Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jeremiah 20:7-13

Ìráhùn Jeremiah

Olúwa, o tàn mí jẹ́,
    o sì ṣẹ́gun.
Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́,
    gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà.
Nígbàkúgbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta
    èmi á sọ nípa ipá àti ìparun.
Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Olúwa ti mú àbùkù
    àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà.
Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ
    tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi
    nínú egungun mi
Agara dá mi ní inú mi
    nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.
10 Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,
    ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo
Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn!
    Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró
kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé,
    Bóyá yóò jẹ́ di títàn,
nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀,
    àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.”

11 Ṣùgbọ́n Olúwa ń bẹ pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí akọni ẹlẹ́rù.
    Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀,
wọn kì yóò sì borí.
    Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀.
    Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé.
12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìwọ tí ó ń dán olódodo wò
    tí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀mí fínní fínní,
jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn,
    nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé.

13 Kọrin sí Olúwa!
    Fi ìyìn fún Olúwa!
Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìní
    lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.

Saamu 69:7-10

Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn,
    ìtìjú sì bo ojú mi.
Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi;
    àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;
(A)Nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run,
    àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.
10 Nígbà tí mo sọkún
    tí mo sì ń fi àwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà
èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;

Saamu 69:11-15

11 Nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà,
    àwọn ènìyàn ń pa òwe mọ́ mi.
12 Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi,
    mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.

13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni
    ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí Olúwa,
ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà
    Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ,
dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú.
14 Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀,
    Má ṣe jẹ́ kí n rì;
gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi,
    kúrò nínú ibú omi.
15 Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀
    bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì
kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi.

Saamu 69:16-18

16 Dá mí lóhùn, Olúwa, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ;
    nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi.
17 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ:
    yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.
18 Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là;
    rà mí padà nítorí àwọn ọ̀tá mi.

Romu 6:1-11

Ikú sí ẹsẹ̀, iyè nínú Kristi

(A)Ǹjẹ́ àwa ó ha ti wí? Ṣé kí àwa ó jókòó nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí oore-ọ̀fẹ́ ba à lè máa pọ̀ sí i? (B)Kí a má ri! Àwa ẹni tí ó ti kú sí ẹ̀ṣẹ̀, àwa ó ha ṣe wà láààyè nínú rẹ̀ mọ́? (C)Tàbí ẹyin kò mọ pé gbogbo wa ti a ti bamitiisi wa sínú Jesu Kristi ni a ti bamitiisi sínú ikú rẹ. (D)Nítorí náà, a sin wa pẹ̀lú Kristi nípa ìtẹ̀bọmi si ikú, kí ó bá le jẹ́ pe bí a ti jí Kristi dìde pẹ̀lú ògo Baba, àwa pẹ̀lú gbé ìgbé ayé tuntun.

(E)Nítorí pé ẹ̀yin ti di ọ̀kan ṣoṣo pẹ̀lú rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde. (F)Gbogbo èrò búburú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. (G)Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́.

(H)Nísinsin yìí, bí àwa bá kú pẹ̀lú Kristi àwa gbàgbọ́ pé àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀. (I)Nítorí àwa mọ̀ pé Kristi ti jí dìde kúrò nínú òkú. Òun kò sì ní kú mọ́. Ikú kò sì lè ní agbára lórí rẹ̀ mọ́. 10 Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, láti ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó wà láààyè títí ayé àìnípẹ̀kun ní ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.

11 (J)Nítorí náà, ẹ ka ara yín bí òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n bí alààyè sí Ọlọ́run nínú Kristi Jesu.

Matiu 10:24-39

24 (A)“Akẹ́kọ̀ọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ọ̀dọ̀ kì í ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. 25 Ó tọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láti dàbí olùkọ́ rẹ̀ àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ láti rí bí ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá pe baálé ilé ní Beelsebulu, mélòó mélòó ni ti àwọn ènìyàn ilé rẹ̀!

26 (B)(C) “Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí kò sí ohun tó ń bọ̀ tí kò ní í fi ara hàn, tàbí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní mọ̀ ni gbangba. 27 Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀. Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé. 28 Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa Ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run àpáàdì. 29 Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin. 30 Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé. 31 Nítorí náà, ẹ má ṣe fòyà; ẹ̀yin ní iye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.

32 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú ènìyàn, òun náà ni èmi yóò jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run. 33 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mí níwájú àwọn ènìyàn, òun náà ni èmi náà yóò sọ wí pé n kò mọ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run.

34 (D)“Ẹ má ṣe rò pé mo mú àlàáfíà wá sí ayé, Èmi kò mú àlàáfíà wá bí kò ṣe idà. 35 Nítorí èmi wá láti ya

“ ‘ọmọkùnrin ní ipa sí baba rẹ̀,
    ọmọbìnrin ní ipa sí ìyá rẹ̀,
àti aya ọmọ sí ìyakọ rẹ̀…
36     Ará ilé ènìyàn ni yóò sì máa ṣe ọ̀tá rẹ̀.’

37 (E)“Ẹni tí ó bá fẹ́ baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi, ẹni tí ó ba fẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi; 38 Ẹni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀lé mi kò yẹ ní tèmi. 39 Ẹni tí ó bá wa ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.