Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Saamu Dafidi.
41 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:
Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.
2 Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:
yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀
kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
3 Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀
yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.
4 Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;
wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.
5 Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé
“Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”
6 Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,
wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;
nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.
7 Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;
èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,
8 wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin
àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,
kì yóò dìde mọ́.”
9 (A)Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,
ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,
tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.
10 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;
gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.
11 Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,
nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.
12 Bí ó ṣe tèmi ni
ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi
ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.
13 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli
láé àti láéláé.
Àmín àti Àmín.
Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.”
52 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin?
Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo,
ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?
2 Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;
ó dàbí abẹ mímú,
ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.
3 Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ,
àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.
4 Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,
ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!
5 Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,
yóò sì dì ọ́ mú,
yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ,
yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela.
6 Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù
wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,
7 “Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,
bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,
ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”
8 Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi
tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;
Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà
láé àti láéláé.
9 Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;
èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,
nítorí orúkọ rẹ dára.
Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Maskili.
44 À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run
àwọn baba wa tí sọ fún wa
ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn,
ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.
2 Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde
Ìwọ sì gbin àwọn baba wa;
Ìwọ run àwọn ènìyàn náà
Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.
3 Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà,
bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ;
àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.
4 Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi,
ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.
5 Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú;
nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀
6 Èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi
idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,
7 Ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa,
ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.
8 Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́,
àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé. Sela.
9 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá;
Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.
10 Ìwọ ti bá wa jà,
ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa,
àwọn ọ̀tá wa ti gba ilẹ̀ wa,
wọ́n sì fi ipá gba oko wa.
11 Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn
Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.
12 Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré,
Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.
13 Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa,
ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.
14 Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.
15 Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́,
ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,
16 nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn
ní ojú àwọn ọ̀tá àti olùgbẹ̀san.
17 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa,
síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ
bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.
18 Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn;
bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.
19 Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá,
ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú,
tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.
20 Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa
tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.
21 Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀,
níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?
22 (A)Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́
a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.
23 Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn?
Dìde fúnrarẹ̀! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.
24 Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú rẹ mọ́
tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?
25 Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku;
ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.
26 Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́;
rà wá padà nítorí ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.
Ọ̀rọ̀ Elihu
32 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí dákẹ́ láti dá Jobu lóhùn, nítorí ó ṣe olódodo lójú ara rẹ̀. 2 Nígbà náà ni inú bí Elihu ọmọ Barakeli ará Busi, láti ìbátan ìdílé Ramu; ó bínú si Jobu nítorí ti ó dá ara rẹ̀ láre kàkà ki ó dá Ọlọ́run láre. 3 Inú sì bí i sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí tí wọn kò rí ọ̀nà láti dá Jobu lóhùn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá Jobu lẹ́bi. 4 Ǹjẹ́ Elihu ti dúró títí tí Jobu fi sọ̀rọ̀ tán nítorí tí àwọn wọ̀nyí dàgbà ju òun lọ ní ọjọ́ orí. 5 Nígbà tí Elihu rí i pé ìdáhùn ọ̀rọ̀ kò sí ní ẹnu àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí nígbà náà ni ó bínú.
6 Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, dáhùn ó sì wí pé:
“Ọmọdé ni èmi,
àgbà sì ní ẹ̀yin;
ǹjẹ́ nítorí náà ní mo dúró,
mo sì ń bẹ̀rù láti fi ìmọ̀ mi hàn yin.
7 Èmi wí pé ọjọ́ orí ni ìbá sọ̀rọ̀,
àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n.
8 Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan ní ó wà nínú ènìyàn
àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye.
9 Ènìyàn ńláńlá kì í ṣe ọlọ́gbọ́n,
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.
10 “Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé: Ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi;
èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.
19 Kíyèsi i, ikùn mi dàbí ọtí wáìnì, tí kò ní ojú-ìhò;
ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-awọ tuntun.
20 Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí,
èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.
21 Lóòtítọ́ èmi kì yóò ṣe ojúsàájú sí ẹnìkankan,
bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan.
22 Nítorí pé èmí kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni í sọ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀,
Ẹlẹ́dàá mi yóò mú mi kúrò lọ́gán.
Elihu bá Jobu sọ̀rọ̀
33 “Ǹjẹ́ nítorí náà, Jobu, èmí bẹ̀ ọ,
gbọ́ ọ̀rọ̀ mi kí o sì fetísí ọ̀rọ̀ mi!
19 “A sì nà án lórí ibùsùn ìrora rẹ̀;
pẹ̀lúpẹ̀lú a fi ìjà egungun rẹ̀ ti ó dúró pẹ́ nà án,
20 bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí rẹ kọ oúnjẹ,
ọkàn rẹ̀ sì kọ oúnjẹ dídùn.
21 Ẹran-ara rẹ̀ run, títí a kò sì fi lè rí i mọ́
egungun rẹ̀ tí a kò tí rí sì ta jáde.
22 Àní, ọkàn rẹ̀ sì súnmọ́ isà òkú,
ẹ̀mí rẹ̀ sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ikú.
23 Bí angẹli kan ba wà lọ́dọ̀ rẹ̀,
ẹni tí ń ṣe alágbàwí,
ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún láti fi ọ̀nà pípé hàn ni,
24 Nígbà náà ni ó ṣe oore-ọ̀fẹ́ fún un ó sì wí pé,
gbà á kúrò nínú lílọ sínú isà òkú;
èmi ti rà á padà.
25 Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọ kékeré,
yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀;
26 Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì ṣe ojúrere rẹ̀,
o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀,
òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn.
27 Ó wá sọ́dọ̀ ènìyàn ó sì wí pé,
‘Èmi ṣẹ̀, kò sì ṣí èyí tí o tọ́, mo sì ti yí èyí tí ó tọ́ po,
a kò sì san ẹ̀san rẹ̀ fún mi;
28 Ọlọ́run ti gba ọkàn mi kúrò nínú lílọ sínú ihò,
ẹ̀mí mi yóò wà láti jẹ adùn ìmọ́lẹ̀ ayé.’
44 Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ péjọ tan láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 45 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Paulu ń sọ.
46 Paulu àti Barnaba sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà. 47 (A)Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti pàṣẹ fún wa pé:
“ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà,
kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ”
48 Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́.
49 A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbègbè náà. 50 Ṣùgbọ́n àwọn Júù rú àwọn obìnrin olùfọkànsìn àti ọlọ́lá sókè àti àwọn àgbà ìlú náà, wọ́n sì gbé inúnibíni dìde sí Paulu àti Barnaba, wọ́n sì le wọn kúrò ni agbègbè wọn. 51 Ṣùgbọ́n wọ́n gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sí wọn, wọn sì wá sí Ikoniomu. 52 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn si kún fún ayọ̀ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́.
19 (A)Nítorí náà ìyapa tún wà láàrín àwọn Júù nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 20 (B)Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wí pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì dàrú; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń gbọ́rọ̀ rẹ̀?”
21 (C)Àwọn mìíràn wí pé, “Ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀mí èṣù lè la ojú àwọn afọ́jú bí?”
Àìgbàgbọ́ àwọn Júù
22 Àkókò náà sì jẹ́ àjọ̀dún ìyàsímímọ́ ní Jerusalẹmu, ni ìgbà òtútù. 23 (D)Jesu sì ń rìn ní tẹmpili, ní ìloro Solomoni, 24 Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó? Bí ìwọ bá ni Kristi náà, wí fún wa gbangba.”
25 (E)Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi. 26 (F)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí nínú àwọn àgùntàn mi, gẹ́gẹ́ bí mo tí wí fún yín. 27 Àwọn àgùntàn mi ń gbọ́ ohùn mi, èmi sì mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn: 28 (G)Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun; wọn kì yóò sì ṣègbé láéláé, kò sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi. 29 Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì ṣí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi. 30 (H)Ọ̀kan ni èmi àti Baba mi.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.