Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Eksodu 26

Àgọ́ náà

26 (A)“Ṣe àgọ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá, aṣọ ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ àti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ni kí ó ṣe iṣẹ́ ọlọ́nà sí wọn. Gbogbo aṣọ títa náà ni kí ó jẹ́ ìwọ̀n kan náà: ìgbọ̀nwọ́ méjì-dínlọ́gbọ̀n ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ni fífẹ̀. Aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn, àti aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn. Ìwọ yóò ṣì ṣe ajábó aṣọ aláró sí aṣọ títa kan láti ìṣẹ́tí rẹ̀ wá níbi ìsopọ̀, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìwọ yóò ṣe ni etí ìkangun aṣọ títa kejì, ni ibi ìsopọ̀ kejì. Àádọ́ta ajábó ní ó pa lára aṣọ títa kan, àti àádọ́ta ajábó ni ó sì lò pa ní etí aṣọ títa tí ó wà ní ìsolù kejì, ajábó náà sì wà ní ọ̀kánkán ara wọn. Ó sì ṣe àádọ́ta ìkọ́ wúrà, ó sì lò ìkọ́ wọ̀n-ọn-nì láti fi aṣọ títa kan kọ́ èkejì, bẹ́ẹ̀ ó sì di odidi àgọ́ kan.

“Ìwọ ó sì ṣe aṣọ títa irun ewúrẹ́ láti fi ṣe ìbò sórí àgọ́ náà—aṣọ títa mọ́kànlá ni ìwọ ó ṣe é. Gbogbo aṣọ títa mọ́kọ̀ọ̀kànlá náà jẹ́ ìwọ̀n kan náà, ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀. Ìwọ ó so aṣọ títa márùn-ún pọ̀ mọ́ ara wọn se ọ̀kan, ó sì tún so mẹ́fà tókù mọ́ ara wọn se ọ̀kan. Ìwọ ó sì ṣẹ́ aṣọ títa kẹfà po sí méjì níwájú àgọ́ náà. 10 Ìwọ ó sì pa àádọ́ta ajábó sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kan, wọ́n sì tún pa ajábó mìíràn sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kejì. 11 Nígbà náà ṣe àádọ́ta ìkọ́ idẹ kí o sì kó wọn sínú ọ̀jábó láti fi so àgọ́ náà pọ̀ kí ó lè jẹ́ ọ̀kan. 12 Àti ìyókù tí ó kù nínú aṣọ títa àgọ́ náà, ìdajì aṣọ títa tí ó kù, yóò rọ̀ sórí ẹ̀yìn àgọ́ náà. 13 Aṣọ títa àgọ́ náà yóò jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan gígùn ní ìhà méjèèjì; Èyí tí ó kù yóò rọ̀ sórí ìhà àgọ́ náà láti fi bò ó. 14 Ìwọ ó sì ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a rì ní pupa fún àgọ́ náà, kí ó sì ṣe ìbòrí awọ seali sórí rẹ̀.

15 “Ìwọ ó sì ṣe pákó igi kasia tí ó dúró òró fún àgọ́ náà. 16 (B)Kí pákó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀. 17 Pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì ni kí ó kọjú sí ara wọn. Ṣe gbogbo àwọn pákó àgọ́ náà bí èyí. 18 Ìwọ ó sì ṣe ogún (20) pákó sí ìhà gúúsù àgọ́ náà, 19 Ìwọ ó sì ṣe ogójì (40) ìhà ìtẹ̀bọ̀ fàdákà kí ó lọ sí ìsàlẹ̀ wọn, méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kan ní ìsàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan. 20 Àti ìhà kejì, ni ìhà àríwá àgọ́ náà, ṣe ogún pákó síbẹ̀ 21 àti ogójì ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà méjì ní abẹ́ pákó kọ̀ọ̀kan. 22 kí ìwọ kí ó ṣe pákó mẹ́fà sì ìkangun, ní ìkangun ìhà ìwọ̀-oòrùn àgọ́ náà, 23 kí o sì ṣe pákó méjì fún igun ní ìhà ẹ̀yìn. 24 Ní igun méjèèjì yìí, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ méjì láti ìdí dé orí rẹ̀, a ó sì so wọ́n pọ̀ sí òrùka kan: méjèèjì yóò sì rí bákan náà. 25 Wọn ó sì jẹ́ pákó mẹ́jọ, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rìnlélógún, méjì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan.

26 “Ìwọ ó sì ṣe ọ̀pá ìdábùú igi kasia; márùn-ún fún pákó ìhà kan àgọ́ náà, 27 Márùn-ún fún àwọn ìhà kejì, àti márùn-ún fún pákó ni ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ìhà ẹ̀yìn àgọ́ náà. 28 Ọ̀pá ìdábùú àárín ni agbede-méjì gbọdọ̀ tàn láti ìkangun dé ìkangun pákó náà. 29 Ìwọ́ ó sì bo àwọn pákó náà pẹ̀lú wúrà, kí o sì ṣe òrùka wúrà kí ó lè di ọ̀pá ìdábùú mu. Kí o sì tún bo ọ̀pá ìdábùú náà pẹ̀lú wúrà.

30 “Gbé àgọ́ náà ró gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a fihàn ọ́ lórí òkè.

31 (C)“Ìwọ ó sì ṣe aṣọ ìgélé aláró, àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí í ṣe ọlọ́nà, tí òun ti àwọn kérúbù ni kí á ṣe é. 32 Ìwọ yóò sì fi rọ̀ sára òpó tí ó di igi kasia mẹ́rin ró tí a fi wúrà bò, tí ó dúró lórí ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin mẹ́rin. 33 Ṣo aṣọ títa náà sí ìsàlẹ̀ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí sí ẹ̀gbẹ́ aṣọ títa náà. Aṣọ títa náà yóò pínyà ibi mímọ́ kúrò ní ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ. 34 Fi ìtẹ́ àánú bo àpótí ẹ̀rí náà ni ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ. 35 Gbé tábìlì náà sí ìta aṣọ títa náà sí ìhà gúúsù àgọ́ náà, kí o sì gbé ọ̀pá fìtílà sí òdìkejì rẹ̀ ní ìhà àríwá.

36 “Fún ti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà, ìwọ yóò ṣe aṣọ títa aláró, elése àlùkò, ti òdódó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe. 37 Ìwọ ó sì ṣe ìkọ́ wúrà fún aṣọ títa yìí, àti òpó igi ṣittimu márùn-ún tí a sì fi wúrà bò. Kí o sì dà ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ márùn-ún fún wọn.

Johanu 5

Ìwòsàn ní etí odò adágún

Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, àjọ àwọn Júù kan kò; Jesu sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu. (A)Adágún omi kan sì wà ní Jerusalẹmu, létí bodè àgùntàn, tí a ń pè ní Betisaida ní èdè Heberu, tí ó ní ẹnu-ọ̀nà márùn-ún. Ní ẹ̀gbẹ́ odò yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn abirùn ènìyàn máa ń gbé dùbúlẹ̀ sí, àwọn afọ́jú, arọ àti aláàrùn ẹ̀gbà, wọ́n sì ń dúró de rírú omi. Nítorí angẹli a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sínú adágún náà, a sì máa rú omi rẹ̀: lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti rú omi náà tan ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ wọ inú rẹ̀ a di alára dídá kúrò nínú ààrùnkárùn tí ó ní. Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjì-dínlógójì. Bí Jesu ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?”

Abirùn náà dá a lóhùn wí pé, “Arákùnrin, èmi kò ní ẹni tí ìbá gbé mi sínú adágún, nígbà tí a bá ń rú omi náà: bí èmi bá ti ń bọ̀ wá, ẹlòmíràn a sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀ síwájú mi.”

(B)Jesu wí fún un pé, “Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.” Lọ́gán, a sì mú ọkùnrin náà láradá, ó sì gbé àkéte rẹ̀, ó sì ń rìn.

Ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ ìsinmi. 10 (C)Nítorí náà àwọn Júù wí fún ọkùnrin náà tí a mú láradá pé, “Ọjọ́ ìsinmi ni òní; kò tọ́ fún ọ láti gbé àkéte rẹ.”

11 Ó sì dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹni tí ó mú mi láradá, ni ó wí fún mi pé, ‘Gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.’ ”

12 Nígbà náà ni wọ́n bi í lérè wí pé, “Ọkùnrin wo ni ẹni tí ó wí fún ọ pé gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?”

13 Ẹni tí a mú láradá náà kò sì mọ̀ ẹni tí ó jẹ́ nítorí Jesu ti kúrò níbẹ̀, àwọn ènìyàn púpọ̀ wà níbẹ̀.

14 (D)Lẹ́yìn náà, Jesu rí i nínú tẹmpili ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!” 15 Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé, Jesu ni ẹni tí ó mú òun láradá.

Àṣẹ ọmọ Ọlọ́run

16 Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jesu, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí o ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi. 17 (E)Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.” 18 (F)Nítorí èyí ni àwọn Júù túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, kì í ṣe nítorí pé ó ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó wí pẹ̀lú pé, Baba òun ni Ọlọ́run jẹ́, ó ń mú ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba.

19 (G)Nígbà náà ni Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe: nítorí ohunkóhun tí baba bá ń ṣe, ìwọ̀nyí ni ọmọ náà sì ń ṣe pẹ̀lú. 20 (H)Nítorí Baba fẹ́ràn ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án, òun yóò sì fi iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọ̀nyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín. 21 (I)Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń jí òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di alààyè: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ń sọ àwọn tí ó fẹ́ di alààyè pẹ̀lú. 22 Nítorí pé Baba kì í ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé ọmọ lọ́wọ́: 23 (J)Kí gbogbo ènìyàn lè máa fi ọlá fún ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fi ọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ọlá fún ọmọ, kò fi ọlá fún Baba tí ó ran an.

24 (K)“Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun, òun kì yóò sì wá sí ìdájọ́; ṣùgbọ́n ó ti ré ikú kọjá bọ́ sí ìyè. 25 (L)Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn ọmọ Ọlọ́run: àwọn tí ó bá gbọ́ yóò sì yè. 26 Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ní ìyè nínú ara rẹ̀; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ó sì fi fún ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀; 27 Ó sì fún un ní àṣẹ láti máa ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú, nítorí tí òun jẹ́ ọmọ ènìyàn.

28 “Kí èyí má ṣe yà yín lẹ́nu; nítorí pé wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní ibojì yóò gbọ́ ohun rẹ̀. 29 (M)Wọn ó sì jáde wá; àwọn tí ó ṣe rere, sí àjíǹde ìyè; àwọn tí ó sì ṣe búburú sí àjíǹde ìdájọ́. 30 (N)Èmi kò le ṣe ohun kan fún ara mi: bí mo ti ń gbọ́ ni, mo ń dájọ́: òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí èmi kò wá ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.

Àwọn ẹ̀rí nípa Jesu

31 (O)“Bí èmi bá ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òtítọ́. 32 Ẹlòmíràn ni ẹni tí ń jẹ́rìí mi; èmi sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi tí ó jẹ́.

33 (P)“Ẹ̀yin ti ránṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Johanu, òun sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́. 34 (Q)Ṣùgbọ́n èmi kò gba jẹ́rìí lọ́dọ̀ ènìyàn: nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là. 35 Òun ni fìtílà tí ó ń jó, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀: ẹ̀yin sì fẹ́ fún sá à kan láti máa yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

36 (R)“Ṣùgbọ́n èmi ní ẹ̀rí tí ó pọ̀jù ti Johanu lọ: nítorí iṣẹ́ tí Baba ti fi fún mi láti ṣe parí, iṣẹ́ náà pàápàá tí èmi ń ṣe náà ń jẹ́rìí mi pé, Baba ni ó rán mi. 37 Àti Baba tìkára rẹ̀ tí ó rán mi ti jẹ́rìí mi. Ẹ̀yin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nígbà kan rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò rí ìrísí rẹ̀. 38 Ẹ kò sì ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti máa gbé inú yín: nítorí ẹni tí ó rán, òun ni ẹ̀yin kò gbàgbọ́. 39 (S)Ẹ̀yin ń wá ìwé mímọ́ nítorí ẹ̀yin rò pé nínú wọn ni ẹ̀yin ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ń jẹ́rìí mi. 40 Ẹ̀yin kò sì fẹ́ láti wá sọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin ba à lè ní ìyè.

41 “Èmi kò gba ògo lọ́dọ̀ ènìyàn. 42 Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé, ẹ̀yin fúnrayín kò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú yín. 43 (T)Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò sì gbà mí; bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, òun ni ẹ̀yin yóò gbà. 44 Ẹ̀yin ó ti ṣe lè gbàgbọ́, ẹ̀yin tí ń gba ògo lọ́dọ̀ ara yín tí kò wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan wá?

45 (U)“Ẹ má ṣe rò pé, èmi ó fi yín sùn lọ́dọ̀ Baba: ẹni tí ń fi yín sùn wà, àní Mose, ẹni tí ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé. 46 Nítorí pé ẹ̀yin ìbá gba Mose gbọ́, ẹ̀yin ìbá gbà mí gbọ́: nítorí ó kọ ìwé nípa tèmi. 47 (V)Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gba ìwé rẹ̀ gbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbà ọ̀rọ̀ mi gbọ́?”

Òwe 2

Èrè ìwà rere tí ọgbọ́n ń mú wá

Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi,
    tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,
tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n
    tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye,
àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn,
    tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye
bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà
    tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́.
Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù Olúwa,
    ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.
Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n,
    láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá
Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo,
    Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,
ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́
    Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.

Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́,
    àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere.
10 Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ
    ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ
11 Ìmòye yóò pa ọ mọ́
    òye yóò sì máa ṣọ́ ọ.

12 Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú,
    lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà,
13 ẹni tí ó kúrò ní ọ̀nà ìdúró ṣinṣin
    láti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,
14 ẹni tí ó yọ̀ nínú ṣíṣe búburú,
    tí ó ṣe inú dídùn sí àyídáyidà àwọn ènìyàn ibi,
15 ọ̀nà ẹni tí ó wọ́
    tí wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ní ọ̀nà wọn.

16 Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àjèjì obìnrin,
    àní, lọ́wọ́ obìnrin àjèjì tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ tannijẹ,
17 ẹni tí ó ti kọ ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀
    tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run rẹ̀.
18 Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikú
    ipa ọ̀nà rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn òkú.
19 Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padà
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dé ọ̀nà ìyè.

20 Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere
    kí ìwọ kí ó sì pa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́.
21 Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náà
    àwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà nínú rẹ̀.
22 Ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náà
    a ó sì fa àwọn aláìṣòótọ́ tu kúrò lórí rẹ̀.

Galatia 1

Paulu Aposteli

Paulu, aposteli tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jesu Kristi àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú. Àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi,

Sí àwọn ìjọ ní Galatia:

(A)Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa, (B)ẹni tí ó fi òun tìkára rẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa, (C)ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.

Kò sí ìhìnrere mìíràn

Ó yà mi lẹ́nu pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kristi, sí ìhìnrere mìíràn: Nítòótọ́, kò sí ìhìnrere mìíràn: bí ó tilẹ̀ ṣe pé àwọn kan wà, tí ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìhìnrere Kristi padà. (D)Ṣùgbọ́n bí ó ṣe àwa ni tàbí angẹli kan láti ọ̀run wá, ni ó bá wàásù ìhìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí a tí wàásù rẹ̀ fún yín lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé! Bí àwa ti wí ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni mo sì tún wí nísinsin yìí pé: Bí ẹnìkan bá wàásù ìhìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí ẹ̀yin tí gbà lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!

10 (E)Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ènìyàn ni èmi ń wá ojúrere rẹ̀ ní tàbí Ọlọ́run? Tàbí ènìyàn ni èmi ń fẹ́ láti wù bí? Bí èmi bá ń fẹ́ láti wu ènìyàn, èmi kò lè jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi.

Paulu ẹni tí Ọlọ́run pè

11 (F)Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ará, pé ìhìnrere tí mo tí wàásù kì í ṣe láti ipa ènìyàn. 12 N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi.

13 (G)Nítorí ẹ̀yin ti gbúròó ìgbé ayé mi nígbà àtijọ́ nínú ìsìn àwọn Júù, bí mo tí ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rékọjá ààlà, tí mo sì lépa láti bà á jẹ́: 14 (H)Mo sì ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ nínú ìsìn àwọn Júù láàrín àwọn ìran mi, mo sì ni ìtara lọ́pọ̀lọpọ̀ sì òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi. 15 (I)Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wú Ọlọ́run ẹni tí ó yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi wá, tí ó sì pé mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. 16 Láti fi ọmọ rẹ̀ hàn nínú mi, kì èmi lè máa wàásù ìhìnrere rẹ̀ láàrín àwọn aláìkọlà; èmi kò wá ìmọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni, 17 bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gòkè lọ sì Jerusalẹmu tọ àwọn tí í ṣe aposteli ṣáájú mi: ṣùgbọ́n mo lọ sí Arabia, mo sì tún padà wá sí Damasku.

18 (J)Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, nígbà náà ni mo gòkè lọ sì Jerusalẹmu láti lọ kì Peteru, mo sì gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, 19 Èmi kò ri ẹlòmíràn nínú àwọn tí ó jẹ́ aposteli, bí kò ṣe Jakọbu arákùnrin Olúwa. 20 Nǹkan tí èmi ń kọ̀wé sí yín yìí, kíyèsi i, níwájú Ọlọ́run èmi kò ṣèké.

21 Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Siria àti ti Kilikia; 22 Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kristi ni Judea: 23 Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, “Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsin yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí.” 24 Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.