M’Cheyne Bible Reading Plan
Omi láti inú àpáta
17 (A)Gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli si gbéra láti jáde kúrò láti aginjù Sini wọ́n ń lọ láti ibi kan de ibi kan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ. Wọ́n pàgọ́ sí Refidimu, ṣùgbọ́n kò sí omi fún àwọn ènìyàn láti mú. 2 Àwọn ènìyàn sì sọ̀ fún Mose, wọ́n wí pé, “Fún wa ni omi mu.”
Mose dá wọn lóhùn wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bá mi jà? Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán Olúwa wò?”
3 (B)Ṣùgbọ́n òǹgbẹ ń gbẹ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń kùn sí Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde kúrò ní Ejibiti láti mú kí òǹgbẹ pa àwa, àwọn ọmọ wa àti ohun ọ̀sìn wa ku fún òǹgbẹ.”
4 Nígbà náà ni Mose gbé ohùn rẹ̀ sókè sí Olúwa pé; “Kí ni kí èmi kí ó ṣe fún àwọn ènìyàn yìí? Wọ́n múra tan láti sọ mi ni òkúta.”
5 Olúwa sì dá Mose lóhùn pé, “Máa lọ síwájú àwọn ènìyàn, mú nínú àwọn àgbàgbà Israẹli pẹ̀lú rẹ, mú ọ̀pá tí ìwọ fi lu odò Naili lọ́wọ́ kí ó sì máa lọ. 6 Èmi yóò dúró ni ibẹ̀ dè ọ ni orí àpáta ni Horebu. Ìwọ ó sì lu àpáta, omi yóò sì jáde nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti mu.” Mose sì ṣe bẹ́ẹ̀ ni iwájú àwọn àgbàgbà Israẹli. 7 Ó sì sọ orúkọ ibẹ̀ ni Massa (ìdánwò) àti Meriba (kíkùn) nítorí àwọn ọmọ Israẹli sọ̀, wọ́n sì dán Olúwa wò, wọ́n wí pé, “Ǹjẹ́ Olúwa ń bẹ láàrín wa tàbí kò sí?”
A ṣẹ́gun àwọn ará Ameleki
8 Àwọn ara Amaleki jáde, wọ́n sì dìde ogun sí àwọn ọmọ Israẹli ni Refidimu. 9 Mose sì sọ fún Joṣua pé, “Yàn lára àwọn ọkùnrin fún wa, kí wọn ó sì jáde lọ bá àwọn ará Amaleki jà. Ní ọ̀la, èmi yóò dúró ni orí òkè pẹ̀lú ọ̀pá Ọlọ́run ní ọwọ́ mi.”
10 Joṣua ṣe bí Mose ti wí fún un, ó sì bá àwọn ará Amaleki jagun; nígbà tí Mose, Aaroni àti Huri lọ sí orí òkè náà. 11 Níwọ́n ìgbà tí Mose bá gbé apá rẹ̀ sókè, Israẹli n borí ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá sì rẹ apá rẹ̀ sílẹ̀, Amaleki a sì borí. 12 Ṣùgbọ́n apá ń ro Mose; Wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà: Aaroni àti Huri sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì; apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti oòrùn wọ. 13 Joṣua sì fi ojú idà ṣẹ́gun àwọn ará Amaleki.
14 (C)Olúwa sì sọ fun Mose pé. “Kọ èyí sì inú ìwé fún ìrántí, kí o sì sọ fún Joṣua pẹ̀lú; nítorí èmi yóò pa ìrántí Amaleki run pátápátá kúrò lábẹ́ ọ̀run.”
15 Mose sì tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì sọ orúkọ pẹpẹ náà ní Olúwa ni àsíá mi (Jehofa-Nisi). 16 Ó wí pé, “A gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ Olúwa. Olúwa yóò bá Amaleki jagun láti ìran dé ìran.”
Wọ́n béèrè nípa àṣẹ Jesu
20 (A)Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹmpili tí ó sì ń wàásù ìhìnrere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà dìde sí i. 2 (B)Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Tàbí ta ni ó fún ọ ní àṣẹ yìí?”
3 Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi pẹ̀lú yóò sì bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan; ẹ sì fi ìdáhùn fún mi. 4 Ìtẹ̀bọmi Johanu, láti ọ̀run wá ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?”
5 Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé, ‘Láti ọ̀run wá ni,’ òun yóò wí pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’ 6 (C)Ṣùgbọ́n bí àwa bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ gbogbo ènìyàn ni yóò sọ wá ní òkúta, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé, wòlíì ni Johanu.”
7 Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa kò mọ̀ ibi tí ó ti wá.”
8 Jesu sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ èmi kì yóò wí fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”
Òwe àwọn ayálégbé
9 (D)(E) Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́. 10 Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùṣọ́gbà náà: kí wọn lè fún un nínú èso ọgbà àjàrà náà: ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. 11 Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn: wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. 12 Ó sì tún rán ẹ̀kẹta: wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde.
13 “Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn yóò bu ọlá fún un.’
14 “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbèrò pé, ‘Èyí ni àrólé; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa.’ 15 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tì í jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á.
“Ǹjẹ́ kín ni olúwa ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn? 16 (F)Yóò wá, yóò sì pa àwọn alágbàtọ́jú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn.”
Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n ní, “Kí a má ri i!”
17 (G)Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:
“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé’?
18 (H)Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá ṣubú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”
19 (I)Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn.
Sísan owó orí fún Kesari
20 (J)Wọ́n sì ń ṣọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn ayọ́lẹ̀wò tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtítọ́ ènìyàn, kí wọn ba à lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn ba à lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́. 21 (K)Wọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lóòtítọ́. 22 Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó òde fún Kesari, tàbí kò tọ́?”
23 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé, 24 “Ẹ fi owó idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti ta ni ó wà níbẹ̀?”
Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.”
25 (L)Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Kesari fún Kesari, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”
26 Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́.
Àjíǹde àti ìgbéyàwó
27 (M)(N) Àwọn Sadusi kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí: wọ́n sì bi í, 28 (O)wí pé, “Olùkọ́, Mose kọ̀wé fún wa pé: Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀. 29 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. 30 Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ. 31 Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú. 32 Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú. 33 Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya ti ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sá à ni í ní aya.”
34 Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún ni. 35 Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún ni. 36 Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn angẹli dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde. 37 (P)Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mose tìkára rẹ̀ sì ti fihàn nínú igbó, nígbà tí ó pe ‘Olúwa ni Ọlọ́run Abrahamu, àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ 38 Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè: nítorí gbogbo wọn wà láààyè fún un.”
39 (Q)Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, “Olùkọ́ ìwọ wí rere!” 40 (R)Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́.
Ọmọ ta ni Jesu n ṣe
41 (S)Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, Ọmọ Dafidi ni Kristi? 42 Dafidi tìkára rẹ̀ sì wí nínú ìwé Saamu pé:
“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
43 títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’
44 Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
45 (T)Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé, 46 “Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn nínú aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu, àti ipò ọlá ní ibi àsè; 47 Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn: àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”
Olóòtítọ́ ni Ọlọ́run
35 Elihu sì wí pe:
2 “Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé,
òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run?
3 Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóò jásí fún ọ,
tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.
4 “Èmi ó dá ọ lóhùn
àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ pẹ̀lú rẹ.
5 Síjú wo ọ̀run; kí o rí i, kí ó sì
bojú wo àwọsánmọ̀ tí ó ga jù ọ́ lọ.
6 Bí ìwọ bá dẹ́ṣẹ̀, kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí?
Tàbí bí ìrékọjá rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i?
7 Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọ fi fún un,
tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?
8 Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bí ìwọ;
òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn.
9 “Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n mú ni kígbe;
wọ́n kígbe nípa apá àwọn alágbára.
10 Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé,
‘Níbo ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;
11 Tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọn ẹranko ayé lọ,
tí ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’
12 Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dáhùn
nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.
13 Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ asán;
bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí.
14 Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì í rí i,
ọ̀rọ̀ ìdájọ́ ń bẹ níwájú rẹ,
ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.
15 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nítorí tí ìbínú rẹ̀ kò tí fìyà jẹ ni,
òun kò ni ka ìwà búburú si?
16 Nítorí náà ní Jobu ṣe ya ẹnu rẹ̀
lásán ó sọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìsí ìmọ̀.”
Ibùgbé wa ọrun
5 Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run. 2 Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá. 3 Bí ó bá ṣe pé a ti fi wọ̀ wá, a kì yóò bá wa ní ìhòhò. 4 Nítorí àwa tí a ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa fẹ́ jẹ́ aláìwọṣọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè ba à lè gbé ara kíkú mì. 5 Ǹjẹ́ ẹni tí ó ti pèsè wa fún nǹkan yìí ni Ọlọ́run, ẹni tí o sì ti fi Ẹ̀mí fún wa pẹ̀lú ni ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ń bọ̀.
6 Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa. 7 Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rí rí. 8 Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa. 9 Nítorí náà àwa ń ṣakitiyan, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. 10 Nítorí pé gbogbo wa ni ó gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi; kí olúkúlùkù lè gbà èyí tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́ sí i nígbà tí ó wà nínú ara ìbá à ṣe rere tàbí búburú.
Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà tí a yà sọ́tọ̀
11 Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fi wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hàn ní ọkàn yín pẹ̀lú. 12 (A)Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lóde ara kì í ṣe ní ọkàn. 13 Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni: tàbí bí iyè wá bá ṣí pépé, fún yín ni. 14 (B)Nítorí ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú. 15 Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láààyè má sì ṣe wà láààyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.
16 Nítorí náà láti ìsinsin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ara, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́. 17 (C)Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé. 18 (D)Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹni tí ó sì tipasẹ̀ Jesu Kristi bá wa làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà fún wa. 19 Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kristi, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn; ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́. 20 (E)Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kristi, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín: àwa ń bẹ̀ yín ní ipò Kristi, “Ẹ bá Ọlọ́run làjà,” 21 (F)Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí: kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.