Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Eksodu 27

Pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun

27 (A)“Ìwọ yóò sì kọ pẹpẹ igi kasia kan, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gígùn; Kí ìhà rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jẹ́ ìwọ̀n kan, ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní fífẹ̀. Ìwọ yóò ṣì ṣe ìwo orí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, kí àwọn ìwo náà àti pẹpẹ náà lè ṣe ọ̀kan, ìwọ yóò sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ. Ìwọ yóò sì ṣe abọ́ ìtẹ́dìí rẹ láti máa gba eérú rẹ̀, àti ọkọ̀ rẹ̀, àwokòtò rẹ̀, àti fọ́ọ̀kì ẹran rẹ̀, àti àwo iná rẹ̀, gbogbo ohun èlò rẹ̀ ni ìwọ yóò fi idẹ ṣe. Ìwọ yóò sí ṣe ni wẹ́wẹ́, iṣẹ́ àwọ̀n idẹ, kí o sì ṣe òrùka idẹ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin iṣẹ́ àwọ̀n náà. Gbé e sí abẹ́ igun pẹpẹ náà, kí ó lè dé ìdajì pẹpẹ náà. Ìwọ yóò sí ṣe òpó igi kasia fún pẹpẹ náà, kí o sì bò ó pẹ̀lú idẹ. A ó sì bọ àwọn òpó náà ní òrùka, wọn yóò sì wà ní ìhà méjèèjì pẹpẹ nígbà tí a bá rù ú. Ìwọ yóò sì ṣe pákó náà ni oníhò nínú. Ìwọ yóò sí ṣe wọ́n bí èyí tí a fihàn ọ́ ní orí òkè.

Àgbàlá

(B)“Ìwọ yóò sì ṣe àgbàlá fún àgọ́ náà. Ní ìhà gúúsù gbọdọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta) ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́, 10 pẹ̀lú ogún (20) òpó àti ogún (20) ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà, kí ó sì di àwọn òpó mú. 11 Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun (20) òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú.

12 “Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá. 13 Ní ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, 14 Aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga ní yóò wà ní ìhà ẹnu-ọ̀nà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta, 15 Àti aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga yóò wá ní ìhà kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta.

16 “Àti fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà, pèsè aṣọ títa, mítà mẹ́sàn-án ní gíga, ti aláró, elése àlùkò, ti òdòdó, àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe, pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin. 17 Gbogbo òpó ti ó wà ní àyíká àgbàlá náà ni a ó fi fàdákà ṣo pọ̀ àti ìkọ́, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ. 18 Àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ni gíga àti mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, pẹ̀lú aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn mítà méjì ní gíga, àti pẹ̀lú ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ. 19 Gbogbo irú iṣẹ́ tí ó wà kí ó ṣe, papọ̀ pẹ̀lú gbogbo èèkàn àgọ́ náà àti fún tí àgbàlá náà, kí ó jẹ́ idẹ.

Òróró fún ọ̀pá fìtílà

20 (C)“Ìwọ yóò sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn kí ó mú òróró olifi dáradára tí a gún fún ọ wá, fún ìmọ́lẹ̀, kí fìtílà lè máa tàn síbẹ̀. 21 Ní àgọ́ àjọ, lẹ́yìn òde aṣọ ìkélé tí ó wá níwájú ẹ̀rí náà, Aaroni àti òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, ni yóò tọ́jú rẹ̀ láti alẹ́, títí di òwúrọ̀ níwájú Olúwa: yóò sì di ìlànà láéláé ni ìrandíran wọn lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli.

Johanu 6

Jesu bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún

(A)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu kọjá sí apá kejì Òkun Galili, tí í ṣe Òkun Tiberia. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ ààmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn. Jesu sì gun orí òkè lọ, níbẹ̀ ni ó sì gbé jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Àjọ ìrékọjá ọdún àwọn Júù sì súnmọ́ etílé.

(B)Ǹjẹ́ bí Jesu ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Filipi pé, “Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ?” Ó sì sọ èyí láti dán an wò; nítorí tí òun fúnrarẹ̀ mọ ohun tí òun ó ṣe.

Filipi dá a lóhùn pé, “Àkàrà igba owó idẹ kò lè tó fún wọn, bí olúkúlùkù wọn kò tilẹ̀ ní í rí ju díẹ̀ bù jẹ.”

(C)Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Anderu, arákùnrin Simoni Peteru wí fún un pé, (D)“Ọmọdékùnrin kan ń bẹ níhìn-ín yìí, tí ó ní ìṣù àkàrà barle márùn-ún àti ẹja wẹ́wẹ́ méjì: ṣùgbọ́n kín ni ìwọ̀nyí jẹ́ láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí?”

10 Jesu sì wí pé, “Ẹ mú kí àwọn ènìyàn náà jókòó!” Koríko púpọ̀ sì wá níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin náà jókòó; ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní iye. 11 Jesu sì mú ìṣù àkàrà náà. Nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì pín wọn fún àwọn tí ó jókòó; bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni ẹja ní ìwọ̀n bí wọ́n ti ń fẹ́.

12 Nígbà tí wọ́n sì yó, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó àjẹkù tí ó kù jọ, kí ohunkóhun má ṣe ṣòfò.” 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó wọn jọ wọ́n sì fi àjẹkù ìṣù àkàrà barle márùn-ún náà kún agbọ̀n méjìlá, èyí tí àwọn tí ó jẹun jẹ kù.

14 (E)Nítorí náà nígbà tí àwọn ọkùnrin náà rí iṣẹ́ ààmì tí Jesu ṣe, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà tí ń bọ̀ wá sí ayé.” 15 (F)Nígbà tí Jesu sì wòye pé wọ́n ń fẹ́ wá fi agbára mú òun láti lọ fi jẹ ọba, ó tún padà lọ sórí òkè, òun nìkan.

Jesu rin lórí omi

16 (G)Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun. 17 Wọ́n sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì rékọjá Òkun lọ sí Kapernaumu. Ilẹ̀ sì ti ṣú, Jesu kò sì tí ì dé ọ̀dọ̀ wọn. 18 Òkun sì ń ru nítorí ẹ̀fúùfù líle tí ń fẹ́. 19 Nígbà tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi tó bí ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jesu ń rìn lórí Òkun, ó sì súnmọ́ ọkọ̀ ojú omi náà; ẹ̀rù sì bà wọ́n. 20 Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.” 21 Nítorí náà wọ́n fi ayọ̀ gbà á sínú ọkọ̀; lójúkan náà ọkọ̀ náà sì dé ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń lọ.

22 Ní ọjọ́ kejì nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó dúró ní òdìkejì Òkun rí i pé, kò sí ọkọ̀ ojú omi mìíràn níbẹ̀, bí kò ṣe ọ̀kan náà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ̀, àti pé Jesu kò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi náà, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni ó lọ. 23 Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ̀ ojú omi mìíràn ti Tiberia wá, létí ibi tí wọn gbé jẹ àkàrà, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti dúpẹ́; 24 Nítorí náà nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Jesu tàbí ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò sí níbẹ̀, àwọn pẹ̀lú wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kapernaumu, wọ́n ń wá Jesu.

Jesu oúnjẹ ìyè

25 Nígbà tí wọ́n sì rí i ní apá kejì Òkun, wọ́n wí fún un pé, “Rabbi, nígbà wo ni ìwọ wá síhìn-ín yìí?”

26 Jesu dá wọn lóhùn ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹ̀yin ń wá mi, kì í ṣe nítorí tí ẹ̀yin rí iṣẹ́ ààmì, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀yin jẹ àjẹyó ìṣù àkàrà. 27 (H)Ẹ má ṣe ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún oúnjẹ tí ó wà títí di ayé àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọmọ ènìyàn yóò fi fún yín: nítorí pé òun ni, àní Ọlọ́run Baba ti fi èdìdì dì í.”

28 Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, “Kín ni àwa ó ha ṣe, kí a lè ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run?”

29 (I)Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni iṣẹ́ Ọlọ́run pé, kí ẹ̀yin gba ẹni tí ó rán an gbọ́.”

30 (J)Nígbà náà ni wọ́n wí fún wọn pé, “Iṣẹ́ ààmì kín ní ìwọ ń ṣe, tí àwa lè rí, kí a sì gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ kín ní ìwọ ṣe? 31 (K)Àwọn baba wa jẹ manna ní aginjù; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ó fi oúnjẹ láti ọ̀run wá fún wọn jẹ.’ ”

32 Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kì í ṣe Mose ni ó fi oúnjẹ fún yín láti ọ̀run wá; ṣùgbọ́n Baba mi ni ó fi oúnjẹ òtítọ́ náà fún yín láti ọ̀run wá. 33 Nítorí pé oúnjẹ Ọlọ́run ni èyí tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó sì fi ìyè fún aráyé.”

34 (L)Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Olúwa, máa fún wa ní oúnjẹ yìí títí láé.”

35 (M)Jesu wí fún wọn pé, “Èmi ni oúnjẹ ìyè: ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yóò pa á; ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé. 36 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Ẹ̀yin ti rí mi, ẹ kò sì gbàgbọ́. 37 (N)Gbogbo èyí tí Baba fi fún mi, yóò tọ̀ mí wá; ẹni tí ó bá sì tọ̀ mí wá, èmi kì yóò tà á nù, bí ó tí wù kó rí. 38 (O)Nítorí èmi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti máa ṣe ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi. 39 (P)Èyí sì ni ìfẹ́ Baba tí ó rán mi pé ohun gbogbo tí o fi fún mi, kí èmi má ṣe sọ ọ̀kan nù nínú wọn, ṣùgbọ́n kí èmi lè jí wọn dìde níkẹyìn ọjọ́. 40 (Q)Èyí sì ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo ọmọ, tí ó bá sì gbà á gbọ́, kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.”

41 Nígbà náà ni àwọn Júù ń kùn sí i, nítorí tí ó wí pé, “Èmi ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá.” 42 (R)Wọ́n sì wí pé, “Jesu ha kọ́ èyí, ọmọ Josẹfu, baba àti ìyá ẹni tí àwa mọ̀? Báwo ni ó ṣe wí pé, ‘Èmi ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá’?”

43 Nítorí náà Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàrín yín! 44 (S)Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, bí kò ṣe pé Baba tí ó rán mi fà á: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́. 45 (T)A sá à ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé, ‘A ó sì kọ́ gbogbo wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá,’ nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́, tí a sì ti ọ̀dọ̀ Baba kọ́, òun ni ó ń tọ̀ mí wá. 46 (U)Kì í ṣe pé ẹnìkan ti rí Baba bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, òun ni ó ti rí Baba. 47 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun. 48 Èmi ni oúnjẹ ìyè. 49 Àwọn baba yín jẹ manna ní aginjù, wọ́n sì kú. 50 Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú. 51 Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá: bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé: oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.”

52 (V)Nítorí náà ni àwọn Júù ṣe ń bá ara wọn jiyàn, pé, “Ọkùnrin yìí yóò ti ṣe lè fi ara rẹ̀ fún wa láti jẹ?”

53 Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá jẹ ara ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin kò ní ìyè nínú yin. 54 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun; Èmi o sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́. 55 Nítorí ara mi ni ohun jíjẹ nítòótọ́, àti ẹ̀jẹ̀ mi ni ohun mímu nítòótọ́. 56 (W)Ẹni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ń gbé inú mi, èmi sì ń gbé inú rẹ̀. 57 Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, tí èmi sì yè nípa Baba gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó jẹ mí, òun pẹ̀lú yóò yè nípa mi. 58 (X)Èyí sì ni oúnjẹ náà tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá: kì í ṣe bí àwọn baba yín ti jẹ manna, tí wọ́n sì kú: ẹni tí ó bá jẹ́ oúnjẹ yìí yóò yè láéláé.” 59 (Y)Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ nínú Sinagọgu, bí ó ti ń kọ́ni ní Kapernaumu.

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yọ́ Jesu sílẹ̀

60 Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Ọ̀rọ̀ tí ó le ni èyí; ta ní lè gbọ́ ọ?”

61 (Z)Nígbà tí Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn sí ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Èyí jẹ́ ìkọ̀sẹ̀ fún yín bí? 62 (AA)Ǹjẹ́, bí ẹ̀yin bá sì rí i tí ọmọ ènìyàn ń gòkè lọ sí ibi tí ó gbé ti wà rí ńkọ́? 63 (AB)Ẹ̀mí ní ń sọ ni di ààyè; ara kò ní èrè kan; ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo sọ fún yín, ẹ̀mí ni, ìyè sì ni pẹ̀lú. 64 (AC)Ṣùgbọ́n àwọn kan wà nínú yín tí kò gbàgbọ́.” Nítorí Jesu mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá ẹni tí wọ́n jẹ́ tí kò gbàgbọ́, àti ẹni tí yóò fi òun hàn. 65 (AD)Ó sì wí pé, “Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, kò sí ẹni tí ó lè tọ̀ mí wá, bí kò ṣe pé a fi fún un láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá.”

66 Nítorí èyí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ padà sẹ́yìn, wọn kò sì bá a rìn mọ́.

67 Nítorí náà Jesu wí fún àwọn méjìlá pé, “Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ lọ bí?”

68 (AE)Nígbà náà ni Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa ó lọ? Ìwọ ni ó ni ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun. 69 Àwa sì ti gbàgbọ́, a sì mọ̀ pé ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”

70 (AF)Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin méjìlá kọ́ ni mo yàn, ọ̀kan nínú yín kò ha sì ya èṣù?” 71 (AG)(Ó ń sọ ti Judasi Iskariotu ọmọ Simoni ọ̀kan nínú àwọn méjìlá: nítorí pé òun ni ẹni tí yóò fi í hàn.)

Òwe 3

Àwọn àǹfààní ọgbọ́n mìíràn

Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi.
    Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.
Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà,
    ni wọn yóò fi kùn un fún ọ.

Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé
    so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ,
    kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ.
(A)Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere
    ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.

Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ
    má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ;
Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ
    òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ.

(B)Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ
    bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.
Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ
    àti okun fún àwọn egungun rẹ.

Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa,
    pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ
10 Nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya
    àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.

11 (C)Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa
    má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,
12 Nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí
    bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.

13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,
    ẹni tí ó tún ní òye sí i
14 Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ
    ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.
15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;
    kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.
16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;
    ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.
17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,
    òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.
18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;
    àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.

19 Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;
20 Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà,
    àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.

21 Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́,
    má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn.
22 Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ,
    àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ.
23 Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu,
    ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀;
24 Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù,
    nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀.
25 Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì,
    tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú.
26 Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ,
    kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.

27 Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ,
    nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.
28 Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé,
    “Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,”
    nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.
29 Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ,
    ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.
30 Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí,
    nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.

31 Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan
    tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

32 Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyídáyidà
    ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.
33 Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú,
    ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo.
34 (D)Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́,
    ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀.
35 Ọlọ́gbọ́n jogún iyì,
    ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.

Galatia 2

Àwọn aposteli tẹ́wọ́ gba Paulu

(A)Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá, ni mo tún gòkè lọ sì Jerusalẹmu pẹ̀lú Barnaba, mo sì mú Titu lọ pẹ̀lú mi. Mo gòkè lọ nípa ohun ti a fihàn mi, mo fi ìhìnrere náà tí mo ń wàásù láàrín àwọn aláìkọlà yé àwọn tí ó jẹ́ ẹni ńlá nínú wọn, èyí i nì ní ìkọ̀kọ̀, kí èmi kí ó má ba á sáré, tàbí kí ó máa ba à jẹ́ pé mo ti sáré lásán. Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Titu tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Giriki láti kọlà. Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárín wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kristi Jesu, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè. (B)Àwọn ẹni ti a kò fún ni àǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn fún ìṣẹ́jú kan; kí ẹ̀yin kí o lè máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ ìhìnrere náà.

(C)Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dàbí ẹni pàtàkì—ohunkóhun tí ó wù kì wọn jásí, kò jẹ́ nǹkan kan fún mi; Ọlọ́run kò fi bí ẹnikẹ́ni ṣe rí ṣe ìdájọ́ rẹ̀—àwọn ènìyàn yìí kò fi ohunkóhun kún ọ̀rọ̀ mi. Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọn rí i pé a tí fi ìhìnrere tí àwọn aláìkọlà le mi lọ́wọ́, bí a tí fi ìhìnrere tí àwọn onílà lé Peteru lọ́wọ́. Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Peteru gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn Júù, òun kan náà ni ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn aláìkọlà. Jakọbu, Peteru, àti Johanu, àwọn ẹni tí ó dàbí ọ̀wọ́n, fún èmi àti Barnaba ni ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ nígbà tí wọ́n rí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, wọ́n sì gbà pé kí àwa náà tọ àwọn aláìkọlà lọ, nígbà ti àwọn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù. 10 Ohun gbogbo tí wọ́n béèrè fún ni wí pé, kí a máa rántí àwọn tálákà, ohun kan náà gan an tí mo ń làkàkà láti ṣe.

Paulu tako Peteru

11 (D)Ṣùgbọ́n nígbà tí Peteru wá sí Antioku, mo takò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ̀bi, mo sì bá a wí. 12 Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fàsẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà. 13 Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Barnaba lọ́nà.

14 Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìhìnrere, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn kèfèrí, èéṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn keferi láti máa rìn bí àwọn Júù?

15 “Àwa tí i ṣe Júù nípa ìbí, tí kì i sí ì ṣe ‘aláìkọlà ẹlẹ́ṣẹ̀,’ 16 (E)Tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹ́ni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, àní àwa pẹ̀lú gbà Jesu Kristi gbọ́, kí a bá a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kristi, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre.

17 “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kristi, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kristi ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì! 18 Nítorí pé bí mo bá sì tún gbé àwọn ohun tí mo tí wó palẹ̀ ró, mo fi ara mi hàn bí arúfin.

19 “Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láààyè sí Ọlọ́run. 20 (F)A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kristi, èmí kò sì wà láààyè mọ́, ṣùgbọ́n Kristi ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láààyè nínú ara, mo wà láààyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkára rẹ̀ fún mi. 21 Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apá kan: nítorí pé bí a bá le ti ipasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kristi kú lásán.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.