Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 40:1-8

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

40 Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa;
    ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.
Ó fà mí yọ gòkè
    láti inú ihò ìparun,
láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀,
    ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta,
ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.
Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,
    àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa.
Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù,
    wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì
    tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn
tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga,
    tàbí àwọn tí ó yapa
lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.
Olúwa Ọlọ́run mi, Ọ̀pọ̀lọpọ̀
    ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe.
Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa;
    ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ
tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn,
    wọ́n ju ohun tí
ènìyàn le è kà lọ.

(A)Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,
    ìwọ ti ṣí mi ní etí.
Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀
    ni ìwọ kò béèrè.
Nígbà náà ni mo wí pé,
    “Èmi nìyí;
nínú ìwé kíká ni
    a kọ ọ nípa tèmi wí pé.
Mo ní inú dídùn
    láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ,
ìwọ Ọlọ́run mi;
    Òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

Lefitiku 15:25-31

25 “ ‘Bí obìnrin bá ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọjọ́ púpọ̀ yálà sí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tàbí tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá kọjá ìgbà tí ó yẹ. Gbogbo ìgbà tí ó bá fi ń ní ìsun ẹ̀jẹ̀ náà ni yóò fi wà ní àìmọ́ gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. 26 Ibùsùn tí ó wù kí ó sùn sí ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀jẹ̀ náà ń wá yóò jẹ́ àìmọ́ bí ibùsùn rẹ̀ ṣe jẹ́ ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó bá jókòó lé yóò wà ní àìmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. 27 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn wọ́n yóò wà ní àìmọ́. Ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ kí ó sì wà ní àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

28 “ ‘Nígbà tí ó bá di mímọ́ kúrò nínú ìsun rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ méje lẹ́yìn náà, a ó kà á sí mímọ́. 29 Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé wá síwájú àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 30 Kí àlùfáà fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún un, níwájú Olúwa fún àìmọ́ ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

31 “ ‘Ẹ ya ará Israẹli sọ́tọ̀ kúrò nínú ohun tí ó ń sọ wọ́n di aláìmọ́, kí wọ́n má bá a kú nínú àìmọ́ wọn nípa bíba ibùgbé mímọ́ mi jẹ́: Èyí tí ó wà láàrín wọn.’ ”

Lefitiku 22:1-9

22 Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n fi ọ̀wọ̀ fún ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli yà sọ́tọ̀ fún mi, kí wọ́n má ba à ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Èmi ni Olúwa.

“Sọ fún wọn pé: ‘Fún àwọn ìran tí ń bọ̀. Bí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ yín tí kò mọ́ bá wá sí ibi ọrẹ mímọ́ tí àwọn ara Israẹli ti yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, kí ẹ yọ ẹni náà kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà ní iwájú mi. Èmi ni Olúwa.

“ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Aaroni bá ní ààrùn ara tí ń ran ni, tàbí ìtújáde nínú ara. Ó lè má jẹ ọrẹ mímọ́ náà títí di ìgbà tí a ó fi wẹ̀ ẹ́ mọ́. Òun tún lè di aláìmọ́ bí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí òkú nǹkan bá sọ di àìmọ́ tàbí bí ó bá farakan ẹnikẹ́ni tí ó ní ìtújáde. Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan èyíkéyìí nínú ohun tí ń rákò, tí ó sọ ọ́ di aláìmọ́, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó sọ ọ́ di àìmọ́, ohunkóhun yówù kí àìmọ́ náà jẹ́. Ẹni náà tí ó fọwọ́ kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú ọrẹ mímọ́ àyàfi bí ó bá wẹ ara rẹ̀. Bí oòrùn bá wọ̀, ẹni náà di mímọ́, lẹ́yìn náà ni ó tó le jẹ ọrẹ mímọ́, torí pé wọ́n jẹ́ oúnjẹ rẹ̀. Kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti kú sílẹ̀, tàbí tí ẹranko fàya, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di aláìmọ́. Èmi ni Olúwa.

“ ‘Kí àwọn àlùfáà pa ìlànà mi mọ́, kí wọn má ba à jẹ̀bi, kí wọn sì kú nítorí pé wọ́n ṣe ọrẹ wọ̀nyí pẹ̀lú fífojútẹ́ńbẹ́lú wọn. Èmi ni Olúwa tí ó sọ wọ́n di mímọ́.

2 Kọrinti 6:14-7:2

Má ṣe dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́

14 Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́: nítorí ìdàpọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdàpọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn? 15 Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kristi ní pẹ̀lú Beliali? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? 16 (A)Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹmpili Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹmpili Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé:

“Èmi á gbé inú wọn,
    èmi o sì máa rìn láàrín wọn,
èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn,
    wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”

17 (B)Nítorí náà,

“Ẹ jáde kúrò láàrín wọn,
    kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀,
    ni Olúwa wí.
Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́;
    Èmi ó sì gbà yín.”

18 Àti,

(C)“Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín,
    Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi!
    ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́, bí a ti ní àwọn ìlérí wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí, kí a sọ ìwà mímọ́ dí pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

Ayọ̀ Paulu

(D)Ẹ gbà wá tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹ́ni, a kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́, a kò rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.