Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Eksodu 38

Pẹpẹ ẹbọ sísun

38 (A)Ó sì fi igi kasia kọ́ pẹpẹ ẹbọ sísun, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni gíga rẹ̀: ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, igun rẹ̀ ṣe déédé. Ó ṣe ìwo sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, nítorí kí ìwo àti pẹpẹ náà lè jẹ́ ọ̀kan, ó sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ. Idẹ ni ó ṣe gbogbo ohun èlò pẹpẹ, ìkòkò rẹ̀, ọkọ, àwokòtò rẹ̀, fọ́ọ̀kì tí a fi n mú ẹran àti àwo iná rẹ̀. Ó ṣe ààrò fún pẹpẹ náà, àwọ̀n onídẹ, kí ó wà níṣàlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, dé ìdajì òkè pẹpẹ náà. Ó dá òrùka idẹ láti mú kí ó di òpó igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin idẹ ààrò náà mú. Ó sì fi igi kasia ṣe àwọn òpó náà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú idẹ. Ó sì fi òpó náà bọ inú òrùka, nítorí kí ó lè wà ní ìhà pẹpẹ náà láti máa fi gbé e. Ó sì fi pákó ṣé pẹpẹ náà ní oníhò nínú.

Agbada fún fífọ̀

(B)Ó ṣe agbada idẹ, o sì fi idẹ ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀ ti àwòjìji àwọn obìnrin tí ó ń sìn ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ.

Àgbàlá inú

(C)Ó sì ṣe àgbàlá inú náà. Ní ìhà gúúsù ni aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára wà, ó jẹ́ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ní gígùn, 10 pẹ̀lú ogún òpó àti ogún (20) ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, àti pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà. 11 Ní ìhà àríwá náà tún jẹ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ní gígùn, ó sì ní ogún òpó àti ogun ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà.

12 Ìhà ìwọ̀-oòrùn jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà pọ̀. 13 Fún ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn ti ń yọ náà jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ni fífẹ̀ 14 Aṣọ títa ìhà ẹnu-ọ̀nà kan jẹ́ mítà mẹ́fà ààbọ̀, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta, 15 àti aṣọ títa ní ìhà kejì tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ mítà mẹ́fà ààbọ̀ pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́fà. 16 Gbogbo aṣọ tí ó yí àgbàlá náà jẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. 17 Ihò ìtẹ̀bọ̀ fún òpó náà idẹ ni. Ìkọ́ òpó náà àti ìgbànú tí ó wà lára òpó náà jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà; gbogbo àwọn òpó àgbàlá náà ní ìgbànú fàdákà.

18 Aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe; ogún ìgbọ̀nwọ́ sì ni gígùn rẹ̀, àti gíga rẹ̀ ní ìbò rẹ̀ jẹ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó bá aṣọ títa àgbàlá wọ̀n-ọn-nì ṣe déédé, 19 pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ mẹ́rin. Ìkọ́ àti ìgbànú wọn jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà. 20 Gbogbo èèkàn àgọ́ tabanaku náà àti ti àyíká àgbàlá náà jẹ́ idẹ.

Àwọn ohun èlò tí a lò

21 Wọ̀nyí ni iye ohun èlò tí a lò fún tabanaku náà, tabanaku ẹ̀rí, èyí ti a kọ bí òfin Mose nípa àwọn ọmọ Lefi ní abẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni àlùfáà. 22 (Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, ṣe ohun gbogbo ti Olúwa pàṣẹ fún Mose; 23 Pẹ̀lú rẹ̀ ni Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani: alágbẹ̀dẹ, àti oníṣẹ́-ọnà àti oníṣọ̀nà tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe ní aṣọ aláró àti elése àlùkò àti òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára.) 24 Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ǹtì mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n àti ẹgbẹ̀rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí i ṣékélì ibi mímọ́.

25 (D)Fàdákà tí a rí nínú ìjọ, ẹni tí a kà nínú ìkànìyàn jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ǹtì àti òjìlélẹ́gbẹ̀sán ó-lé-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, 26 ààbọ̀ ṣékélì kan ní orí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, lórí olúkúlùkù ẹni tí ó ti kọjá tí a ti kà, láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àròpọ̀ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n-ọ̀kẹ́-lé-ẹgbẹ̀ta-dínlógún ó-lé-àádọ́jọ ọkùnrin (603,550). 27 Ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà ní a lò láti fi dá ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ibi mímọ́ àti fún aṣọ títa ọgọ́rùn-ún ihò ìtẹ̀bọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì náà tálẹ́ǹtì kan fún ihò ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan. 28 Ó lo òjì-dínlẹ́gbẹ̀san ó-lé-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣékélì (1,775 shekels) ni ó fi ṣe ìkọ́ fún òpó náà, láti fi bo orí òpó náà àti láti fi ṣe ọ̀já wọn.

29 Idẹ ara ọrẹ náà jẹ́ àádọ́rin tálẹ́ǹtì àti egbèjìlá ṣékélì. 30 Ó lò ó láti fi ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, pẹpẹ idẹ náà pẹ̀lú ààrò idẹ rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, 31 ihò ìtẹ̀bọ̀ àgbàlá náà àyíká àti ihò ìtẹ̀bọ̀ ẹnu-ọ̀nà àgbàlá àti gbogbo èèkàn àgọ́ náà, àti gbogbo èèkàn àgbàlá náà yíká.

Johanu 17

Jesu gbàdúrà fún ara rẹ̀

17 (A)Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ó sì wí pé:

“Baba, wákàtí náà dé, yin ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ kí ó lè yìn ọ́ lógo pẹ̀lú. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fún un ní àṣẹ lórí ènìyàn gbogbo, kí ó lè fi ìyè àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó fi fún un. Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ ìwọ nìkan Ọlọ́run òtítọ́, àti Jesu Kristi, ẹni tí ìwọ rán. Èmi ti yìn ọ́ lógo ní ayé: èmi ti parí iṣẹ́ tí ìwọ fi fún mi láti ṣe. (B)Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Baba, ṣe mí lógo pẹ̀lú ara rẹ, ògo tí mo ti ní pẹ̀lú rẹ kí ayé kí ó tó wà.

Jesu gbàdúrà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn

“Èmi ti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ti fún mi láti inú ayé wá: tìrẹ ni wọ́n ti jẹ́, ìwọ sì ti fi wọ́n fún mi; wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́. Nísinsin yìí, wọ́n mọ̀ pé ohunkóhun gbogbo tí ìwọ ti fi fún mi, láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni. Nítorí ọ̀rọ̀ tí ìwọ fi fún mi, èmi ti fi fún wọn, wọ́n sì ti gbà á, wọ́n sì ti mọ̀ nítòótọ́ pé, lọ́dọ̀ rẹ ni mo ti jáde wá, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi. (C)Èmi ń gbàdúrà fún wọn: èmi kò gbàdúrà fún aráyé, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ìwọ ti fi fún mi; nítorí pé tìrẹ ni wọ́n í ṣe. 10 Tìrẹ sá à ni gbogbo ohun tí í ṣe tèmi, àti tèmi sì ni gbogbo ohun tí í ṣe tìrẹ, a sì ti ṣe mí lógo nínú wọn. 11 (D)Èmi kò sí ní ayé mọ́, àwọn wọ̀nyí sì ń bẹ ní ayé, èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́, ní orúkọ rẹ, kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, àní gẹ́gẹ́ bí àwa. 12 (E)Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn ní ayé, mo pa wọ́n mọ́ ní orúkọ rẹ; àwọn tí ìwọ fi fún mi, ni mo ti pamọ́, ẹnìkan nínú wọn kò sọnù bí kò ṣe ọmọ ègbé; kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ.

13 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, nǹkan wọ̀nyí ni mo sì ń sọ ní ayé, kí wọn kí ó lè ní ayọ̀ mi ní kíkún nínú àwọn tìkára wọn. 14 (F)Èmi ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn; ayé sì ti kórìíra wọn, nítorí tí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. 15 Èmi kò gbàdúrà pé, kí ìwọ kí ó mú wọn kúrò ní ayé, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ibi. 16 Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé. 17 Sọ wọ́n di mímọ́ nínú òtítọ́: òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ. 18 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti rán mi wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán wọn sí ayé pẹ̀lú. 19 Èmi sì ya ara mi sí mímọ́ nítorí wọn, kí a lè sọ àwọn tìkára wọn pẹ̀lú di mímọ́ nínú òtítọ́.

Jesu gbàdúrà fún gbogbo onígbàgbọ́

20 “Kì sì í ṣe kìkì àwọn wọ̀nyí ni mo ń gbàdúrà fún, ṣùgbọ́n fún àwọn pẹ̀lú tí yóò gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn; 21 (G)Kí gbogbo wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan; gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti jẹ́ nínú mi, àti èmi nínú rẹ, kí àwọn pẹ̀lú kí ó lè jẹ́ ọ̀kan nínú wa: kí ayé kí ó lè gbàgbọ́ pé, ìwọ ni ó rán mi. 22 Ògo tí ìwọ ti fi fún mi ni èmi sì ti fi fún wọn; kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́ ọ̀kan; 23 Èmi nínú wọn, àti ìwọ nínú mi, kí a lè ṣe wọ́n pé ní ọ̀kan; kí ayé kí ó lè mọ̀ pé, ìwọ ni ó rán mi, àti pé ìwọ sì fẹ́ràn wọn gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́ràn mi.

24 (H)“Baba, èmi fẹ́ kí àwọn tí ìwọ fi fún mi, kí ó wà lọ́dọ̀ mi, níbi tí èmi gbé wà; kí wọn lè máa wo ògo mi, tí ìwọ ti fi fún mi: nítorí ìwọ sá à fẹ́ràn mi síwájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

25 “Baba olódodo, ayé kò mọ̀ ọ́n; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, àwọn wọ̀nyí sì mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi. 26 Mo ti sọ orúkọ rẹ di mí mọ̀ fún wọn, èmi ó sì sọ ọ́ di mí mọ̀: kí ìfẹ́ tí ìwọ fẹ́ràn mi, lè máa wà nínú wọn, àti èmi nínú wọn.”

Òwe 14

14 Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀,
    ṣùgbọ́n aṣiwèrè obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ fà á lulẹ̀.

Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù Olúwa,
    ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn Olúwa.

Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàṣán fún ẹ̀yìn rẹ̀,
    ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.

Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóní
    ṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá.

Ẹlẹ́rìí tí ń ṣọ òtítọ́ kì í tan ni
    ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde.

Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,
    ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.

Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,
    nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.

Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn
    ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ.

Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀
    ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere.

10 Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀
    kò sì ṣí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.

11 A ó pa ilé ènìyàn búburú run
    Ṣùgbọ́n àgọ́ olódodo yóò máa gbèrú sí i.

12 Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn,
    ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa jásí ikú.

13 Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora;
    ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́.

14 A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀,
    ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀.

15 Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́
    ṣùgbọ́n olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.

16 Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi
    ṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra.

17 Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè,
    a sì kórìíra eléte ènìyàn.

18 Òpè jogún ìwà òmùgọ̀
    ṣùgbọ́n a dé ọlọ́gbọ́n ní adé ìmọ̀.

19 Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rere
    àti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo.

20 Kódà àwọn aládùúgbò tálákà kò fẹ́ràn rẹ̀
    ṣùgbọ́n, ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀.

21 Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀
    ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní.

22 Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í ṣìnà bí?
    Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbèrò ohun rere ń rí ìfẹ́ àti òtítọ́.

23 Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá,
    ṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni.

24 Ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni adé orí wọn
    ṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá.

25 Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí là
    ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn.

26 Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára,
    yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.

27 Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè,
    tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.

28 Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo ọba,
    ṣùgbọ́n láìsí ìjòyè, ọba á parun.

29 Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀,
    ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.

30 Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara,
    ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.

31 Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn
    ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.

32 Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀,
    kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.

33 Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóye
    kódà láàrín àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun.

34 Òdodo a máa gbé orílẹ̀-èdè lékè,
    ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ.

35 Ọba a máa ní inú dídùn sí ìránṣẹ́ tí ó gbọ́n
    ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ wá sórí ìránṣẹ́ adójútini.

Filipi 1

(A)Paulu àti Timotiu, àwọn ìránṣẹ́ Jesu Kristi.

Sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu tí ó wà ní Filipi, pẹ̀lú àwọn alábojútó àti àwọn díákónì.

(B)Oore-ọ̀fẹ́ sí yín, àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Olúwa wa Jesu Kristi.

Àdúrà àti Ọpẹ́

Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín: Nínú gbogbo àdúrà mi fún un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà, nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìhìnrere láti ọjọ́ kìn-ín-ní wá títí di ìsinsin yìí. (C)Ohun kan yìí sá à dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ náà tí Jesu Kristi yóò dé:

(D)Gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi láti ro èyí nípa gbogbo yín, nítorí tí mo fi yín sọ́kàn, bí mo tilẹ̀ wà nínú ìdè tàbí ìdáhùn ẹjọ́, àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìhìnrere, gbogbo yín jẹ́ alábápín oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú mi. Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jesu Kristi.

Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti síwájú sí i nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, 10 kí ẹ̀yin kí ó lè ní òye ohun tí ó dára jùlọ; kí ó sì jásí òdodo àti aláìjẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ títí di ọjọ́ dídé Jesu Kristi: 11 Lẹ́yìn ìgbà ti ẹ ti kún fún àwọn ìwà òdodo láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.

Ìrírí Paulu nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́

12 (E)Ǹjẹ́ èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀, ará, pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi jásí àtẹ̀gùn sí ìlọsíwájú ìhìnrere. 13 (F)Nítorí ìdí èyí, ó ti hàn gbangba sí gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin àti sí àwọn ẹlòmíràn wí pé mo wà nínú ìdè fún Kristi. 14 Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni a ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù.

15 Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kristi, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é. 16 Àwọn kan ń fi ìjà wàásù Kristi, kì í ṣe pẹ̀lú òtítọ́ inú, wọ́n ń gbèrò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi: 17 Àwọn kan ẹ̀wẹ̀ si ń fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a gbé mi dìde láti dá ààbò bo iṣẹ́ ìhìnrere. 18 Kí ló tún kù? Kìkì í pé níbi gbogbo, ìbá à ní ìfẹ̀tànṣe tàbí ni ti òtítọ́ a sá à n wàásù Kristi, èmi sì ń yọ̀ nítorí èyí.

Nítòótọ́, èmi ó sì máa yọ̀, 19 (G)nítorí tí mo mọ̀ pé èyí ni yóò yọrí sí ìgbàlà fún mi láti inú àdúrà yín wá, àti ìfikún ẹ̀mí Jesu Kristi, 20 (H) Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn àti ìrètí mi pé kí ojú kí ó má ṣe ti mi ní ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí èmi kí ó le máa ni ìgboyà ní ìgbà gbogbo àti nísinsin yìí, kí a lè ti ipasẹ̀ mi gbé Kristi ga lára mi, ìbá à ṣe pé mo wà láààyè, tàbí mo kú. 21 (I)Nítorí, ní ti èmi, láti wa láààyè jẹ́ Kristi, láti kú pẹ̀lú sì jẹ́ èrè fún mi. 22 Ṣùgbọ́n bí èmi bá le è ṣe iṣẹ́ ti ó ni àpẹẹrẹ nípa wíwà láààyè nínú ara, ṣùgbọ́n ohun ti èmi ó yàn, èmi kò mọ̀. 23 Ṣùgbọ́n èmi n ṣiyèméjì, nítorí ti èmi fẹ́ láti lọ kúrò nínú ayé yìí, láti wà lọ́dọ̀ Kristi; nítorí ó dára púpọ̀ jù: 24 Síbẹ̀ láti wà láààyè jẹ́ àǹfààní nítorí tiyín. 25 Bí èyí sì ti dá mi lójú, mo mọ̀ pé èmi ó dúró, èmi ó sì máa wà pẹ̀lú yín fún ìtẹ̀síwájú àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́, 26 kí ìṣògo yín kí ó lè di púpọ̀ gidigidi nínú Jesu Kristi, àti nínú mi nípa ìpadà wá mi sọ́dọ̀ yín.

27 Ohun yówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé yín ri gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere Kristi: pé yálà bi mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi kí ó lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin jùmọ̀ jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìhìnrere, pẹ̀lú ọkàn kan; 28 (J)Kí ẹ má sì jẹ́ ki àwọn ọ̀tá dẹ́rùbà yin ni ohunkóhun: èyí tí í ṣe ààmì tí ó dájú pé a ó pa wọ́n run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ni yóò gbà yin là. 29 Nítorí tí a ti fún yin ni àǹfààní, kì í ṣe láti gba Kristi gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú: 30 (K)Ẹ sì máa ja ìjà kan náà, èyí ti ẹ̀yin ti ri, ti ẹ sì ti gbọ́ pé èmi n jà pẹ̀lú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.