yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa bá à kú síbí? 5 Kí ni ó dé tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Ejibiti wá sí ibi búburú yìí? Ibi tí kò ní oúnjẹ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́, èso àjàrà tàbí pomegiranate. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tí a ó mu níhìn-ín!”
6 Mose àti Aaroni kúrò ní ibi àpéjọ, wọ́n sì lọ dojúbolẹ̀ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahàn wọ́n. 7 Olúwa sọ fún Mose pé, 8 “Mú ọ̀pá, náà kí o sì pe ìjọ àwọn ènìyàn jọ, ìwọ àti Aaroni arákùnrin rẹ, kí ẹ sọ̀rọ̀ sí àpáta náà ní ojú wọn, yóò sì tú omi rẹ̀ jáde, ìwọ ó sì fún ìjọ àti ẹran wọn mu.”
9 Báyìí ni Mose mú ọ̀pá láti iwájú Olúwa wá, gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún un. 10 Òun àti Aaroni pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mose sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?” 11 Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu.
12 Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.”
13 Èyí ni omi ti Meriba, níbi tí àwọn ọmọ Israẹli ti bá Olúwa jà àti ibi tí O ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́ láàrín wọn.
6 (A)Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si. 7 (B)Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.” 8 (C)Bẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbèrè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbàá-mọ̀kànlá-lé-ẹgbẹ̀rún ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan. 9 (D)Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n. 10 (E)Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n.
11 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ fún wa, a sì kọ̀wé wọn fún ìkìlọ̀ fún wa, àwa ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé dé bá. 12 Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à ṣubú. 13 (F)Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.