Revised Common Lectionary (Complementary)
Maskili ti Etani ará Esra.
89 Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé;
pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
2 Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé,
pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnrarẹ̀.
3 (A)Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi
mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.
4 ‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé
èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì,
Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.
16 Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,
wọn ń yin òdodo rẹ.
17 Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;
nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo.
18 Nítorí ti Olúwa ni asà wa,
ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
Hananiah wòlíì èké
28 Ní oṣù karùn-ún ní ọdún kan náà, ọdún kẹrin ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba Sedekiah ọba Juda, wòlíì Hananiah ọmọ Assuri, tí ó wá láti Gibeoni, sọ fún mi ní ilé Olúwa tí ó wà ní iwájú àwọn àlùfáà àti gbogbo ènìyàn: 2 “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Èmi yóò mú àjàgà ọba Babeli rọrùn. 3 Láàrín ọdún méjì, Èmi yóò mú gbogbo ohun èlò tí ọba Nebukadnessari; ọba Babeli kó kúrò ní ilé Olúwa tí ó sì kó lọ sí Babeli padà wá. 4 Èmi á tún mú ààyè Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda padà, àti gbogbo àwọn tí ń ṣe àtìpó láti Juda ní Babeli,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘àjàgà yín láti ọwọ́ ọba Babeli yóò rọrùn.’ ”
Ẹ̀ṣẹ̀, ìgbàgbọ́, àti iṣẹ́
17 (A)Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò le ṣe kí ohun ìkọ̀sẹ̀ máa wa: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ dé. 2 Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì gbé e jù sínú Òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀. 3 (B)Ẹ máa kíyèsára yín.
“Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dáríjì ín. 4 Bí ó bá sì ṣẹ̀ ọ́ ní igba méje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìgbà méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dáríjì ín.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.