Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Eksodu 30

Pẹpẹ tùràrí

30 (A)“Ìwọ yóò sì ṣe pẹpẹ igi kasia kan; máa jó tùràrí lórí rẹ̀. Kí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé, kí ó jẹ́ ìdajì mítà ní gígùn, ìdajì mítà ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga rẹ̀—kí ìwo rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. Ìwọ yóò sì bo òkè rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀ pẹ̀lú u kìkì wúrà, ìwọ yóò sì ṣe wúrà gbà á yíká. Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì fún pẹpẹ náà níṣàlẹ̀ ìgbátí méjèèjì ní òdìkejì ìhà rẹ̀—láti gbá àwọn òpó rẹ̀ mú, láti lè máa fi gbé e. Ìwọ yóò sì ṣe òpó igi kasia, ìwọ yóò sì bọ́ wọ́n pẹ̀lú wúrà. Ìwọ yóò gbé pẹpẹ náà sí iwájú aṣọ ìkélé, èyí tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí níwájú ìtẹ́ àánú èyí tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí níbi ti èmi yóò ti máa bá ọ pàdé.

“Aaroni yóò sì máa jó tùràrí dídùn lórí pẹpẹ náà ní àràárọ̀, nígbà tí ó tún àwọn fìtílà náà ṣe. Aaroni yóò sì tún jó tùràrí nígbà tí ó bá tan fìtílà ní àṣálẹ́, bẹ́ẹ̀ ní tùràrí yóò máa jó títí láé níwájú Olúwa fún àwọn ìran tó ń bọ̀. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mú àjèjì tùràrí wá sórí pẹpẹ yìí tàbí ẹbọ sísun kankan tàbí ọrẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ da ẹbọ ohun mímu sórí i rẹ̀. 10 Aaroni yóò sì máa ṣe ètùtù sórí àwọn ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Òun yóò sì máa ṣe ètùtù ọdọọdún yìí pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ètùtù fún ìran tó ń bọ̀. Mímọ́ jùlọ ni sí Olúwa.”

Ètùtù owó

11 (B)Nígbà náà ni Olúwa wí fún Mose pé, 12 “Nígbà tí ìwọ bá ka iye àwọn ọmọ Israẹli láti mọ iye wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọdọ̀ mú ìràpadà ọkàn rẹ̀ wá fún Olúwa ní ìgbà tí o bá ka iye wọn. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-ààrùn kì yóò súnmọ́ wọn, nígbà tí o bá ń ka iye wọn. 13 Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì ṣékélì, gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gera. Ìdajì ṣékélì yìí ní ọrẹ fún Olúwa. 14 Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá sínú àwọn tí a kà láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni yóò fi ọrẹ fún Olúwa. 15 Àwọn olówó kì yóò san ju ìdajì ṣékélì lọ, àwọn tálákà kò sì gbọdọ̀ dín ní ìdajì ṣékélì nígbà tí ẹ̀yin bá mú ọrẹ wá fún Olúwa láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín. 16 Ìwọ yóò sì gba owó ètùtù náà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ yóò sì fi lélẹ̀ fún ìsìn àgọ́ àjọ. Yóò jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli níwájú Olúwa, láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.”

Agbada fún wíwẹ̀

17 Nígbà náà ni Olúwa wí fún Mose pé, 18 (C)“Ìwọ yóò sì ṣe agbada idẹ kan, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ idẹ, fún wíwẹ̀. Ìwọ yóò sì gbé e sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì pọn omi sínú rẹ̀. 19 Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn pẹ̀lú omi tí ó wà nínú rẹ̀. 20 Nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ, wọ́n yóò wẹ̀ pẹ̀lú omi nítorí kí wọ́n má ba à kú. Bákan náà, nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe ìsìn, láti mú ẹbọ ti a fi iná sun wá fún Olúwa, 21 wọn yóò sì wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, nítorí kí wọn máa ba à kú. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún Aaroni àti irú àwọn ọmọ rẹ̀ fún ìrandíran wọn.”

Òróró ìyàsímímọ́

22 (D)Olúwa sọ fún Mose pé, 23 Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ṣékélì (kílógírámù mẹ́fà) tí òjìá ṣíṣàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́tà-lé-nígba (250) ṣékélì tí kinamoni dídùn, àti kénì dídùn àádọ́tà-lé-nígba (250) ṣékélì, 24 kasia ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ṣékélì—gbogbo rẹ̀ ní ìlànà ṣékélì ibi mímọ́ àti hínì òróró olifi kan (lítà mẹ́rin). 25 Ṣe ìwọ̀nyí ní òróró mímọ́ ìkunra, tí a pò gẹ́gẹ́ bí olùṣe òórùn dídùn tì í ṣe, Yóò jẹ òróró mímọ́ ìtasórí. 26 Ìwọ yóò sì lò ó láti ya àgọ́ sí mímọ́ àti àpótí ẹ̀rí náà, 27 tábìlì àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà àti ohun èlò rẹ̀, àti pẹpẹ tùràrí, 28 pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀. 29 Ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn wọn yóò di mímọ́.

30 “Ìwọ yóò sì ta òróró sí orí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè sìn mí bí àlùfáà. 31 Ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èyí ni yóò ṣe òróró mímọ́ ìtasórí mi fún ìrandíran tó ń bọ̀. 32 Má ṣe dà á sí ara ènìyàn kí o má sì ṣe ṣe òróró kankan ni irú rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ̀yin sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́. 33 Ẹnikẹ́ni tí ó bá po irú rẹ̀, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fi sára àlejò yàtọ̀ sí àlùfáà, a ó gé e kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”

Tùràrí

34 Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú tùràrí olóòórùn dídùn sọ́dọ̀ rẹ, onika, àti galibanumu àti kìkì tùràrí dáradára, òṣùwọ̀n kan fún gbogbo rẹ, 35 ṣe tùràrí olóòórùn dídùn tí a pò, iṣẹ́ àwọn olóòórùn, tí ó ní iyọ̀, ó dára, ó sì jẹ́ mímọ́. 36 Ìwọ yóò sì lọ díẹ̀ nínú rẹ̀ kúnná, ìwọ yóò sì gbé e síwájú ẹ̀rí ní àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti pàdé yín. Yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ fún yín. 37 Ẹ má ṣe ṣe tùràrí kankan ní irú èyí fúnrayín; ẹ kà á ní mímọ́ sí Olúwa. 38 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe irú rẹ̀ láti máa gbádùn òórùn rẹ̀, òun ni a ó gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”

Johanu 9

Jesu la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú

Bí ó sì ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí rẹ̀ wá. (A)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Rabbi, ta ní ó dẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin yìí tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?”

(B)Jesu dáhùn pé, “Kì í ṣe nítorí pé ọkùnrin yìí dẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n kí a ba à lè fi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn lára rẹ̀. (C)Èmi ní láti ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ ọ̀sán: òru ń bọ̀ wá nígbà tí ẹnìkan kì yóò lè ṣe iṣẹ́. (D)Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”

(E)Nígbà tí ó ti wí bẹ́ẹ̀ tan, ó tutọ́ sílẹ̀, ó sì fi itọ́ náà ṣe amọ̀, ó sì fi amọ̀ náà ra ojú afọ́jú náà. (F)Ó sì wí fún un pé, “Lọ wẹ̀ nínú adágún Siloamu!” (Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni “rán”). Nítorí náà ó gba ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó wẹ̀, ó sì dé, ó ń ríran.

Ǹjẹ́ àwọn aládùúgbò àti àwọn tí ó rí i nígbà àtijọ́ pé alágbe ni ó jẹ́, wí pé, “Ẹni tí ó ti ń jókòó ṣagbe kọ́ yìí?” Àwọn kan wí pé òun ni.

Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ó jọ ọ́ ni.”

Ṣùgbọ́n òun wí pé, “Èmi ni.”

10 Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Bá wo ni ojú rẹ ṣe là?”

11 Ó dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jesu ni ó ṣe amọ̀, ó sì fi kun ojú mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Lọ sí adágún Siloamu, kí o sì wẹ̀,’ èmi sì lọ, mo wẹ̀, mo sì ríran.”

12 Wọ́n sì wí fún un pé, “Òun náà ha dà?”

Ó sì wí pé, “Èmi kò mọ̀.”

Àwọn Farisi wádìí ìwòsàn

13 Wọ́n mú ẹni tí ojú rẹ̀ ti fọ́ rí wá sọ́dọ̀ àwọn Farisi. 14 Ọjọ́ ìsinmi ni ọjọ́ náà nígbà tí Jesu ṣe amọ̀, tí ó sì là á lójú. 15 Nítorí náà àwọn Farisi pẹ̀lú tún bi í léèrè, bí ó ti ṣe ríran. Ọkùnrin náà fèsì, “Ó fi amọ̀ lé ojú mi, mo sì wẹ̀, báyìí mo sì ríran.”

16 (G)Nítorí náà àwọn kan nínú àwọn Farisi wí pé, “Ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, nítorí tí kò pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.”

Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Ọkùnrin tí í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò ha ti ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ ààmì wọ̀nyí?” Ìyapa sì wà láàrín wọn.

17 Nítorí náà, wọ́n sì tún wí fún afọ́jú náà pé, “Kí ni ìwọ ní wí nípa rẹ̀, nítorí tí ó là ọ́ lójú?”

Ó sì wí pé, “Wòlíì ní í ṣe.”

18 Nítorí náà àwọn Júù kò gbàgbọ́ nípa rẹ̀ pé ojú rẹ̀ ti fọ́ rí, àti pé ó sì tún ríran, títí wọ́n fi pe àwọn òbí ẹni tí a ti là lójú. 19 Wọ́n sì bi wọ́n léèrè wí pé, “Ǹjẹ́ èyí ni ọmọ yín, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, a bí ní afọ́jú? Báwo ni ó ṣe ríran nísinsin yìí?”

20 Àwọn òbí rẹ̀ dá wọn lóhùn wí pé, “Àwa mọ̀ pé ọmọ wa ni èyí, àti pé a bí i ní afọ́jú: 21 Ṣùgbọ́n bí ó tí ṣe ń ríran nísinsin yìí àwa kò mọ̀; ẹni tí ó là á lójú, àwa kò mọ̀: ẹni tí ó ti dàgbà ni òun; ẹ bi í léèrè: yóò wí fúnrarẹ̀.” 22 (H)Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn òbí rẹ̀ sọ, nítorí tí wọ́n bẹ̀rù àwọn Júù: nítorí àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan pé bí ẹnìkan bá jẹ́wọ́ pé Kristi ni, wọn ó yọ ọ́ kúrò nínú Sinagọgu. 23 Nítorí èyí ni àwọn òbí rẹ̀ fi wí pé, “Ẹni tí ó dàgbà ni òun, ẹ bi í léèrè.”

24 Nítorí náà, wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ògo fún Ọlọ́run: àwa mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkùnrin yìí jẹ́.”

25 Nítorí náà, ó dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni, èmi kò mọ̀: Ohun kan ni mo mọ̀, pé mo tí fọ́jú rí, nísinsin yìí mo ríran.”

26 Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé, “Kí ni ó ṣe ọ́? Báwo ni ó ṣe là ọ́ lójú.”

27 Ó dá wọn lóhùn wí pé, “Èmi ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọ́: nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe ń fẹ́ tún gbọ́? Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ ṣe ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bí?”

28 (I)Wọ́n sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ni ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: ṣùgbọ́n ọmọ-ẹ̀yìn Mose ni àwa. 29 Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mose sọ̀rọ̀: ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti eléyìí, àwa kò mọ ibi tí ó ti wá.”

30 Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ohun ìyanu sá à ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n òun sá à ti là mí lójú. 31 Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣe olùfọkànsìn sí Ọlọ́run, tí ó bá sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, Òun ni ó ń gbọ́ tirẹ̀. 32 Láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, a kò ì tí ì gbọ́ pé ẹnìkan la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú rí. 33 Ìbá ṣe pé ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kì bá tí lè ṣe ohunkóhun.”

34 Sí èyí, wọ́n fèsì pé: “Láti ìbí ni o tì jíngírí nínú ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ ha fẹ́ kọ́ wa bí?” Wọ́n sì tì í sóde.

Ìfọ́jú ẹ̀mí

35 Jesu gbọ́ pé, wọ́n ti tì í sóde; nígbà tí ó sì rí i, ó wí pe, “Ìwọ gba Ọmọ Ọlọ́run, gbọ́ bí?”

36 Òun sì dáhùn wí pé, “Ta ni, Olúwa, kí èmi lè gbà á gbọ́?”

37 Jesu wí fún un pé, “Ìwọ ti rí i, Òun náà sì ni ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí.”

38 (J)Ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́,” ó sì wólẹ̀ fún un.

39 (K)Jesu sì wí pé, “Nítorí ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran; àti kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.”

40 Nínú àwọn Farisi tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú fọ́jú bí?”

41 (L)Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fọ́jú, ẹ̀yin kì bá tí lẹ́sẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa ríran,’ nítorí náà ẹ̀ṣẹ̀ yín wà síbẹ̀.

Òwe 6

Ìkìlọ̀ láti ṣọ́ra fún ìwà òmùgọ̀

Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ,
    bí ìwọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì ènìyàn,
bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ,
    tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté,
Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹ
    níwọ̀n bí o ti kó ṣọ́wọ́ aládùúgbò rẹ:
lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀;
    bẹ aládùúgbò rẹ dáradára
Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́,
    tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá.
Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo èsúró kúrò lọ́wọ́ ọdẹ,
    bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ.

Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ
    kíyèsi ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n!
Kò ní olùdarí,
    kò sí alábojútó tàbí ọba,
síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjò
    yóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè.

Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ?
    Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ?
10 Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,
    ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀
11 Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣà
    àti àìní bí adigunjalè.

12 Ènìyànkénìyàn àti ènìyàn búburú,
    tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri,
13 tí ó ń ṣẹ́jú pàkòpàkò,
    ó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀
    ó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe,
14 tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀
    ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀.
15 Nítorí náà ìdààmú yóò dé bá a ní ìṣẹ́jú akàn;
    yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.

16 Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra,

ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i:

17 Ojú ìgbéraga,

Ahọ́n tó ń parọ́

ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,

18 ọkàn tí ń pète ohun búburú,

ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà,

19 Ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu

àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan.

Ìkìlọ̀ nítorí àgbèrè

20 Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́
    má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.
21 Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláé
    so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ
22 Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ;
    nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùṣọ́ rẹ;
    nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀.
23 Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà,
    ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀,
    àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí
    ni ọ̀nà sí ìyè.
24 Yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin búburú,
    kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn obìnrin àjèjì.

25 Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ si nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ
    tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra.

26 Nítorí pé nípasẹ̀ àgbèrè obìnrin ni ènìyàn fi ń di oníṣù-àkàrà kan,
    ṣùgbọ́n àyà ènìyàn a máa wá ìyè rẹ̀ dáradára.
27 Ǹjẹ́ ọkùnrin ha le è gbé iná lé orí itan
    kí aṣọ rẹ̀ má sì jóná?
28 Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná?
    Kí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì má jóná?
29 Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya;
    kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láìjìyà.

30 Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè
    nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á.
31 Síbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje
    bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà.
32 Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbèrè kò nírònú;
    ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni
33 Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀,
    ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé.

34 Nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè,
    kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san.
35 Kò nígbà nǹkan kan bí ohun ìtánràn;
    yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó.

Galatia 5

Òmìnira nínú Jesu

Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin nínú òmìnira náà èyí tí Kristi fi sọ wá di òmìnira, kí ẹ má sì ṣe tún fi ọrùn bọ̀ àjàgà ẹrú mọ́.

Kíyèsi i, èmi Paulu ni ó wí fún yín pé, bí a bá kọ yín nílà abẹ́, Kristi kì yóò lérè fún yín ní ohunkóhun. Mo sì tún sọ fún olúkúlùkù ènìyàn tí a kọ ní ilà pé, ó di ajigbèsè láti pa gbogbo òfin mọ́. A ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ kí a dá yín láre nípa òfin; pé ẹ ti ṣubú kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́. Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo. (A)Nítorí nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.

Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára. Ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ràn sí òtítọ́? Ìyípadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó pè yín wá. (B)Ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìyẹ̀fun wú. 10 Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé sí yín nínú Olúwa pé, ẹ̀yin kì yóò ní èrò ohun mìíràn; ṣùgbọ́n ẹni tí ń yọ yín lẹ́nu yóò ru ìdájọ́ tirẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́. 11 Ṣùgbọ́n, ará, bí èmi bá ń wàásù ìkọlà síbẹ̀, kín ni ìdí tí a fi ń ṣe inúnibíni sí mi síbẹ̀? Ǹjẹ́ ìkọ̀sẹ̀ àgbélébùú ti kúrò. 12 Èmi ìbá fẹ́ kí àwọn tí ń yọ yín lẹ́nu tilẹ̀ gé ẹ̀yà ara wọn kan kúrò.

13 Nítorí a ti pè yín sí òmìnira, ará kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín bí àǹfààní sípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa fi ìfẹ́ sin ọmọnìkejì yín. 14 (C)Nítorí pé a kó gbogbo òfin já nínú èyí pé, “Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” 15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń bu ara yín ṣán, tí ẹ sì ń jẹ ara yín run, ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe pa ara yín run.

Ìyè nípa ti ẹ̀mí

16 Ǹjẹ́ mo ní, Ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ṣẹ. 17 (D)Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara: àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má ba à lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́. 18 Ṣùgbọ́n bí a bá ń ti ọwọ́ Ẹ̀mí ṣamọ̀nà yín, ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin.

19 (E)Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tí í ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà, 20 Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórìíra, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọtaraẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́ òdì. 21 Àrankàn, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde òru, àti irú ìwọ̀nyí; àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.

22 Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, 23 ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu: òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí, 24 Àwọn tí í ṣe ti Kristi Jesu ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. 25 Bí àwa bá wà láààyè sípa ti Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a sì máa rìn nípa ti Ẹ̀mí. 26 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa ṣe ògo asán, kí a má mú ọmọnìkejì wa bínú, kí a má ṣe ìlara ọmọnìkejì wa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.