Add parallel Print Page Options

(A)Nítorí náà nígbà tí Kristi wá sí ayé, ó wí pé,

“Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ,
    ṣùgbọ́n ara ni ìwọ ti pèsè fún mi;
Ẹbọ sísun àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni
    ìwọ kò ní inú dídùn sí.
Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Kíyèsi i (nínú ìwé kíká ni a gbé kọ ọ́ nípa ti èmi)
    mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ ”

Nígbà tí o wí ni ìṣáájú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin). Nígbà náà ni ó wí pé, “Kíyèsi i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run.” Ó mú ti ìṣáájú kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀.

Read full chapter