Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Sekariah 9:9-12

Ọba sioni ń bọ̀

(A)Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni,
    hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu:
Wo ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ:
    òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà;
    ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
    àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
10 Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Efraimu,
    àti ẹṣin ogun kúrò ni Jerusalẹmu,
    a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun.
Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn kèfèrí.
    Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti Òkun dé Òkun,
    àti láti odò títí de òpin ayé.
11 Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ,
    Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun.
12 Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ti o ni ìrètí:
    àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́po méjì.

Saamu 145:8-14

Olóore-ọ̀fẹ́ ni Olúwa àti aláàánú
    ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.

Olúwa dára sí ẹni gbogbo;
    ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá.
10 Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni
    yóò máa yìn ọ́ Olúwa;
    àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ.
11 Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ
    wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ,
12 Kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀
    àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo.
13 Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni,
    àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.
14 Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró
    ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.

Romu 7:15-25

15 (A)Èmi pàápàá, kò mọ̀ ohun tí èmi ń ṣe. Nítorí pé, ohun tí mo fẹ́ ṣe gan an n kò ṣe é, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìíra ni mo ń ṣe. 16 Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe ohun tí èmi kò fẹ́, mo gbà pé òfin dára. 17 Ṣùgbọ́n bí ọ̀rọ̀ ṣe rí yìí kì í ṣe èmi ni ó ṣe é bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. 18 Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi fẹ́ ṣe èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe. 19 Nítorí ohun tí èmi ṣe kì í ṣe ohun rere tí èmi fẹ́ láti ṣe; rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, èyí nì ni èmi ń ṣe. 20 Nísinsin yìí, bí mo bá ń ṣe nǹkan tí n kò fẹ́ láti ṣe, kì í ṣe èmí fúnra mi ni ó ṣe é, bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ nínú ni ó ṣe é.

21 Nítorí náà, èmi kíyèsi pé òfin ní ń ṣiṣẹ́ nínú mi: nígbà tí èmi bá fẹ́ ṣe rere, búburú wà níbẹ̀ pẹ̀lú mi. 22 (B)Nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run; 23 (C)mo rí òfin mìíràn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi, èyí tí ń gbógun ti òfin tó tinú ọkàn mi wá, èyí tí ó sọ mi di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi. 24 (D)Èmi ẹni òsì! Ta ni yóò ha gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ara kíkú yìí? 25 Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa!

Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi fúnra mi jẹ́ ẹrú sí òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mo jẹ́ ẹrú fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.

Matiu 11:16-19

16 (A)“Kí ni èmi ìbá fi ìran yìí wé? Ó dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ń jókòó ní ọjà tí wọ́n sì ń ké pe àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn:

17 “ ‘Àwa ń fun fèrè fún yín,
    ẹ̀yin kò jó;
àwa kọrin ọ̀fọ̀
    ẹ̀yin kò káàánú.’

18 Nítorí Johanu wá kò bá a yín jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù.’ 19 Ọmọ ènìyàn wá bá a yín jẹun, ó sì bá yin mu, wọ́n wí pé, ọ̀jẹun àti ọ̀mùtí; ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n a dá ọgbọ́n láre nípa ìṣe rẹ̀.”

Matiu 11:25-30

Ìsinmi fún aláàárẹ̀

25 (A)(B) Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Mo yìn ọ Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, nítorí ìwọ ti fi òtítọ́ yìí pamọ́ fún àwọn tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti amòye, Ìwọ sì ti fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́. 26 Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí ó wù ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

27 (C)“Ohun gbogbo ni Baba mi ti fi sí ìkáwọ́ mi. Kò sí ẹni tí ó mọ ọmọ bí kò ṣe Baba, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ Baba, bí kò ṣe ọmọ, àti àwọn tí ọmọ yan láti fi ara hàn fún.

28 “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wíwúwo lé lórí, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi. 29 Ẹ gbé àjàgà mi wọ̀. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi nítorí onínútútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi, ẹ̀yin yóò sì ri ìsinmi fún ọkàn yín. 30 Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.