Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 50

Saamu ti Asafu

50 Olúwa, Ọlọ́run alágbára
    sọ̀rọ̀ kí o sì pe ayé jọ
    láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀.
Láti Sioni wá, pípé ni ẹwà,
    Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀
Ọlọ́run ń bọ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́,
iná yóò máa jó níwájú rẹ̀,
    àti ní àyíká rẹ̀ ni ẹ̀fúùfù líle yóò ti máa jà ká.
Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé,
    kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn rẹ̀.
“Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi
    àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.”
Àwọn ọ̀run yóò sì sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀,
    Nítorí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni onídàájọ́.

“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ:
    èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.
Èmi kí yóò bá ọ wí
    nítorí àwọn ìrúbọ rẹ,
tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi
    ní ìgbà gbogbo.
Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un,
    tàbí kí o mú òbúkọ láti
inú agbo ẹran rẹ̀
10 Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi
    àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.
11 Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá
    àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi
12 Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,
    nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo
tí ó wa ní inú rẹ̀.
13 Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí
    mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?

14 “Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,
    kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo.
15 Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú,
    èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”

16 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú:

“Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ,
    tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?
17 Ìwọ kórìíra àṣẹ mi,
    ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.
18 Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́ ọn,
    ìwọ sì da ara rẹ dé àwọn alágbèrè.
19 Ìwọ lo ẹnu rẹ fún aburú,
    ìwọ sì ń fi ahọ́n rẹ pète ẹ̀tàn.
20 Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí arákùnrin rẹ,
    ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá rẹ jẹ́.
21 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́;
    ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ,
ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí,
    èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara rẹ.

22 “Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
    Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, láìsí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀.
23 Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe,
    kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”

Saamu 59-60

Fún adarí orin. Tí ohùn orin “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí Saulu rán àwọn olùṣọ́ sí ilé Dafidi kí òun bá le rí i pa.

59 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run;
    dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi.
Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburú
    kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀.

Wò ó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí!
    Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi
Kì í ṣe nítorí ìrékọjá mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, Olúwa.
Èmi kò ṣe àìṣedéédéé kan, síbẹ̀ wọ́n sáré wọ́n ṣetán láti kọlù mí.
    Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi.
Olúwa Ọlọ́run Alágbára,
    Ọlọ́run Israẹli,
dìde fún ara rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀-èdè wí;
    má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. Sela.

Wọ́n padà ní àṣálẹ́,
    wọ́n ń gbó bí àwọn ajá,
    wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.
Kíyèsi ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu:
    wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn,
    wọ́n sì wí pé, “Ta ni ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?”
Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín
    Ìwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.

Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ;
    nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,
10     Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi.

Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi.
    Yóò sì jẹ́ kí n yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi.
11 Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa,
    kí àwọn ènìyàn mi má ba à gbàgbé.
Nínú agbára rẹ, jẹ́ kí wọn máa rìn kiri,
    kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
12 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn,
    ní ọ̀rọ̀ ètè wọn,
    kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn.
Nítorí èébú àti èké tí wọn ń sọ,
13     Pa wọ́n run nínú ìbínú,
    run wọ́n di ìgbà tí wọn kò ní sí mọ́.
Nígbà náà ni yóò di mí mọ̀ dé òpin ayé
    pé Ọlọ́run jẹ ọba lórí Jakọbu. Sela.

14 Wọ́n padà ní àṣálẹ́,
    wọn ń gbó bí àwọn ajá
    wọ́n ń rin ìlú náà káàkiri.
15 Wọ́n ń rin kiri fún oúnjẹ
    wọ́n sì ń yán nígbà tí wọn kò yó.
16 Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára rẹ,
    n ó kọrin ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀;
nítorí ìwọ ni ààbò mi,
    ibi ìsádi mi ní ìgbà ìpọ́njú.

17 Ìwọ agbára mi, èmi ó kọrin ìyìn sí ọ;
    ìwọ, Ọlọ́run, ààbò mi, Ọlọ́run ìfẹ́ mi.

Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Miktamu ti Dafidi. Fún ìkọ́ni. Nígbà tí ó bá Aramu-Naharaimu àti Siria-Soba jà, àti nígbà tí Joabu yípadà tí ó sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlá àwọn ará Edomu ní Àfonífojì Iyọ̀.

60 Ìwọ ti kọ̀ wá sílẹ̀,
    Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká,
ìwọ ti bínú nísinsin yìí, tún ara rẹ yípadà sí wa.
Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ;
    mú fífọ́ rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mì.
Ìwọ ti fi ìgbà ewu han àwọn ènìyàn rẹ;
    Ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wá gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
Àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ní ìwọ fi ọ̀págun fún
    kí a lè fihàn nítorí òtítọ́. Sela.

(A)Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́,
    kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.
Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀:
    “Ní ayọ̀, èmi ó pọ Ṣekemu jáde
    èmi ó sì wọ́n Àfonífojì Sukkoti.
Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;
    Efraimu ni àṣíborí mi,
    Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.
Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
    lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí;
    lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”

Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì?
    Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?
10 Kì í ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀
    tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?
11 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá,
    nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.
12 Nípa Ọlọ́run ni a óò ní ìṣẹ́gun,
    yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Saamu 93

93 Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;
    ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ
    àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.
Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;
    kò sì le è yí.
Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;
    ìwọ wà títí ayérayé.

A ti gbé Òkun sókè, Olúwa,
    Òkun ti gbé ohùn wọn sókè;
    Òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.
Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,
    ó ni ògo ju Òkun rírú lọ
    Olúwa ga ní ògo.

Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;
    ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́
    fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.

Saamu 96

96 (A)Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa:
    Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.
Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀
    ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́
Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
    àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.

Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;
    òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ
Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè
    ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run
Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀
    agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn
    Ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa
Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;
    ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀
Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;
    ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.
10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba”
    a fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;
    ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.

11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo
    jẹ́ kí pápá Òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun
gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.
12     Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀
àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀:
nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀
13     Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,
    nítorí tí ó ń bọ̀ wá,
Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé
yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé
    àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.

Jobu 29:1

Jobu rántí ìbùkún rẹ̀ àtẹ̀yìnwá

29 Pẹ̀lúpẹ̀lú, Jobu sì tún tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé:

Jobu 31:1-23

Àwíjàre Jobu

31 “Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú,
    èmi yó ha ṣe tẹjúmọ́ wúńdíá?
Nítorí pé kí ni ìpín Ọlọ́run láti ọ̀run wá?
    Tàbí kí ni ogún Olódùmarè láti òkè ọ̀run wá.
Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú ni ìparun wà fún,
    àti àjàkálẹ̀-ààrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?
Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi,
    òun kò ha sì ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi?

“Bí ó bá ṣe pé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn,
    tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn;
(Jẹ́ kí Ọlọ́run wọ́n mí nínú ìwọ̀n òdodo,
    kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)
Bí ẹsẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà,
    tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi,
    tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀ mọ́ mi ní ọwọ́,
Ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ,
    àní kí a fa irú-ọmọ mi tu.

“Bí àyà mi bá di fífà sí ipasẹ̀ obìnrin kan,
    tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu-ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,
10 Kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn,
    kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.
11 Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú
    àní, ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀
12 Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun,
    tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu.

13 “Tí mo bá sì ṣe àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mi
    tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí,
    nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà;
14 Kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde?
    Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá?
15 Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a?
    Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa?

16 “Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà,
    tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì,
17 Tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ,
    tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀;
18 nítorí pé láti ìgbà èwe mi wá ni a ti tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú mi bí ẹni pé baba,
    èmi sì ń ṣe ìtọ́jú opó láti inú ìyá mi wá:
19 Bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ,
    tàbí tálákà kan láìní ìbora;
20 Bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi,
    tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípasẹ̀ irun àgùntàn mi;
21 Bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba,
    nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè,
22 Ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ihò èjìká rẹ̀,
    kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá.
23 Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù ńlá fún mi,
    àti nítorí ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró.

Ìṣe àwọn Aposteli 15:1-11

Àjọ ìgbìmọ̀ ní Jerusalẹmu

15 (A)Àwọn ọkùnrin kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, wọ́n sì kọ́ àwọn arákùnrin pé, “Bí kò ṣe pé a bá kọ yín ni ilà bí ìṣe Mose, ẹ̀yin kí yóò lè là.” Nígbà tí Paulu àti Barnaba ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú ara wọn, wọ́n yan Paulu àti Barnaba àti àwọn mìíràn nínú aposteli kí wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí. Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Fonisia àti Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà: wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin. Nígbà tí wọn sì dé Jerusalẹmu, ìjọ àti àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.

Ṣùgbọ́n àwọn kan nínú ẹ̀yà àwọn Farisi tí wọ́n gbàgbọ́ dìde, wọ́n ń wí pé, “A ní láti kọ wọ́n ní ilà, àti láti pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa pa òfin Mose mọ́.”

Àwọn aposteli àti àwọn alàgbà péjọ láti rí si ọ̀ràn yìí. Nígbà tí iyàn sì di púpọ̀, Peteru dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ará, ẹ̀yin mọ̀ pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn nínú yín pé, kí àwọn aláìkọlà lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ìhìnrere láti ẹnu mi, kí wọn sì gbàgbọ́. Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olùmọ̀-ọkàn, sì jẹ́ wọn lẹ́rìí, ó fún wọn ni Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwa. Kò sí fi ìyàtọ̀ sí àárín àwa àti àwọn, ó ń fi ìgbàgbọ́ wẹ̀ wọ́n lọ́kàn mọ́. 10 Ǹjẹ́ nítorí náà èéṣe tí ẹ̀yin o fi dán Ọlọ́run wò, láti fi àjàgà bọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́rùn, èyí tí àwọn baba wa àti àwa kò lè rù? 11 Ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Olúwa Jesu àwa ó là, gẹ́gẹ́ bí àwọn.”

Johanu 11:17-29

Jesu tu àwọn arábìnrin rẹ̀ nínú

17 Nítorí náà nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ọjọ́ mẹ́rin ná, 18 Ǹjẹ́ Betani súnmọ́ Jerusalẹmu tó ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún: 19 (A)Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Marta àti Maria láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn. 20 Nítorí náà, nígbà tí Marta gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀: ṣùgbọ́n Maria jókòó nínú ilé.

21 Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú. 22 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ.”

23 Jesu wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.”

24 (B)Marta wí fún un pé, “Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn.”

25 (C)Jesu wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè: 26 (D)Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?”

27 (E)Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa: èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kristi náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”

28 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Maria arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.” 29 Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.