Book of Common Prayer
Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.
38 Olúwa, Má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.
2 Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin,
ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.
3 Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ;
kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.
4 Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀;
wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.
5 Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́
nítorí òmùgọ̀ mi.
6 Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi
èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.
7 Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni
kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi,
8 Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ;
mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.
9 Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ;
ìmí ẹ̀dùn mi kò sápamọ́ fún ọ.
10 Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀;
bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.
11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi,
àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.
12 Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi;
àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun,
wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.
13 Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;
àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.
14 Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀,
àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.
15 Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè;
ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.
16 Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;
nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”
17 Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú,
ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.
18 Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;
àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
19 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.
20 Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi
àwọn ni ọ̀tá mi
nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn.
21 Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa!
Ọlọ́run mi, Má ṣe jìnnà sí mi.
22 Yára láti ràn mí lọ́wọ́,
Olúwa, Olùgbàlà mi.
Àdúrà láti ní òye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
25 Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀;
ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
26 Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn;
kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
27 Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ:
nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
28 Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;
fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
29 Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn
fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
30 Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́
èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
31 Èmi yára di òfin rẹ mú. Olúwa
má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
32 Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ,
nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.
Ìlérí Ọlọ́run fún aláforítì
33 Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ;
nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
34 Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
35 Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí,
nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
36 Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ
kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
37 Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:
pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
38 Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí òfin rẹ dára.
39 Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù
nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
40 Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ!
Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.
Ìgbàlà láti inú òfin Ọlọ́run
41 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa,
ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ;
42 Nígbà náà ni èmi yóò dá
ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,
nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi
nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ
44 Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo
láé àti láéláé.
45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,
nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
46 Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba
ojú kì yóò sì tì mí,
47 Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ
nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
48 Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,
èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.
Ìdáhùn Jobu
12 Jobu sì dáhùn, ó sì wí pé:
Jobu tẹ̀síwájú nínú àròyé rẹ̀
14 “Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin,
ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.
2 Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀;
ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.
3 Ìwọ sì ń ṣíjú rẹ wò irú èyí ni?
Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?
4 Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá?
Kò sí ẹnìkan!
5 Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀,
iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
Ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.
6 Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè
sinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.
7 “Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá
ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ,
àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ.
8 Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,
tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀;
9 Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi,
yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.
10 Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù;
Àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́.
Àgékúrú ọjọ́ ọmọ ènìyàn
11 “Bí omi ti í tán nínú ipa odò,
àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ,
12 bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;
títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,
wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.
13 “Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,
kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,
títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,
ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!
14 Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?
Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀
fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.
15 Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;
ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ń kaye ìṣísẹ̀ mi;
ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?
17 A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,
ìwọ sì rán àìṣedéédéé mi pọ̀.
18 “Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán,
a sì ṣí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.
19 Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì
mú omi sàn bo ohun tí ó hù jáde lórí ilẹ̀,
ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.
20 Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ!
Ìwọ pa awọ ojú rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.
21 Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀;
wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsi i lára wọn.
22 Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí
ìrora. Ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”
18 Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìrúkèrúdò díẹ̀ kọ́ ni ó wà láàrín àwọn ọmọ-ogun nípa ohun tí ó dé bá Peteru. 19 Nígbà tí Herodu sì wá a kiri, tí kò sì rí i, ó wádìí àwọn ẹ̀ṣọ́, ó pàṣẹ pé, kí a pa wọ́n.
Ikú Herodu
Herodu sì sọ̀kalẹ̀ láti Judea lọ sí Kesarea, ó sì wà níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 20 Herodu sí ń bínú gidigidi sí àwọn ará Tire àti Sidoni; ṣùgbọ́n wọ́n fi ìmọ̀ ṣọ̀kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọn sì ti tu Bilasitu ìwẹ̀fà ọba lójú, wọn ń bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí pé ìlú ọba náà ni ìlú tí wọ́n ti ń gba oúnjẹ.
21 Ni ọjọ́ àfiyèsí kan, Herodu sì wà nínú aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ni orí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ń bá àwọn àjọ ènìyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba. 22 Àwọn ènìyàn sì hó wí pé, “Ohùn ọlọ́run ni èyí, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” 23 Lójúkan náà, nítorí ti Herodu kò fi ògo fún Ọlọ́run, angẹli Olúwa lù ú, ó sì kú, ìdin sì jẹ ẹ́.
24 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbilẹ̀, ó sì bí sí i.
25 Barnaba àti Saulu sì padà wá láti Jerusalẹmu, nígbà ti wọ́n sì parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, wọn sì mú Johanu ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku wá pẹ̀lú wọn.
47 Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.”
Jesu béèrè nípa ohun tí n ṣe ti ara rẹ̀
48 (A)Àwọn Júù dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò wí nítòótọ́ pé, ará Samaria ni ìwọ jẹ́, àti pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù?”
49 Jesu sì dáhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù, ṣùgbọ́n èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ẹ̀yin kò sì bu ọlá fún mi. 50 Èmi kò wá ògo ara mi: Ẹnìkan ń bẹ tí ó ń wá a tí yóò sì ṣe ìdájọ́. 51 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò rí ikú láéláé.”
52 Àwọn Júù wí fún un pé, “Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù. Abrahamu kú, àti àwọn wòlíì; ìwọ sì wí pé, ‘Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò láéláé’ 53 (B)Ìwọ ha pọ̀ ju Abrahamu Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú: ta ni ìwọ ń fi ara rẹ pè?”
54 Jesu dáhùn wí pé, “Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ nǹkan; Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe: 55 Ẹ kò sì mọ̀ ọ́n: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: bí mo bá sì wí pé, èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò di èké gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, mo sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. 56 (C)Abrahamu baba yín yọ̀ láti rí ọjọ́ mi: ó sì rí i, ó sì yọ̀.”
57 (D)Nítorí náà, àwọn Júù wí fún un pé, “Ọdún rẹ kò ì tó àádọ́ta, ìwọ sì ti rí Abrahamu?”
58 (E)Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kí Abrahamu tó wà, èmi ti wa.” 59 (F)Nítorí náà wọ́n gbé òkúta láti sọ lù ú: ṣùgbọ́n Jesu fi ara rẹ̀ pamọ́, ó sì jáde kúrò ní tẹmpili.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.