Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 30

Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.

30 Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,
    nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè
    tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.
Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́
    ìwọ sì ti wò mí sàn.
Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
    mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.

Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;
    kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,
    ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;
Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,
    Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.

Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,
    “a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”
Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,
    ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;
ìwọ pa ojú rẹ mọ́,
    àyà sì fò mí.

Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é;
    àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:
“Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,
    nínú lílọ sí ihò mi?
Eruku yóò a yìn ọ́ bí?
    Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?
10 Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;
    ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”

11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;
    ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.
    Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.

Saamu 32

Ti Dafidi. Maskili.

32 (A)Ìbùkún ni fún àwọn
    tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
    tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
    ẹni tí Ọlọ́run kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn
    àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.

Nígbà tí mo dákẹ́,
    egungun mi di gbígbó dànù
    nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.
Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru
    ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;
agbára mi gbẹ tán
    gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.

Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ
    àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.
Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́
    ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”
ìwọ sì dárí
    ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ
    ní ìgbà tí a lè rí ọ;
nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,
    wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;
    ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;
    ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.

Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn
    èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.
Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka,
    tí kò ní òye
ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,
    kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.
10 Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,
    ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin
    ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.

11 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo;
    ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.

Saamu 42-43

ÌWÉ KEJÌ

Saamu 42–72

Fún adarí orin. Maskili ti àwọn ọmọ Kora.

42 Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi,
    bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run.
Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè.
    Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?
Oúnjẹ mi ni omijé mi
    ní ọ̀sán àti ní òru,
    nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́ pé,
    “Ọlọ́run rẹ dà?”
Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí,
    èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi:
èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ,
    èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run
pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn,
    pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.

Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
    Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run,
    nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín,
    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi:
    nítorí náà, èmi ó rántí rẹ
láti ilẹ̀ Jordani wá,
    láti Hermoni láti òkè Mibsari.
Ibú omi ń pe ibú omi
    nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀
gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀
    bò mí mọ́lẹ̀.

Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ rẹ̀,
    àti ni àṣálẹ́ ni orin rẹ̀ wà pẹ̀lú mi
àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.

Èmi wí fún Ọlọ́run àpáta mi,
    “Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi?
Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́,
    nítorí ìnilára ọ̀tá?”
10 Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí
    àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí,
Bí wọn ti ń béèrè ní gbogbo ọjọ́.
    “Níbo ni Ọlọ́run rẹ wà?”

11 Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
    Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
    nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun ni
    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
43 Dá mi láre, Ọlọ́run mi,
    kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè:
yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.
Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.
    Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?
Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,
    nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?
Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde,
    jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí;
jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ,
    sí ibi tí ìwọ ń gbé.
Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,
    sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,
èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,
    ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.

Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?
    Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
    nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni
    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

Jobu 22:1-4

Èsì Elifasi

22 Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé:

(A)“Ènìyàn lè è ṣe rere fún Ọlọ́run?
    Bí ọlọ́gbọ́n ti í ṣe rere fún ara rẹ̀?
Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmarè pé olódodo ni ìwọ?
    Tàbí èrè kí ni fún un ti ìwọ mú ọ̀nà rẹ̀ pé?

“Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rù
    Ọlọ́run rẹ? Yóò ha bá ọ lọ sínú ìdájọ́ bí?

Jobu 22:21-23:7

21 “Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà;
    nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.
22 Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá,
    kí o sì to ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ.
23 Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró:
    Bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,
24 Tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀
    lórí erùpẹ̀ àti wúrà ofiri lábẹ́ òkúta odò,
25 Nígbà náà ní Olódùmarè yóò jẹ́ wúrà rẹ,
    àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
26 Lóòtítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmarè,
    ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run.
27 Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò sì gbọ́ tìrẹ,
    ìwọ ó sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.
28 Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú, yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ;
    ìmọ́lẹ̀ yóò sì mọ́ sípa ọ̀nà rẹ.
29 Nígbà tí ipa ọ̀nà rẹ bá lọ sísàlẹ̀,
    nígbà náà ni ìwọ o wí pé, ‘Ìgbésókè ń bẹ!’
    Ọlọ́run yóò sì gba onírẹ̀lẹ̀ là!
30 Yóò gba ẹni tí kì í ṣe aláìjẹ̀bi là,
    a ó sì gbà á nípa mímọ́ ọwọ́ rẹ̀.”

Èsì Jobu

23 Ìgbà náà ni Jobu sì dáhùn wí pé:

“Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò;
    ọwọ́ mí sì wúwo sí ìkérora mi.
Háà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wá
    Ọlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀!
Èmi ìbá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀,
    ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé.
Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dá
    mi lóhùn; òye ohun tí ìbáwí a sì yé mi.
Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí?
    Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsi mi.
Níbẹ̀ ni olódodo le è bá a wíjọ́,
    níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì bọ́ ni ọwọ́ onídàájọ́ mi láéláé.

Ìṣe àwọn Aposteli 13:26-43

26 (A)“Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Abrahamu, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí. 27 Nítorí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu, àti àwọn olórí wọn, nítorí tiwọn kò mọ̀ Jesu, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi. 28 Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pilatu láti pa á. 29 Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì. 30 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, 31 o sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Galili wá sí Jerusalẹmu, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsin yìí fún àwọn ènìyàn.

32 “Àwa sì mú ìhìnrere wá fún yín pé: Ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa, 33 (B)èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jesu dìde: Bí a sì ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Saamu kejì pé:

“ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi;
    lónìí ni mo bí ọ.’

34 (C)Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé:

“ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’

35 (D)Nítorí ó sì wí nínú Saamu mìíràn pẹ̀lú pé:

“ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’

36 “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́. 37 Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́.

38 “Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jesu yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín. 39 Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mose. 40 Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:

41 (E)“ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,
    kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù;
nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín,
    tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,
    bí a tilẹ̀ sọ fún yin.’ ”

42 Bí Paulu àti Barnaba sì ti ń jáde láti inú Sinagọgu, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀. 43 Nígbà tí wọn sì jáde nínú Sinagọgu, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀lé Paulu àti Barnaba, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

Johanu 10:1-18

Agbo kan àti olùṣọ́-àgùntàn kan

10 “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ inú agbo àgùntàn, ṣùgbọ́n tí ó bá gba ibòmíràn gun òkè, òun náà ni olè àti ọlọ́ṣà. (A)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ti ẹnu-ọ̀nà wọlé, Òun ni olùṣọ́ àwọn àgùntàn. Òun ni aṣọ́nà yóò ṣílẹ̀kùn fún; àwọn àgùntàn gbọ́ ohùn rẹ̀: ó sì pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ lórúkọ, ó sì ṣe amọ̀nà wọn jáde. Nígbà tí ó bá sì ti mú àwọn àgùntàn tirẹ̀ jáde, yóò síwájú wọn, àwọn àgùntàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn: nítorí tí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. Wọn kò jẹ́ tọ àlejò lẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọn a sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: nítorí tí wọn kò mọ ohùn àlejò.” (B)Òwe yìí ni Jesu pa fún wọn: ṣùgbọ́n òye ohun tí nǹkan wọ̀nyí tí ó ń sọ fún wọn kò yé wọn.

Nítorí náà Jesu tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn. (C)Olè àti ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi: ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ tiwọn. Èmi ni ìlẹ̀kùn: bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, òun ni a ó gbàlà, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko. 10 Olè kì í wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun: èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀.

11 (D)“Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 12 Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri. 13 Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn.

14 “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí. 15 (E)Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba; mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 16 (F)Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn yóò sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùṣọ́-àgùntàn kan. 17 Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á. 18 (G)Ẹnìkan kò gbà á lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀, mo sì lágbára láti tún gbà á. Àṣẹ yìí ni mo ti gbà wá láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.