Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 50:7-15

“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ:
    èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.
Èmi kí yóò bá ọ wí
    nítorí àwọn ìrúbọ rẹ,
tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi
    ní ìgbà gbogbo.
Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un,
    tàbí kí o mú òbúkọ láti
inú agbo ẹran rẹ̀
10 Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi
    àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.
11 Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá
    àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi
12 Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,
    nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo
tí ó wa ní inú rẹ̀.
13 Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí
    mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?

14 “Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,
    kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo.
15 Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú,
    èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”

Ẹkun Jeremiah 3:40-58

40 Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò,
    kí a sì tọ Olúwa lọ.
41 Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè
    sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé:
42 “Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀
    ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.

43 “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa;
    ìwọ ń parun láìsí àánú.
44 Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ
    pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.
45 Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn
    láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.

46 “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn
    gbòòrò sí wa.
47 Àwa ti jìyà àti ìparun,
    nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”
48 Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò
    nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.

49 Ojú mi kò dá fún omijé,
    láì sinmi,
50 títí ìgbà tí Olúwa yóò ṣíjú wolẹ̀
    láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.
51 Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi
    nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.

52 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí
    dẹ mí bí ẹyẹ.
53 Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò
    wọ́n sì ju òkúta lù mí.
54 Orí mi kún fún omi,
    mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.

55 Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa,
    láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.
56 Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi: “Má ṣe di etí rẹ
    sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”
57 O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́,
    o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”

58 Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò,
    o ra ẹ̀mí mi padà.

Ìṣe àwọn Aposteli 28:1-10

Erékùṣù ni Mẹlita

28 Nígbà tí gbogbo wa sì yọ tan ni àwa tó mọ̀ pé, Mẹlita ni a ń pè erékùṣù náà. Kì í ṣe oore díẹ̀ ni àwọn aláìgbédè náà ṣe fún wa: nítorí ti wọ́n dáná, wọ́n sì gbà gbogbo wa sí ọ̀dọ̀ nítorí òjò ń rọ nígbà náà, àti nítorí òtútù. Nígbà tí Paulu sì ṣa ìdí ìṣẹ́pẹ́ igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́. Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú Òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láààyè.” Òun sì gbọn ẹranko náà sínú iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é. Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣubú lulẹ̀ láti kú lójijì: nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí.

Ní agbègbè ibẹ̀ ni ilé ọkùnrin ọlọ́lá erékùṣù náà wà, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Pọbiliu; ẹni tí ó ti ipa inú rere gbà wá sí ọ̀dọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. Ó sì ṣe, baba Pọbiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá. Nígbà tí èyí sì ṣetán, àwọn ìyókù tí ó ni ààrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá. 10 Wọ́n sì bu ọlá púpọ̀ fún wa; nígbà tí a ń lọ, wọ́n sì fún wa ní ohun púpọ̀ tí a nílò ní ọ̀nà àjò wa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.