Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 56-58

Fún adarí orin. Ti ohùn “Àdàbà lórí Óákù òkè réré.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí àwọn ará Filistini ka mọ́ ní Gati.

56 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbónára lépa mi;
    ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjà
    sí mi, wọn ń ni mi lára.
Àwọn ọ̀tá mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́,
    àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.

Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí,
    èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ,
    nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí
kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?

Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́,
    wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.
Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba
    Wọ́n ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi
wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.
San ẹ̀san iṣẹ́ búburú wọ́n fún wọn;
    Ní ìbínú rẹ, Ọlọ́run, wọ́ àwọn ènìyàn náà bọ́ sílẹ̀.

Kọ ẹkún mi sílẹ̀;
    kó omijé mi sí ìgò rẹ,
wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?
Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà
    nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́
    nípa èyí ni mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi.

10 Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀
    nínú Olúwa, ẹni tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀:
11 Nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi:
    ẹ̀rù kì yóò bà mí.
Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?

12 Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ rẹ Ọlọ́run:
    èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ.
13 Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikú
    àti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú,
kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́run
    ní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.

Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta.

57 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,
    nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.
Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ
    títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.

Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
    sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi.
Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá,
    yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì
tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi.
    Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde.

Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún;
    mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú,
àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà
    ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.

Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ,
    kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.

Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi:
    a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú,
wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi:
ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.

(A)Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run;
    ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn.
Jí, ìwọ ọkàn mi!
    Jí, ohun orin èlò àti dùùrù!
    Èmi tìkára mi, yóò sì jí ní kùtùkùtù.

Èmi ó máa yìn ọ́, Olúwa, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
    èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn.
10 Nítorí títóbi ní ìfẹ́ rẹ, tí ó dé ọ̀run;
    òtítọ́ rẹ tàn dé àwọsánmọ̀.

11 Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ;
    kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.

Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu.

58 Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòótọ́
    ẹ̀yin ìjọ ènìyàn?
Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́
    ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?
Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìṣòdodo,
    ọwọ́ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.

Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà,
    lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké.
Oró wọn dàbí oró ejò,
    wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,
tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú,
    bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.

Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run;
    ní ẹnu wọn,
ká ọ̀gàn àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.
Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń sàn lọ;
    nígbà tí ó bá fa ọfà rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.
Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé
    bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn.

Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún;
    bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.
10 Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn,
    nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.
11 Àwọn ènìyàn yóò wí pé,
    “Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo;
    lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”

Saamu 64-65

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

64 Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi
    pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá.

Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú
    kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,
    wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.
Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀:
    wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.

Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú,
    wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀
    wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”
Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé,
    “A wa ti parí èrò tí a gbà tán”
    lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.

Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà;
    wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.
Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n,
    Gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.
Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù
    wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run
    wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.

10 Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú Olúwa
    yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀.
    Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín.

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Orin.

65 Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ní Sioni;
    sí ọ ni a ó mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.
Ìwọ tí ó ń gbọ́ àdúrà,
    gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!
    Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.
Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàn
    tí o mú wa láti máa gbé àgọ́ rẹ!
A tẹ́ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé rẹ,
    ti tẹmpili mímọ́ rẹ.

Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohun ìyanu ti òdodo,
    Ọlọ́run olùgbàlà wa,
ẹni tí ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo òpin ayé
    àti àwọn tí ó jìnnà nínú Òkun,
Ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára rẹ,
    tí odi ara rẹ ní àmùrè agbára
Ẹni tí ó mú rírú omi Òkun dákẹ́
    ríru ariwo omi wọn,
    àti ìdágìrì àwọn ènìyàn
Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù,
    nítorí ààmì rẹ wọ̀n-ọn-nì;
    ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ́ yọ̀,
    ìwọ pè fún orin ayọ̀.

Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;
    ìwọ mú un ọ̀rọ̀ púpọ̀.
Odò Ọlọ́run kún fún omi
    láti pèsè ọkà fún àwọn ènìyàn,
nítorí ibẹ̀ ni ìwọ ti yàn án.
10 Ìwọ fi bomirin sí aporo rẹ̀
    ìwọ tẹ́ ògúlùtu rẹ̀;
ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ rẹ̀ rọ̀,
    o sì bùkún ọ̀gbìn rẹ̀.
11 Ìwọ fi oore rẹ dé ọdún ní adé,
    ọ̀rá ń kán ní ipa ọ̀nà rẹ
12 Pápá tútù ní aginjù ń kan
    àwọn òkè kéékèèkéé fi ayọ̀ di ara wọn ní àmùrè.
13 Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà ní aṣọ;
    Àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀,
    wọ́n hó fún ayọ̀, wọ́n ń kọrin pẹ̀lú.

Jobu 40

Jobu rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀

40 Olúwa dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé:

“Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́?
    Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!”

Nígbà náà ni Jobu dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé,

“Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà?
    Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi.
Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́;
    lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.”

Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé:

“Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin,
    èmi ó bi ọ léèrè,
    kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.

“Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán?
    Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo
Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run
    tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?
10 Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́,
    tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ.
11 Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde;
    kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.
12 Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀
    kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
13 Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀,
    kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú
14 Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé,
    ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.

15 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti,
    tí mo dá pẹ̀lú rẹ,
    òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.
16 Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
    àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.
17 Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari;
    Iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀.
18 Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ;
    Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.
19 Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run;
    síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.
20 Nítòótọ́ òkè ńláńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá,
    níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀.
21 Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì,
    lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀.
22 Igi lótusì ṣíji wọn bò o;
    igi arọrọ odò yí i káàkiri.
23 Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ;
    ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.
24 Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀,
    tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?

Ìṣe àwọn Aposteli 15:36-16:5

Ìjà láàrín Paulu àti Barnaba

36 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòókan, Paulu sì sọ fún Barnaba pé, “Jẹ́ kí a tún padà lọ bẹ àwọn arákùnrin wa wò, bí wọn ti ń ṣe sí ni ìlú gbogbo tí àwa ti wàásù ọ̀rọ̀ Olúwa.” 37 Barnaba sì pinnu rẹ̀ láti mú Johanu lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku. 38 Ṣùgbọ́n Paulu rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni pamfilia, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà. 39 Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì: Barnaba sì mu Marku ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Saipurọsi. 40 Ṣùgbọ́n Paulu yan Sila, ó sì lọ, bí a ti fi lé oore-ọ̀fẹ́ Olúwa lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin. 41 Ó sì la Siria àti Kilikia lọ, ó ń mú ìjọ ní ọkàn le.

Timotiu darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila

16 Ó sì wá sí Dabe àti Lysra: sí kíyèsi i, ọmọ-ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀, tí a ń pè ní Timotiu, ọmọ obìnrin kan tí í ṣe Júù, tí ó gbàgbọ́; ṣùgbọ́n Giriki ní baba rẹ̀. Ẹni tí a ròhìn rẹ̀ ní rere lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin tí ó wà ní Lysra àti Ikoniomu. Òun ni Paulu fẹ́ kí ó bá òun lọ; ó sì mú un, ó sì kọ ọ́ ní ilà, nítorí àwọn Júù tí ó wà ní agbègbè wọ̀nyí: nítorí gbogbo wọn mọ̀ pé, Giriki ni baba rẹ̀. Bí wọn sì ti ń la àwọn ìlú lọ, wọ́n ń fi àwọn àṣẹ, tí a tí pinnu láti ọ̀dọ̀ àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tí ó wà ní Jerusalẹmu, lé wọn lọ́wọ́ láti máa pa wọ́n mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ sì fẹsẹ̀múlẹ̀ ní ìgbàgbọ́, wọn sí ń pọ̀ sí i ní iye lójoojúmọ́.

Johanu 11:55-12:8

55 (A)Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé: ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ìgbèríko sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu ṣáájú ìrékọjá, láti ya ara wọn sí mímọ́. 56 (B)Nígbà náà ni wọ́n ń wá Jesu, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ̀, bí wọ́n ti dúró ní tẹmpili, wí pé, “kín ni ẹyin ti rò ó sí pé kì yóò wá sí àjọ?” 57 Ǹjẹ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi ti pàṣẹ pé bí ẹnìkan bá mọ ibi tí ó gbé wà, kí ó fi í hàn, kí wọn ba à lè mú un.

A fi ààmì òróró yàn Jesu ni Betani

12 (C)Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú. Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀: Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́: ṣùgbọ́n Lasaru Jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀. Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òṣùwọ̀n lítà kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà.

(D)Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, “Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?” (E)Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́.

(F)Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi. Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin sá à ní tálákà pẹ̀lú yín; ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.