Book of Common Prayer
Fún adarí orin. Orin. Saamu.
66 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ilẹ̀ gbogbo!
2 Ẹ kọrin ọlá orúkọ rẹ̀;
Ẹ kọrin ìyìnsí i,
3 Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé,
ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ rẹ!
Nípa ọ̀pọ̀ agbára rẹ ni àwọn ọ̀tá
rẹ yóò fi sìn ọ́.
4 Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;
wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,
wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ.” Sela.
5 Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe,
Iṣẹ́ rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!
6 Ó yí Òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,
wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá,
níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀.
7 Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀,
ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè
kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela.
8 Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,
jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀;
9 Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa,
kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀
10 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò;
ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.
11 Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n
o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa
12 Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí
àwa la iná àti omi kọjá
ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.
13 Èmi ó wá sí tẹmpili rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,
kí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ
14 Ẹ̀jẹ́ tí ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọ
nígbà tí mo wà nínú ìṣòro.
15 Èmi ó rú ẹbọ sísun ọlọ́ràá sí ọ,
àti ẹbọ ọ̀rá àgbò;
èmi ó rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela.
16 Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run;
ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.
17 Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i:
Ìyìn rẹ̀ wà ní ẹnu mi.
18 Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi,
Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi;
19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́
ó ti gbọ́ ohùn mi nínú àdúrà.
20 Ìyìn ni fún Ọlọ́run
ẹni tí kò kọ àdúrà mi
tàbí mú ìfẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!
Ejò idẹ
4 Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hori lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Edomu. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà; 5 wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run àti Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti kí a ba le wá kú sí aginjù yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kórìíra oúnjẹ tí kò dára yìí!”
6 Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárín wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sì kú. 7 Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mose wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí asọ̀rọ̀-òdì sí Olúwa àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí Olúwa mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mose gbàdúrà fún àwọn ènìyàn.
8 Olúwa sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.” 9 Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.
11 (A)Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Àwa ń sọ èyí tí àwa mọ̀, a sì ń jẹ́rìí èyí tí àwa ti rí; ẹ̀yin kò sì gba ẹ̀rí wa. 12 Bí mo bá sọ ohun ti ayé yìí fún yín, tí ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ ohun ti ọ̀run fún yín? 13 (B)Kò sì ṣí ẹni tí ó gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, Ọmọ Ènìyàn tí ń bẹ ní ọ̀run. 14 (C)Bí Mose sì ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ Ènìyàn sókè pẹ̀lú: 15 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, kí ó má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó le ní ìyè àìnípẹ̀kun.”
16 (D)“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. 17 (E)Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là.
118 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;
àánú rẹ̀ dúró láéláé.
2 Jẹ́ kí Israẹli wí pé:
“Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
3 Jẹ́ kí ilé Aaroni wí pé:
“Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
4 Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa wí pé:
“Àánú rẹ̀ dúró láéláé.”
5 Nínú ìrora mi, mo sọkún sí Olúwa,
ó sì dá mi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.
6 (B)Olúwa ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù.
Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
7 Olúwa ń bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ mi
Nítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìṣẹ́gun mi lórí àwọn tí ó kórìíra mi.
8 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.
9 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ-aládé lọ.
10 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi káàkiri,
ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn kúrò
11 Wọ́n yí mi káàkiri ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,
ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn dànù
12 Wọ́n gbá yìn ìn yí mi ká bí oyin,
ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún;
ní orúkọ Olúwa èmi ké wọn dànù.
13 Ìwọ tì mí gidigidi kí n lè ṣubú,
ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́.
14 Olúwa ni agbára àti orin mi;
ó sì di ìgbàlà mi.
15 Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo:
“Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!
16 Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbéga;
ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!”
17 Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò yè,
èmi yóò pòkìkí ohun tí Olúwa ṣe.
18 Olúwa bá mi wí gidigidi,
ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.
19 Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi:
èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.
20 Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwa
ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.
21 Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn;
ìwọ sì di ìgbàlà mi.
22 (C)Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
ni ó di pàtàkì igun ilé;
23 Olúwa ti ṣe èyí,
ó ṣe ìyanu ní ojú wa.
24 Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá:
ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.
25 (D)Olúwa, gbà wá;
Olúwa, fún wa ní àlàáfíà.
26 Ìbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.
Àwa ti fi ìbùkún fún ọ láti ilé Olúwa wá.
27 Olúwa ni Ọlọ́run,
ó ti mú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn sí wa lára
pẹ̀lú ẹ̀ka igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́
ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀
ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ.
28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ;
ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga.
29 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
17 Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ. 18 Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí: 19 Nínú èyí tí ó lọ pẹ̀lú tí ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú túbú: 20 (A)àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́ràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run dúró pẹ́ ní sá à kan ní ọjọ́ Noa, nígbà tí wọ́n fi kan ọkọ̀ nínú èyí tí a gba ọkàn díẹ̀ là nípa omi, èyí ni ẹni mẹ́jọ. 21 Àpẹẹrẹ èyí ti ń gbà yín là nísinsin yìí pẹ̀lú, àní ìtẹ̀bọmi, kì í ṣe wíwẹ́ èérí ti ara nù, bí kò ṣe ìdáhùn ẹ̀rí ọkàn rere si Ọlọ́run, nípa àjíǹde Jesu Kristi. 22 Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run: pẹ̀lú àwọn angẹli, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.