Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Eksodu 15

Orin Mose àti Miriamu

15 (A)Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí Olúwa:

Èmi yóò kọrin sí Olúwa,
    nítorí òun pọ̀ ní ògo.
Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún
    ni ó ti sọ sínú Òkun.

(B)Olúwa ni agbára àti orin mi;
    òun ti di Olùgbàlà mi,
òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín,
    Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga.
Ológun ni Olúwa,
    Olúwa ni orúkọ rẹ,
Kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀
    ni ó mú wọ inú Òkun.
Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọ
    ni ó rì sínú Òkun pupa.
Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀;
    wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi Òkun bí òkúta.
“Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,
    pọ̀ ní agbára.
Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,
    fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú.

“Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi
    ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú.
Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ;
    Tí ó run wọ́n bí àgémọ́lẹ̀ ìdí koríko
Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni
    omi fi ń wọ́jọ pọ̀.
Ìṣàn omi dìde dúró bí odi;
    ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun.
Ọ̀tá ń gbéraga, ó ń wí pé:
    ‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn.
Èmi ó pín ìkógun;
    Èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn.
Èmi yóò fa idà mi yọ,
    ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’
10 Ìwọ fẹ́ èémí rẹ,
    òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀.
Wọ́n rì bí òjé
    ni àárín omi ńlá.
11 Ta ni nínú àwọn òrìṣà
    tó dàbí rẹ, Olúwa?
Ta ló dàbí rẹ:
    ní títóbi,
ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn,
    tí ń ṣe ohun ìyanu?

12 “Ìwọ na apá ọ̀tún rẹ,
    Ilẹ̀ si gbé wọn mì.
13 Nínú ìfẹ́ rẹ ti kì í sákí Ìwọ ṣe amọ̀nà
    àwọn ènìyàn náà tí Ìwọ ti rà padà.
Nínú agbára rẹ Ìwọ yóò tọ́ wọn,
    lọ sí ibi ìjókòó rẹ mímọ́.
14 Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrì
    Ìkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn Filistia.
15 Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Edomu,
    Àwọn olórí Moabu yóò wárìrì
Àwọn ènìyàn Kenaani yóò sì yọ́ dànù;
16     Ìbẹ̀rù bojo yóò ṣubú lù wọ́n nítorí
nína títóbi apá rẹ̀
    wọn yóò dúró jẹ́ẹ́ láì mira bí i òkúta
Títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi rékọjá, Olúwa,
    Títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi rékọjá.
17 Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́n
    ni orí òkè ti ìwọ jogún;
Ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, Olúwa.
    Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbé kalẹ̀, Olúwa.

18 Olúwa yóò jẹ ọba
    láé àti láéláé.”

19 Nígbà ti ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ inú Òkun, Olúwa mú kí omi Òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la Òkun kọjá. 20 Miriamu wòlíì obìnrin, arábìnrin Aaroni, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin sì jáde tẹ̀lé e pẹ̀lú ìlù òun ijó. 21 Miriamu kọrin sí wọn báyìí pé:

“Ẹ kọrin sí Olúwa
    Nítorí òun ni ológo jùlọ
Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún
    Ni òun bi ṣubú sínú Òkun.”

Omi Mara àti Elimu

22 Nígbà náà ni Mose ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn Israẹli jáde láti Òkun pupa lọ sínú ijù Ṣuri. Wọ́n lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ijù náà, wọn kò sì rí omi. 23 Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi Mara nítorí omi náà korò (Nítorí náà ni a ṣe pe ibẹ̀ ni Mara: ibi ìkorò). 24 Àwọn ènìyàn ń kùn sí Mose wí pé, “Kí ni àwa yóò mu?”

25 Mose sì ké pe Olúwa, Olúwa sì fi igi kan hàn án, ó sì sọ igi náà sínú omi, omi náà sì dùn.

Níbẹ̀ ni Olúwa ti gbé ìlànà àti òfin kalẹ̀ fún wọn, níbẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò. 26 Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí òfin Olúwa Ọlọ́run, ti ìwọ sì ṣe ohun tí ó tọ́ ni ojú rẹ̀, ti ìwọ sì tẹ̀lé ohun tí ó pàṣẹ, ti ìwọ si pa ìlànà rẹ̀ mọ́. Èmi kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn ààrùn wọ̀n-ọn-nì ti mo mú wá sórí àwọn ará Ejibiti wá sí ara rẹ, nítorí èmi ni Olúwa ti ó mú ọ láradá.”

27 Nígbà ti wọ́n dé Elimu, níbi ti kànga omi méjìlá (12) àti àádọ́rin (70) ọ̀pẹ gbé wà, wọ́n pàgọ́ síbẹ̀ ni etí omi.

Luku 18

Òwe ìforítì opó

18 (A)Ó sì pa òwe kan fún wọn láti fi yé wọn pe, ó yẹ kí a máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí a má sì ṣàárẹ̀; Wí pé, “Onídàájọ́ kan wà ní ìlú kan, tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn. Opó kan sì wà ní ìlú náà, ó sì ń tọ̀ ọ́ wá, wí pé, ‘Gbẹ̀san mi lára ọ̀tá mi!’

“Lákọ̀ọ́kọ́ kò dá a lóhùn: ṣùgbọ́n níkẹyìn ó wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Bí èmi kò tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí èmi kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn, Ṣùgbọ́n nítorí tí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, èmi ó gbẹ̀san rẹ̀, kí ó má ba à fi wíwá rẹ̀ nígbàkúgbà dá mi lágara.’ ”

(B)Olúwa sì wí pé, “Ẹ gbọ́ bí aláìṣòótọ́ onídàájọ́ ti wí! (C)Ọlọ́run kì yóò ha sì gbẹ̀san àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, tí ń fi ọ̀sán àti òru kígbe pè é, tí ó sì mú sùúrù fún wọn? Mo wí fún yín, yóò gbẹ̀san wọn kánkán! Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọmọ Ènìyàn bá dé yóò ha rí ìgbàgbọ́ ní ayé bí?”

Òwe Farisi àti agbowó òde

Ó sì pa òwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ara wọn pé, àwọn ni olódodo, tí wọ́n sì ń gan àwọn ẹlòmíràn; 10 Pé, “Àwọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sí tẹmpili láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisi, èkejì sì jẹ́ agbowó òde. 11 (D)Èyí Farisi dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, ‘Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí. 12 (E)Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì ní ọ̀sẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’

13 “Ṣùgbọ́n agbowó òde dúró lókèèrè, kò tilẹ̀ jẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ṣùgbọ́n ó lu ara rẹ̀ ní oókan àyà, ó wí pé, ‘Ọlọ́run ṣàánú fún mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀!’

14 (F)“Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga.”

Àwọn ọmọdé àti Jesu

15 (G)Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí. 16 Ṣùgbọ́n Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run. 17 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”

Ọlọ́rọ̀ alákòóso

18 (H)(I) Ìjòyè kan sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, wí pé, “Olùkọ́ rere, kín ni èmi ó ṣe tí èmi ó fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

19 Jesu wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí bí kò ṣe ẹnìkan, èyí sì ni Ọlọ́run. 20 (J)Ìwọ mọ̀ àwọn òfin: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ ”

21 Ó sì wí pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti pamọ́ láti ìgbà èwe mi wá.”

22 (K)Nígbà tí Jesu sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn tálákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra ní ọ̀run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

23 Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi: nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. 24 (L)Nígbà tí Jesu rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, ó wí pé, “Yóò ti ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run! 25 Nítorí ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run lọ.”

26 Àwọn tí ó sì gbọ́ wí pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha lè là?”

27 (M)Ó sì wí pé, “Ohun tí ó ṣòro lọ́dọ̀ ènìyàn kò ṣòro lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”

28 (N)Peteru sì wí pé, “Sá wò ó, àwa ti fi ilé wa sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!”

29 Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run, 30 Tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”

Jesu tún sọ nípa ikú rẹ̀

31 (O)Nígbà náà ni ó pe àwọn méjìlá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Sá wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, a ó sì mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, nítorí Ọmọ Ènìyàn. 32 Nítorí tí a ó fi lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́, a ó fi ṣe ẹlẹ́yà, a ó sì fi ṣe ẹ̀sín, a ó sì tutọ́ sí i lára. 33 Wọn ó sì nà án, wọn ó sì pa á: ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.”

34 Ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò sì yé wọn: ọ̀rọ̀ yìí sì pamọ́ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ ohun tí a wí.

Afọ́jú alágbe gba ìwòsàn

35 (P)Bí ó ti súnmọ́ Jeriko, afọ́jú kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà ó ń ṣagbe: 36 Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó béèrè pé, kín ni ìtumọ̀ èyí. 37 Wọ́n sì wí fún un pé, “Jesu ti Nasareti ni ó ń kọjá lọ.”

38 Ó sì kígbe pé, “Jesu, ìwọ ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”

39 Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”

40 Jesu sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í, 41 Wí pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?”

Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.”

42 (Q)Jesu sì wí fún un pé, “Ríran; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.” 43 Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run.

Jobu 33

Elihu bá Jobu sọ̀rọ̀

33 “Ǹjẹ́ nítorí náà, Jobu, èmí bẹ̀ ọ,
    gbọ́ ọ̀rọ̀ mi kí o sì fetísí ọ̀rọ̀ mi!
Kíyèsi i nísinsin yìí, èmí ya ẹnu mi,
    ahọ́n mi sì sọ̀rọ̀ ní ẹnu mi.
Ọ̀rọ̀ mi yóò sì jásí ìdúró ṣinṣin ọkàn mi,
    ètè mi yóò sì sọ ìmọ̀ mi jáde dájúdájú.
Ẹ̀mí Ọlọ́run ni ó tí dá mi,
    àti ìmísí Olódùmarè ni ó ti fún mi ní ìyè.
Bí ìwọ bá le dá mi lóhùn,
    tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ níwájú mi;
Kíyèsi i, bí ìwọ ṣe jẹ́ ti Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà;
    láti amọ̀ wá ni a sì ti dá mi pẹ̀lú.
Kíyèsi i, ẹ̀rù ńlá mi kì yóò bà ọ;
    bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi kì yóò wúwo sí ọ lára.

“Nítòótọ́ ìwọ sọ ní etí mi,
    èmí sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé,
‘Èmi mọ́, láìní ìrékọjá, aláìṣẹ̀ ní èmi;
    bẹ́ẹ̀ àìṣedéédéé kò sí ní ọwọ́ mi.
10 Kíyèsi i, Ọlọ́run ti rí àìṣedéédéé pẹ̀lú mi;
    ó kà mí sì ọ̀tá rẹ̀.
11 Ó kan ẹ̀ṣẹ̀ mi sínú àbà;
    o kíyèsi ipa ọ̀nà mi gbogbo.’

12 “Kíyèsi i, nínú èyí ìwọ ṣìnà!
    Èmi ó dá ọ lóhùn pé, Ọlọ́run tóbi jù ènìyàn lọ!
13 Nítorí kí ni ìwọ ṣe ń bá a jà, wí pé,
    òun kò ní sọ ọ̀rọ̀ kan nítorí iṣẹ́ rẹ̀?
14 Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan,
    àní, lẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n ènìyàn kò róye rẹ̀.
15 Nínú àlá, ní ojúran òru,
    nígbà tí orun èjìká bá kùn ènìyàn lọ,
    ní sísùn lórí ibùsùn,
16 Nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn,
    yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí,
17 Kí ó lè fa ènìyàn sẹ́yìn kúrò nínú ètè rẹ̀;
    Kí ó sì pa ìgbéraga mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn;
18 Ó sì fa ọkàn rẹ̀ padà kúrò nínú isà òkú,
    àti ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣègbé lọ́wọ́ idà.

19 “A sì nà án lórí ibùsùn ìrora rẹ̀;
    pẹ̀lúpẹ̀lú a fi ìjà egungun rẹ̀ ti ó dúró pẹ́ nà án,
20 bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí rẹ kọ oúnjẹ,
    ọkàn rẹ̀ sì kọ oúnjẹ dídùn.
21 Ẹran-ara rẹ̀ run, títí a kò sì fi lè rí i mọ́
    egungun rẹ̀ tí a kò tí rí sì ta jáde.
22 Àní, ọkàn rẹ̀ sì súnmọ́ isà òkú,
    ẹ̀mí rẹ̀ sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ikú.
23 Bí angẹli kan ba wà lọ́dọ̀ rẹ̀,
    ẹni tí ń ṣe alágbàwí,
    ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún láti fi ọ̀nà pípé hàn ni,
24 Nígbà náà ni ó ṣe oore-ọ̀fẹ́ fún un ó sì wí pé,
    gbà á kúrò nínú lílọ sínú isà òkú;
    èmi ti rà á padà.
25 Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọ kékeré,
    yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀;
26 Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì ṣe ojúrere rẹ̀,
    o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀,
    òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn.
27 Ó wá sọ́dọ̀ ènìyàn ó sì wí pé,
    ‘Èmi ṣẹ̀, kò sì ṣí èyí tí o tọ́, mo sì ti yí èyí tí ó tọ́ po,
    a kò sì san ẹ̀san rẹ̀ fún mi;
28 Ọlọ́run ti gba ọkàn mi kúrò nínú lílọ sínú ihò,
    ẹ̀mí mi yóò wà láti jẹ adùn ìmọ́lẹ̀ ayé.’

29 “Wò ó! Nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run
    máa ń ṣe fún ènìyàn nígbà méjì àti nígbà mẹ́ta,
30 Láti mú ọkàn rẹ padà kúrò nínú isà òkú,
    láti fi ìmọ́lẹ̀ alààyè han sí i.

31 “Jobu, kíyèsi i gidigidi kí o sì fetí sí mi;
    pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì máa sọ ọ́
32 Bí ìwọ bá sì ní ohun wí, dá mi lóhùn;
    máa sọ, nítorí pé èmi fẹ́ dá ọ láre.
33 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbọ́ tèmi;
    pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì kọ́ ọ ní ọgbọ́n.”

2 Kọrinti 3

(A)Àwa ha tún bẹ̀rẹ̀ láti máa yín ara wá bí? Tàbí àwa ha ń fẹ́ ìwé ìyìn sọ́dọ̀ yín, tàbí láti ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ẹlòmíràn tí ń ṣe? Ẹ̀yin fúnrayín ni ìwé ìyìn wa, tí a ti kọ sí yín ní ọkàn, ti gbogbo ènìyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń kà. (B)Ẹ̀yin sì ń fihàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kristi ni yín, kì í ṣe èyí tí a sì fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè, kì í ṣe nínú wàláà òkúta bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ẹran.

Irú ìgbẹ́kẹ̀lé yìí ni àwa ní nípasẹ̀ Kristi sọ́dọ̀ Ọlọ́run: Kì í ṣe pé àwa tó fún ara wa láti ṣírò ohunkóhun bí ẹni pé láti ọ̀dọ̀ àwa tìkára wa; ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tító wà; Ẹni tí ó mú wa yẹ bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe ní ti ìwé àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí, nítorí ìwé a máa pa ni, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ní di ààyè.

Ògo tó wà nínú májẹ̀mú tuntun

(C)Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mose nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ); yóò ha ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù? Nítorí pé bi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo. 10 Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ. 11 Nítorí pé bí èyí ti ń kọjá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo!

12 Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fi ìgboyà púpọ̀ sọ̀rọ̀. 13 Kì í sì í ṣe bí Mose, ẹni tí ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Israẹli má ba à lè tẹjúmọ́ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ 14 Ṣùgbọ́n ojú inú wọn fọ́; nítorí pé títí fi di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mú láéláé, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kristi ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò. 15 Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbàkúgbà ti a bá ń ka Mose, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kàn wọn. 16 Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò. 17 (D)Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbi tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira gbé wà 18 Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.