Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Eksodu 19:2-8

Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gbéra kúrò ní Refidimu, wọ́n wọ ijù Sinai, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀, níbẹ̀ ni Israẹli sì dó sí ní iwájú òkè ńlá.

Mose sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ. Olúwa sì ké pè é láti orí òkè náà wá pé, “Èyí ni ìwọ yóò sọ fún ilé Jakọbu àti ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: ‘Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Ejibiti, àti bí mo ti gbé e yín ní apá ìyẹ́ idì. (A)Nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá ṣe ìgbọ́ràn sí mi dé ojú ààmì, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ni tèmi. Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ilẹ̀ ọba àwọn àlùfáà fún mi, orílẹ̀-èdè mímọ́.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.”

Mose sì tọ àwọn ènìyàn wá, ó sí pe àwọn àgbàgbà láàrín àwọn ènìyàn jọ. Ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ ti Olúwa pàṣẹ fún un láti sọ ní iwájú wọn. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa yóò ṣe ohun gbogbo ti Olúwa wí.” Mose sì mú ìdáhùn wọn padà tọ Olúwa lọ.

Saamu 100

Saamu. Fún ọpẹ́

100 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé
Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa:
    Ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,
    kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé
tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀
    àti àgùntàn pápá rẹ̀.

Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
    àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;
    ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore
    ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;
    àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.

Romu 5:1-8

Àlàáfíà àti ayọ̀

(A)Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. (B)Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run. (C)Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú: bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí: (D)Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.

Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kristi kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run. Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo: ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú. (E)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.

Matiu 9:35-10:8

Àwọn Alágbàṣe Kéré

35 (A)Jesu sì rìn yí gbogbo ìlú ńlá àti ìletò ká, ó ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn, ó sì ń wàásù ìhìnrere ìjọba ọrun, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn àti gbogbo àìsàn ní ara àwọn ènìyàn. 36 (B)Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àánú wọn ṣe é, nítorí àárẹ̀ mú wọn, wọn kò sì rí ìrànlọ́wọ́, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́. 37 (C)Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan 38 Nítorí náà, ẹ gbàdúrà sí Olúwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.”

Jesu rán àwọn méjìlá jáde

10 (D)Jesu sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀; ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn ààrùn àti àìsàn gbogbo.

Orúkọ àwọn aposteli méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí:

ẹni àkọ́kọ́ ni Simoni ẹni ti a ń pè ni Peteru àti arákùnrin rẹ̀ Anderu;

Jakọbu[a] ọmọ Sebede àti arákùnrin rẹ̀ Johanu.

Filipi àti Bartolomeu;

Tomasi àti Matiu agbowó òde;

Jakọbu ọmọ Alfeu àti Taddeu;

Simoni ọmọ ẹgbẹ́ Sealoti, Judasi Iskariotu, ẹni tí ó da Jesu.

(E)Àwọn méjèèjìlá wọ̀nyí ni Jesu ran, ó sì pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe lọ sì ọ̀nà àwọn kèfèrí, ẹ má ṣe wọ̀ ìlú àwọn ará Samaria Ẹ kúkú tọ̀ àwọn àgùntàn ilé Israẹli tí ó nù lọ. Bí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ máa wàásù yìí wí pé: ‘Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ máa ṣe ìwòsàn fún àwọn aláìsàn, ẹ si jí àwọn òkú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fi fún ni.

Matiu 10:9-23

“Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín; 10 Ẹ má ṣe mú àpò fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá; oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un. 11 Ìlúkílùú tàbí ìletòkíletò tí ẹ̀yin bá wọ̀, ẹ wá ẹni ti ó bá yẹ níbẹ̀ rí, níbẹ̀ ni kí ẹ sì gbé nínú ilé rẹ̀ títí tí ẹ̀yin yóò fi kúrò níbẹ̀. 12 Nígbà tí ẹ̀yin bá sì wọ ilé kan, ẹ kí i wọn. 13 Bí ilé náà bá sì yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó bà sórí rẹ̀; ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó padà sọ́dọ̀ yín. 14 Bí ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tàbí tí kò gba ọ̀rọ̀ yín, ẹ gbọn eruku ẹ̀ṣẹ̀ yín sílẹ̀ tí ẹ bá ń kúrò ní ilé tàbí ìlú náà. 15 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò sàn fún ìlú Sodomu àti Gomorra ní ọjọ́ ìdájọ́ ju àwọn ìlú náà lọ.

16 “Mò ń rán yín lọ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàrín ìkookò. Nítorí náà, kí ẹ ní ìṣọ́ra bí ejò, kí ẹ sì ṣe onírẹ̀lẹ̀ bí àdàbà. 17 (A)Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nítorí wọn yóò fi yín le àwọn ìgbìmọ̀ ìgbèríko lọ́wọ́ wọn yóò sì nà yín nínú Sinagọgu. 18 Nítorí orúkọ mi, a ó mú yín lọ síwájú àwọn baálẹ̀ àti àwọn ọba, bí ẹlẹ́rìí sí wọn àti àwọn aláìkọlà. 19 Nígbà tí wọ́n bá mú yín, ẹ má ṣe ṣàníyàn ohun tí ẹ ó sọ tàbí bí ẹ ó ṣe sọ ọ́. Ní ojú kan náà ni a ó fi ohun tí ẹ̀yin yóò sọ fún yín. 20 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ó sọ ọ́, bí kò ṣe Ẹ̀mí Baba yín tí ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.

21 (B)“Arákùnrin yóò sì fi arákùnrin fún pípa. Baba yóò fi àwọn ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóò ṣọ̀tẹ̀ sí òbí wọn, wọn yóò sì mú kí a pa wọ́n. 22 Gbogbo ènìyàn yóò sì kórìíra yín nítorí mi, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá dúró ṣinṣin dé òpin ni a ó gbàlà. 23 Nígbà tí wọn bá ṣe inúnibíni sì i yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sì ìlú kejì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin kò tì í le la gbogbo ìlú Israẹli já tán kí Ọmọ Ènìyàn tó dé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.