Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Eksodu 23

Òfin òdodo àti àánú

23 (A)“Ìwọ kò gbọdọ̀ tan ìròyìn èké kalẹ̀: Ìwọ kò gbọdọ̀ ran ènìyàn búburú lọ́wọ́ láti jẹ́rìí èké.

“Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀pọ̀ ènìyàn láti ṣe aburú. Nígbà tí ìwọ bá jẹ́rìí sí ẹjọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po nípa gbígbé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ènìyàn. (B)Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú sí tálákà nínú ẹjọ́ rẹ̀.

“Bí ìwọ bá ṣe alábàápàdé akọ màlúù tàbí akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ọ̀tá rẹ tí ó ṣìnà lọ, rí i dájú pé o mú un padà wá fún un. Bí ìwọ bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnìkan tí ó kórìíra rẹ tí ẹrù ṣubú lé lórí, má ṣe fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀; rí i dájú pé o ran án lọ́wọ́ nípa rẹ.

“Ìwọ kò gbọdọ̀ du aláìní ní ìdájọ́ òdodo. (C)Má ṣe lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn èké, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tàbí olódodo ènìyàn, nítorí Èmi kò ní dá ẹlẹ́bi láre.

(D)“Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́.

(E)“Ìwọ kò gbọdọ̀ pọ́n àjèjì kan lójú, ẹ̀yin sa ti mọ inú àjèjì, nítorí ẹ̀yin náà ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti.

Òfin Ọjọ́ Ìsinmi

10 (F)“Ní ọdún mẹ́fà ni ìwọ yóò gbin oko rẹ, ìwọ yóò sì kóre èso rẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, jẹ́ kí ilẹ̀ náà wà ní àìkọ àti ní àìlò, jẹ́ kí ilẹ̀ náà kí ó sinmi. Nígbà náà ni tálákà láàrín yín yóò rí oúnjẹ láti ibẹ̀. Ẹranko igbó yóò sì jẹ èyí tí wọ́n fi sílẹ̀. Ìwọ ṣe bákan náà pẹ̀lú ọgbà àjàrà rẹ àti ọgbà olifi rẹ.

12 (G)“Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì sinmi ní ọjọ́ keje, kí akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ bá à lè ní ìsinmi, kí a sì tú ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àlejò ti ń gbé ni ilé rẹ lára.

13 “Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo wí fún un yín. Ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà, kí a má ṣe gbọ́ orúkọ wọn ní ẹnu yín.

Àjọ̀dún Mẹ́ta Nínú Ọdún

14 (H)“Ní ìgbà mẹ́ta ni ìwọ yóò ṣe àjọ fún mi nínú ọdún.

15 “Ṣe àjọ àkàrà àìwú; jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje, bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní àkókò tí a ti yàn ní oṣù Abibu, nítorí ni oṣù yìí ni ìwọ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.

“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo.

16 “Ṣe àjọ ìkórè pẹ̀lú èso àkọ́so ọ̀gbìn oko rẹ.

“Ṣe àjọ àkójọ oko rẹ ní òpin ọdún, nígbà tí ìwọ bá kó ìre oko rẹ jọ tan.

17 “Ní ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ọkùnrin yín yóò máa wá fi ara hàn ní iwájú Olúwa Olódùmarè.

18 (I)“Ìwọ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ sí mi ti òun ti àkàrà tó ní ìwúkàrà.

“Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rá ẹbọ àjọ mi ni kò gbọdọ̀ kù títí di òwúrọ̀.

19 (J)“Mú àkọ́ká èso ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ.

“Ìwọ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ewúrẹ́ nínú omi ọmú ìyá rẹ̀.

Angẹli Olúwa ni yóò pèsè ọ̀nà sílẹ̀

20 “Kíyèsi èmi rán angẹli kan lọ ní iwájú rẹ, láti ṣọ́ ọ ni ọ̀nà àti láti mú ọ dé ibi ti mo ti pèsè sílẹ̀ fún. 21 Fi ara balẹ̀, kí o sì fetísílẹ̀ sí i, kí o sì gba ohùn rẹ̀ gbọ́; má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí i, nítorí kò ní fi àìṣedéédéé yín jì yín, orúkọ mi wà lára rẹ̀. 22 Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí ohùn rẹ̀ tí ẹ sì ṣe ohun gbogbo ti mo ní kí ẹ ṣe, èmi yóò jẹ́ ọ̀tá àwọn ọ̀tá yín. Èmi yóò sì fóòro àwọn tí ń fóòro yín. 23 Angẹli mi yóò lọ níwájú rẹ, yóò sì mú ọ dé ọ̀dọ̀ àwọn ará: Amori, Hiti, Peresi, Kenaani, Hifi àti Jebusi, èmi a sì gé wọn kúrò. 24 Ìwọ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún òrìṣà wọn, bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, tàbí kí ẹ tẹ̀lé ìṣe wọn. Kí ìwọ kí ó si wó wọn lulẹ̀, kí ìwọ kí ó sì fọ́ ère òkúta wọ́n túútúú. 25 Ẹ̀yin yóò sí máa sin Olúwa Ọlọ́run yin, òun yóò si bùsi oúnjẹ rẹ. Èmi yóò mú àìsàn kúrò láàrín rẹ. 26 Oyún kò ní bàjẹ́ lára obìnrin kan, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan kì yóò yàgàn ni ilẹ̀ rẹ. Èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.

27 “Èmi yóò rán ẹ̀rù mi lọ ṣáájú rẹ, ìdàrúdàpọ̀ yóò sì wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ bá da ojú kọ. Èmi yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ yí ẹ̀yìn padà sí ọ, kí wọn sì sá ní iwájú rẹ. 28 Èmi yóò rán oyin ṣáájú rẹ láti lé àwọn ará: Hifi, Kenaani àti Hiti kúrò ni ọ̀nà rẹ. 29 Ṣùgbọ́n, Èmi kò ni lé gbogbo wọn jáde ni ọdún kan ṣoṣo, ki ilẹ̀ náà má ba à di ahoro, àwọn ẹranko búburú yóò sì ti pọ̀jù fún ọ. 30 Díẹ̀díẹ̀ ni èmi yóò máa lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ, títí ìwọ yóò fi pọ̀ tó láti gba gbogbo ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ìní.

31 “Èmi yóò fi ìdí òpin ààlà ilẹ̀ rẹ lélẹ̀ láti etí Òkun pupa títí dé Òkun àwọn ara Filistini, láti aṣálẹ̀ títí dé etí odò Eufurate: Èmi yóò fa àwọn ènìyàn ti ń gbé ilẹ̀ náà lé ọ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ. 32 Ìwọ kò gbọdọ̀ dá májẹ̀mú kankan pẹ̀lú wọn tàbí pẹ̀lú àwọn òrìṣà wọn. 33 Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn gbé ni ilẹ̀ rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò mú ọ dẹ́ṣẹ̀ sí mi: nítorí bí ìwọ bá sin òrìṣà wọn, èyí yóò jẹ́ ìdẹ̀kùn fun ọ nítòótọ́.”

Johanu 2

Jesu sọ omi di ọtí wáìnì

(A)Ní ọjọ́ kẹta, wọn ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kana ti Galili. Ìyá Jesu sì wà níbẹ̀, A sì pe Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi ìgbéyàwó náà. (B)Nígbà tí wáìnì sì tán, ìyá Jesu wí fún un pé, “Wọn kò ní wáìnì mọ́.”

(C)Jesu fèsì pé, “Arábìnrin ọ̀wọ́n, èéṣe tí ọ̀rọ̀ yìí fi kàn mí? Àkókò mi kò tí ì dé.”

Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín.”

(D)Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ọgbọ̀n jálá.

Jesu wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí.” Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí.

Lẹ́yìn náà ni ó wí fún wọn pé, “Ẹ bù jáde lára rẹ̀ kí ẹ sì gbé e tọ alábojútó àsè lọ.”

Wọ́n sì gbé e lọ; alábojútó àsè náà tọ́ omi tí a sọ di wáìnì wò. Òun kò sì mọ ibi tí ó ti wá, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tí ó bu omi náà wá mọ̀. Alábojútó àsè sì pe ọkọ ìyàwó sí apá kan, 10 Ó sì wí fún un pé, “Olúkúlùkù a máa kọ́kọ́ gbé wáìnì tí ó dára jùlọ kalẹ̀; nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì mu ún yó tan, nígbà náà ní wọn a mú èyí tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ wá; ṣùgbọ́n ìwọ ti pa wáìnì dáradára yìí mọ́ títí ó fi di ìsinsin yìí.”

11 (E)Èyí jẹ́ àkọ́ṣe iṣẹ́ ààmì, tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Ó sì fi ògo rẹ̀ hàn; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.

Jesu ṣe àfọ̀mọ́ tẹmpili

12 (F)Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapernaumu, Òun àti ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: wọ́n sì gbé ibẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.

13 (G)Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, Jesu sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu, 14 (H)Ó sì rí àwọn tí n ta màlúù, àti àgùntàn, àti àdàbà, àti àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nínú tẹmpili wọ́n jókòó: 15 Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹmpili, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó si ti tábìlì wọn ṣubú. 16 (I)Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.” 17 (J)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì rántí pé, a ti kọ ọ́ pé, “Ìtara ilé rẹ jẹ mí run.”

18 (K)Nígbà náà ní àwọn Júù dáhùn, wọ́n sì bi í pé, “Ààmì wo ni ìwọ lè fihàn wá, tí ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí?”

19 (L)Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wó tẹmpili yìí palẹ̀, Èmi ó sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta.”

20 Nígbà náà ní àwọn Júù wí pé, “Ọdún mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ni a fi kọ́ tẹmpili yìí, ìwọ ó ha sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta?” 21 (M)Ṣùgbọ́n òun ń sọ ti tẹmpili ara rẹ̀. 22 (N)Nítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn; wọ́n sì gba ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ gbọ́.

23 Nígbà tí ó sì wà ní Jerusalẹmu, ní àjọ ìrékọjá, lákokò àjọ náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ ààmì tí ó ṣe. 24 Ṣùgbọ́n Jesu kò gbé ara lé wọn, nítorí tí ó mọ gbogbo ènìyàn. 25 (O)Òun kò sì nílò ẹ̀rí nípa ènìyàn: nítorí tí o mọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ènìyàn.

Jobu 41

Ọlọ́run ń tẹ̀síwájú láti pe Jobu níjà

41 “Ǹjẹ́ ìwọ le è fi ìwọ̀ fa Lefitani jáde?
    Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?
Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní í mú,
    tàbí fi ìwọ̀ ẹ̀gún gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́?
Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀
    rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́?
Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí?
    Ìwọ ó ha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí?
Ìwọ ha lè ba sáré bí ẹni pé ẹyẹ ni,
    tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀?
Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà á bí?
    Wọn ó ha pín láàrín àwọn oníṣòwò?
Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin gun awọ rẹ̀,
    tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ìpẹja.
Fi ọwọ́ rẹ lé e lára,
    ìwọ ó rántí ìjà náà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
Kíyèsi, ìgbìyànjú láti mú un ní asán;
    ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì?
10 Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè;
    Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi.
11 Ta ni ó kọ́kọ́ ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san án fún un?
    Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.

12 “Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara Lefitani,
    tàbí ipá rẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.
13 Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ̀?
    Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì eyín rẹ̀?
14 Ta ni ó lè ṣí ìlẹ̀kùn iwájú rẹ̀?
    Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.
15 Ìpẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀;
    ó pàdé pọ̀ tímọ́tímọ́ bí ààmì èdìdì.
16 Èkínní fi ara mọ́ èkejì tó bẹ́ẹ̀
    tí afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárín wọn.
17 Èkínní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀;
    wọ́n lè wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n.
18 Nípa sí sin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ á mọ́,
    ojú rẹ̀ a sì dàbí ìpéǹpéjú òwúrọ̀.
19 Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́-iná ti jáde wá,
    ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde.
20 Láti ihò imú rẹ ni èéfín ti jáde wá,
    bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìfèéfèé lábẹ́ rẹ̀.
21 Èémí rẹ̀ tiná bọ ẹ̀yin iná,
    ọ̀wọ́-iná sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.
22 Ní ọrùn rẹ̀ ní agbára kù sí,
    àti ìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀.
23 Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀,
    wọ́n múra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn ní ipò.
24 Àyà rẹ̀ dúró gbagidi bí òkúta,
    àní, ó le bi ìyá ọlọ.
25 Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè, àwọn alágbára bẹ̀rù;
    nítorí ìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú.
26 Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbí ọfà,
    ẹni tí ó ṣá a kò lè rán an.
27 Ó ká irin sí ibi koríko gbígbẹ
    àti idẹ si bi igi híhù.
28 Ọfà kò lè mú un sá;
    òkúta kànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àgékù koríko.
29 Ó ka ẹṣin sí bí àgékù ìdì koríko;
    ó rẹ́rìn-ín sí mímì ọ̀kọ̀.
30 Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀,
    ó sì tẹ́ ohun mímú ṣóńṣó sórí ẹrẹ̀.
31 Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò;
    ó sọ̀ agbami Òkun dàbí kólòbó ìkunra.
32 Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀;
    ènìyàn a máa ka ibú sí ewú arúgbó.
33 Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀,
    tí a dá láìní ìbẹ̀rù.
34 Ó bojú wo ohun gíga gbogbo,
    ó sì nìkan jásí ọba lórí gbogbo àwọn ọmọ ìgbéraga.”

2 Kọrinti 11

Paulu àti àwọn aposteli ẹlẹ́kọ̀ọ́ èké

11 (A)Mo rò wí pé ẹ ó faradà díẹ̀ nínú ìwà òmùgọ̀ mi ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ ni, mo fẹ́ kí ẹ gbà mí láàyè. (B)Nítorí pé èmi ń jowú lórí i yín bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run: nítorí tí mo ti fì yín fún ọkọ kan, kí èmi bà á lè mú yín wá bí wúńdíá tí ó mọ́ sọ́dọ̀ Kristi. (C)Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi. (D)Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jesu mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìhìnrere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.

(E)Nítorí mo rò pé èmi kò rẹ̀yìn nínú ohunkóhun sí àwọn àgbà Aposteli. (F)Bí mo tilẹ̀ jẹ́ òpè nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kì í ṣe nínú ìmọ̀; Ní ọ̀nàkọnà ni àwa ti fi èyí hàn dájúdájú fún yín nínú ohun gbogbo. (G)Tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìhìnrere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́. (H)Èmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbígba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín. Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni: nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedonia wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀. 10 (I)Ó jẹ́ òtítọ́, Kristi tí ń bẹ nínú mi pé kò sí ẹni tí ó lè dá mi lẹ́kun ìṣògo yìí ni gbogbo ẹkùn Akaia. 11 (J)Nítorí kín ni? Nítorí èmi kò fẹ́ràn yín ni bí? Ọlọ́run mọ̀.

12 (K)Èmi yóò tẹ̀síwájú láti máa ṣe ohun ti èmi ń ṣe láti le mú ìjákulẹ̀ bá àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti bá wa dọ́gba nínú èyí ti àwa ń ṣògo lé lórí. 13 Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn èké Aposteli àwọn ẹni ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa wọ́n dà di aposteli Kristi. 14 Kì í sì í ṣe ohun ìyanu; nítorí Satani, tìkára rẹ̀ ń pa ara rẹ̀ dàbí angẹli ìmọ́lẹ̀. 15 Nítorí náà kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá pa ara wọn dàbí àwọn ìránṣẹ́ òdodo; ìgbẹ̀yìn àwọn ẹni tí yóò rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.

Paulu ṣògo nínú ìjìyà rẹ̀

16 Mo sì tún wí pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé òmùgọ̀ ni mí; ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ẹ gbà mí bí òmùgọ̀ kí èmi lè gbé ara mi ga díẹ̀. 17 (L)Ohun tí èmi ń sọ, èmi kò sọ ọ́ nípa ti Olúwa, ṣùgbọ́n bí òmùgọ̀ nínú ìgbẹ́kẹ̀lé ìṣògo yìí. 18 Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ni ó ń ṣògo nípa ti ara, èmi ó ṣògo pẹ̀lú. 19 (M)Nítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkára yín jẹ́ ọlọ́gbọ́n. 20 Nítorí ẹ̀yin faradà á bí ẹnìkan bá sọ yín dí òǹdè, bí ẹnìkan bá jẹ́ yín run, bí ẹnìkan bá gbà lọ́wọ́ yín, bí ẹnìkan bá gbé ara rẹ̀ ga, bí ẹnìkan bá gbá yín lójú. 21 Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera!

Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú. 22 Heberu ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Israẹli ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Irú-ọmọ Abrahamu ní òun bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. 23 (N)Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkúgbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀. 24 (O)Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù. 25 (P)Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú. 26 (Q)Ní ìrìnàjò nígbàkúgbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní aginjù, nínú ewu lójú Òkun, nínú ewu láàrín àwọn èké arákùnrin. 27 (R)Nínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́ òru nígbàkúgbà, nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú àwẹ̀ nígbàkúgbà, nínú òtútù àti ìhòhò. 28 Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọn n dúró tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ. 29 (S)Ta ni ó ṣe àìlera, tí èmi kò ṣe àìlera? Tàbí a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò gbiná?

30 Bí èmi yóò bá ṣògo, èmi ó kúkú máa ṣògo nípa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti àìlera mi. 31 Ọlọ́run àti Baba Olúwa wá Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́ olùbùkún jùlọ láéláé mọ̀ pé èmi kò ṣèké. 32 (T)Ní Damasku, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ọba Areta fi ẹgbẹ́ ogun ká ìlú àwọn ará Damasku mọ́, ó ń fẹ́ láti mú mi bí arúfin: 33 Láti ojú fèrèsé nínú agbọ̀n ni a sì ti sọ̀ mí kalẹ̀ lẹ́yìn odi, tí mo sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.