Revised Common Lectionary (Complementary)
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;
fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,
kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.
12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé
13 Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi;
ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.
14 Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run;
àti ìjọ àwọn alágbára ń wá
ọkàn mi kiri,
wọn kò sì fi ọ́ pè.
15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,
Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
16 Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi;
fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára
kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.
17 Fi ààmì hàn mí fún rere,
kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri,
kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa
ni ó ti tù mí nínú.
9 Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán,
àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́
kò jámọ́ nǹkan kan.
Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú;
wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan sí ìtìjú ara wọn.
10 Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère,
tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?
11 Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójútì;
àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n.
Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì
fi ìdúró wọn hàn;
gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú Ìpayà àti àbùkù.
12 Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò,
ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú;
ó fi òòlù ya ère kan,
ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀,
Ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un;
kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.
13 Gbẹ́nàgbẹ́nà fi ìwọ̀n wọ́n ọ́n
ó sì fi lẹ́ẹ̀dì ṣe ààmì sí ara rẹ̀,
Ó tún fi ìfà fá a jáde
ó tún fi òṣùwọ̀n ṣe ààmì sí i.
Ó gbẹ́ ẹ ní ìrí ènìyàn
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nínú ògo rẹ̀,
kí ó lè máa gbé nínú ilé òrìṣà.
14 Ó gé igi kedari lulẹ̀,
tàbí bóyá ó mú sípírẹ́ṣì tàbí igi óákù.
Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrín àwọn igi inú igbó,
ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà.
15 Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn;
díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kí
ara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́,
ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà.
Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín;
ó yá ère, ó sì ń foríbalẹ̀ fún un.
16 Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná;
lórí i rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀,
ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó.
Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé,
“Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.”
17 Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀;
ó foríbalẹ̀ fún un, ó sì sìn ín.
Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé,
“Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.”
Ìdánilójú ìlérí Ọlọ́run
13 (A)Nítorí nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Abrahamu, bí kò ti rí ẹni tí ó pọ̀jù òun láti fi búra, ó fi ara rẹ̀ búra, wí pé, 14 “Nítòótọ́ ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i.” 15 Bẹ́ẹ̀ náà sì ni, lẹ́yìn ìgbà tí Abrahamu fi sùúrù dúró, ó ri ìlérí náà gbà.
16 Nítorí ènìyàn a máa fi ẹni tí ó pọ̀jù wọ́n lọ búra: ìbúra náà a sì fi òpin sí gbogbo ìjiyàn wọn fún ìfẹ̀sẹ̀ múlẹ̀ ọ̀rọ̀. 17 Nínú èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí ń fẹ́ gidigidi láti fi àìlèyípadà ète rẹ̀ hàn fún àwọn ajogún ìlérí náà, ó fi ìbúra sáàrín wọn. 18 Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú ṣinṣin: 19 (B)Èyí tí àwa níbi ìdákọ̀ró ọkàn fún ọkàn wa, ìrètí tí ó dájú tí ó sì dúró ṣinṣin, tí ó sì wọ inú ilé lọ lẹ́yìn aṣọ ìkélé; 20 (C)níbi tí Jesu, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ alábojútó àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.