Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 100

Saamu. Fún ọpẹ́

100 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé
Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa:
    Ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,
    kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé
tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀
    àti àgùntàn pápá rẹ̀.

Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
    àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;
    ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore
    ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;
    àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.

Eksodu 4:18-23

Mose padà sí Ejibiti

18 Mose padà sí ọ̀dọ̀ Jetro baba ìyàwó rẹ̀, ó sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n padà tọ àwọn ènìyàn mi lọ ni ilẹ̀ Ejibiti láti wò bóyá wọ́n ṣì wà láààyè síbẹ̀.”

Jetro sì dáhùn, ó wí pé, “Máa lọ ni àlàáfíà.”

19 (A)Nísinsin yìí, Olúwa ti sọ fún Mose ni ilẹ̀ Midiani pé, “Máa padà lọ sí Ejibiti, nítorí àwọn ti ó fẹ́ pa ọ ti kú.” 20 Mose mú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó kó wọn lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ padà sí Ejibiti. Ó sì mú ọ̀pá Ọlọ́run sí ọwọ́ rẹ̀.

21 Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Ní ìgbà tí ìwọ bá padà sí Ejibiti rí i pé ìwọ ṣe iṣẹ́ ìyanu ni iwájú Farao. Èmi ti fún ọ lágbára láti ṣe é. Èmi yóò sì sé àyà rẹ̀ le, òun kì yóò jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà kí ó lọ. 22 Lẹ́yìn náà, kí o sọ fún Farao pé, ‘Èyí ni Olúwa sọ: Israẹli ní àkọ́bí ọmọ mi ọkùnrin, 23 (B)mo sọ fún ọ, “Jẹ́ kí ọmọ mi lọ, ki òun kí ó lè máa sìn mí.” Ṣùgbọ́n ìwọ kọ̀ láti jẹ́ kí ó lọ; nítorí náà, èmi yóò pa àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin.’ ”

Heberu 3:1-6

Jesu pọ̀ ju Mose lọ

Nítorí náà ẹ̀yin ará mímọ́, alábápín ìpè ọ̀run, ẹ gba ti aposteli àti olórí àlùfáà ìjẹ́wọ́ wa rò, àní Jesu; (A)Ẹni tí o ṣe olóòtítọ́ si ẹni tí ó yàn án, bí Mose pẹ̀lú tí ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo nínú ilé Ọlọ́run. Nítorí a ka ọkùnrin yìí ni yíyẹ sí ògo ju Mose lọ níwọ̀n bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti lọ́lá ju ilé lọ. Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run. (B)Mose nítòótọ́ sì ṣe olóòtítọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ́n ní ìgbà ìkẹyìn. Ṣùgbọ́n Kristi jẹ́ olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwa jẹ́, bí àwa bá gbẹ́kẹ̀lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.